Divorce: Ìyàwó fi ẹ̀sùn kan ọkọ rẹ̀ pé ó máa n bá àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ ní ìbálòpọ̀

Oríṣun àwòrán, others
Ọrọ di irọ ni, ootọ ni, lasiko ti ajinhinrere obìnrin kan, Chinwe Ekwe, to jẹ ẹni ọdun mọkandinlaadọta fi ẹsun kan ọkọ rẹ to jẹ pasitọ pe o ma n ba awọn ọmọ ijọ rẹ sun.
Chinwe sọ ọrọ yii lasiko to n fesi si iwe ikọsilẹ ni ile ẹjọ ibilẹ to wa ni Igando nipinlẹ Eko.
Ọkọ rẹ, Pasitọ Paul Ekwe fi ẹsun kan Chinwe pe o n gbero lati pa òun.
- Lere Paimo ṣàlàyé bí fíìmù "Ogbori Elémosho" ṣe sọ ọ̀ di Olóyè MFR pẹ̀lú Dangote àti Adenuga
- Darandaran tí kò bá forúkọ sílẹ̀ gbọdọ̀ fi ìgbó ìjọba sílẹ̀ l'Ondo, Akeredolu fèsì sọ́rọ̀ Garba Shehu
- Wo ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Joe Biden, aàrẹ tuntun ilẹ̀ America
- Ìpínlẹ̀ Eko ló ń léwájú nínú àwọn tó lùgbàdì Covid 19 lánàá- NCDC
Arabinrin Chinwe sọ pe nise ni ọkọ oun ma n ba awọn obinrin miran ni ibalopọ, eyi ti ko yọ iyawo ile silẹ.
O ni "gbogbo nkan ni mo fi n ṣe itọju rẹ nipa ti ẹmi ati ara. Sugbọn o tun yàn lati ma a ṣe isekuse pẹlu oriṣiriṣi obinrin.
" Koda, o gbe obirin kan to jẹ iyawo ile wa sinu ile wa gẹgẹ bi iyawo rẹ tuntun, to si le mi jade."
Arabinrin Chinwe sọ pe nise ni ọkọ oun n ba orúkọ oun jẹ kiri pe oun gbeero lati pa a.
O ni ko si èrè kankan fun oun ti oun ba pa ọkọ ti oun bi ọmọbìnrin meje fun.
" Nitori pe o fẹ ẹ fẹ iyawo mii lo ṣe n parọ mọ mi.
"Emi ni mo n gbọ gbogbo bukaata rẹ, àmọ́ awọn ale rẹ lo n fi owo ra oúnjẹ fun."
Bakan naa ni Chinwe sọ pe ọkọ oun ti fi ọlọpaa mu oun ri, fun ẹsun to fi kan pe oun ba sọọsi rẹ jẹ, ti oun tun ji ní miliọnu márùn-ún Naira.
Sugbọn ṣa, Chinwe bẹ adájọ pe ko ma ṣe tu igbeyawo wọn ka, nitori pe oun ṣi nifẹ ọkọ oun botilẹ jẹ pe alagbere ni.
Kini awijare Pasitọ Ekwe?
Nigba to n ṣorọ nile ẹjọ, Pasitọ Paul Ekwe to jẹ ọkọ Chinwe sọ pe dandan ni ki ile ẹjọ tu igbeyawo ọdun mejidinlọgbọn naa ka nitori pe iyawo oun fẹ ẹ pa oun.
Ekwe sọ pe alagidi ati ẹni to fẹran ija ni Chinwe.
"Ija ojoojumọ lo kun inu igbeyawo wa. Chinwe ti sọ ile mi di ibi inira ati aisi ifọkanbalẹ fun mi."
- Ọkọ̀ agbépo bẹ́ntiról kankan kò gbọdọ̀ gun afárá nípínlẹ Ogun mọ́ - Gomina Dapo Abiodun
- Fulani kìí ṣe ajínigbé! Akeredolu kò ní ká pòórá nínú igbó ìjọba l'Ondo, ohun tí Gómìnà sọ rèé...- Miyetti Allah
- Ta ni Mohammad Buba Marwa tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọ̀gá àgbà àjọ NDLEA?
- Kíní Kọmíṣọ́nnà Ọlọ́pàá, mẹ̀kòó ṣe tí wọ́n fi rí ẹ̀wọ̀n gbére he ní Ekiti?
O tun fi ẹsun kan iyawo rẹ pe o sọ awọn ọmọ oun di ọ̀tá oun, debi i pe o fẹ ìkan lara wọn fun ọkọ lai jẹ ki oun mọ.
O bẹ ile ẹjọ lati tu igbeyawo wọn ka nitori pe ifẹ ti oun ni si iyawo oun nigba kan ko si mọ.
Ile ẹjọ si ti sun ẹjọ wọn si ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kinni, ọdun 2021.



















