Ekiti Stolen Items: Kíní Ọlọ́pàá, mẹ̀kòó ṣe tí wọ́n fi rí ẹ̀wọ̀n gbére he ní Ekiti?

Olopaa

Igbakeji Kọmisọnna, Okubo Aboye ati mẹkoo rẹ ni wọn ti ran lọ si ẹwọn gbere, lẹyin ti o gba ọkọ ti wọn ji lọwọ awọn ajinigbe.

Aboye to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgọta naa ni ileẹjọ giga nipinlẹ Ado-Ekiti.

Awọn meje miran ni Solomon Ayodele Obamoyegun 39, Femi Omiawe 40, Damilola Obamoyegun 20, Bose Sade Ajayi 30, George Lucky 35, Chukwuma Nnamani 22, ati Sunday Ogunleye 45 naa ni wọn ri ẹwọn ọdun marun un hẹ fun ẹsun ajinigbe.

Awọn ọlọpaa to ṣe iwadii ijinigbe naa ni wọn ri ọkọ ti wọn jigbe naa ni ile igbe ACP Akubo Aboye, to si jẹwọ pe oun ra ọkọ Hilux van naa lọwọ ẹni to n tun ọkọ rẹ ṣe, ti wọn gba lọwọ awọn ajinigbe.

Adajọ John Adeyeye lasiko to n dajọ ni awọn mejeeji ni wọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn, nitori naa ni wọn si n ran wọn lọ si ẹwọn gbere.

Adajọ Adeyeye ni awọn mẹsan naa jẹbi ẹsun ijinigbe, ti wọn si bere owo ẹmi lọwọ wọn.

O fikun wi pe ọrọ ijinigbe Naijiria ti peleke si, ti ko si pin si ipinlẹ Ekiti nikan.

Bakan naa ni adajọ fikun wi pe awọn n ṣiṣẹ awọn bi iṣẹ ni wọn ṣe ṣedajọ awọn to jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa: Alagba Ajibola láti Fakunle ní olùkọ́ wa lórí ètò ìró lónìí