Water drinking advantages: Wo ìpalára ní ọ̀nà mẹ́fà tó lè bá ènìyàn tí kò bá kí ń mu omi mímu tó ìwọn tó yẹ

Oríṣun àwòrán, others
Ìpalára mẹ́fà tó wà nínú kí èèyàn ṣalai mú omi ní ìwọ̀n ti ara nílò.
Ṣe gbogbo wa la kuku mọ wipe mimu omi deedee jẹ ọnà kan gboogi lati je ki ara wa ni okun ati alaafia.
Lasiko ti a wa yi, ti oorun a maa mu gidi gan an, omi mímu jẹ ọnà ti ará fi n ṣe idapada awọn okun to ba ti padanu nipasẹ lilọ bíbọ ati iṣẹ ṣiṣe.
Bi omi ko ba sì ni ọnà ọfún wa tabi ninu agọ ara wa, ko ni pẹ ti orisirisi ailera yóò máa bá agọ ara wa finra.
- Wo àwọn oúnjẹ márùn ún tó ń mú kí àtọ̀ ọkùnrin dára síi
- World Food Day: Wo àwọn oúnjẹ ìṣẹ̀mbáyé Yorùbá tó ti ń di àpatì
- Wo àwọn ìṣesí ojoojúmọ́ mẹ́wàá tó le ṣàkóbá fún ọpọlọ rẹ
- Ṣé irúfẹ́ oúnjẹ tí ò ń jẹ́ lè jẹ́ kí o gbádùn ìbálòpọ̀ rẹ síi?
- Wo oríṣìí oúnjẹ márùn ún tó lè dẹ́kun ikùn yíyọ àti ara àsanjù
- Wo oríṣìí àrùn márùn ún tí ìgbéyàwó láàrin ìbátan si ìbátan máa ń fà
Díẹ ninu awọn ohun to yẹ ki o ṣọra fun ree ninu wọn:
1) Ara ko ni ji pepe to bo ti ṣe yẹ:
Ti ara ko ba ni omi tó bo ti ṣe yẹ,ara oluwaarẹ ko ni ji pepe lati se awọn iṣẹ to yẹ kó lè ṣe.
Lọpọ igba irẹwẹsi yoo ba ọkan eeyan ti gbogbo ara ko sí ní le ṣiṣẹ bo ti ṣe yẹ.
2) Ewu rọ lapa-rọ lẹsẹ(stroke):
Gẹgẹ bi iwadii kan ti awọn onimọ nipa ailera kasan ara gbe jade, wọn ni aimaa mu omi daada le fa ki eeyan ni rọlapa rọlẹsẹ ti oloyinbo n pe ni Stroke.
3) Ṣiṣe ibẹrẹ ko ni wa nirọwọrọsẹ:
Ounjẹ ti eeyan ba jẹ ti ko mu omi sí daada,iru oúnjẹ bẹ ko ni da daada lara onitọhun.
Nitori idi eyi ko dáa tó ki eeyan maa fi oungbẹ gbẹ ara rẹ tabi ko ma sey mu omi tó bo ti ṣe yẹ.
4) Ori fifọ:
Nitori pe ọpọlọ wa nilo omi ti yóò fi le ṣiṣẹ daada, bi eeyan ko ba mu omi daadaa ko sí tàbí ṣugbọn ori fifọ ko ni jẹ ki iru eeyan bẹ gbádùn ara rẹ.
5) Awọ ara ko ni jọlọ to:
Apẹrẹ bi eeyan ba ṣe n mu omi sí a máa hàn lara awọ ẹni bẹẹ.
Ìdí ni pé ara wa nilo omi ki o baa le ji pepe ko si máa dan daada.
Bi eeyan ba kọ ti ko mu omi daada n'isẹ ni awọ rẹ yoo hun jọ ti yoo si dabi arugbo ọsan gan an.
Awọ ti ko dan daada,ẹ fura si boya alawọ naa ko mu omi daadaa ni.
6) Ai mu omi máa n mu eeyan sanra:
Bi eeyan ko ba fẹ sanra púpọ,ọna kan to lè fi jo walẹ ni ko máa mú omi daadaa.
Ni idakeji bi eeyan ba fe sanra ko yàgò fún omi mímu ṣugbọn o dami loju pe ẹ ko ni fẹ ṣe bẹẹ.
Ẹ máa gbagbe ilera lóògùn ọrọ, bi a ba si fẹ kí awọ wàá máa dan bi ti ikoko,omi mímu wa lara ohun táa lè ṣe.





















