Overweight and pot belly: Wo oríṣìí oúnjẹ márùn ún tó lè dẹ́kun ikùn yíyọ àti ara àsanjù

Irẹsi

Oríṣun àwòrán, Food Ace

Njẹ iwọ ominu n kọ ẹ lori bi o ṣe n yọkun tabi bi o ṣe n tobi sii?

Wo ọna ti o le gba dẹkun yiyọkun ati titobi sii pẹlu alaye onimọ nipa ounjẹ jijẹ yii.

Akọṣẹ-mọṣẹ nipa ounjẹ jijẹ to tun jẹ nọọsi, Adanna Monday ni o ṣe pataki ki onikaluku maa se ounjẹ to ba fẹ jẹ fun ra rẹ.

Bakan naa lo sọ pe o yẹ ki eeyan ni gbedeke ounjẹ ti yoo maa jẹ nigba kuu gba.

Ninu ọrọ rẹ, ''jijẹ ounjẹ lasiko ati deedee le jẹ ki ara asanju, aisan bii ẹjẹ ruru ati arun itọ ṣuga jina si agọ ara eeyan.''

Isọri ounjẹ marun un ree ti o le jẹ lati maa sanra asanju tabi yọkun

1. Eso

Mkpuruosisi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nọọsi Adanna sọ pe jijẹ oriṣiiriṣii eso bii mọngoro, ọsan oronbo atawọn eso mii dara fun ilera agọ ara.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ

O eso bi ''apple'' ati ''strawberries'' jẹ eso aṣara loore ati pe ko ni jẹ ki ọra pọju ninu agọ ara.

Adanna ni irufẹ awọn eso yii ni ohun aṣara loore kan ti wọn n pe ni ''fibre'' ninu.

2. Ẹfọ tabi ewebẹ

Amunututu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nọọsi Adanna ni jijẹ ewe ''pumpkin'' ati amunututu dara fun agọ ara.

O ni bi awọn ewe ẹfọ yii ti dudu were were lo jẹ ki o ṣe anfaani fun ara.

Adanna ni iru awọn ewe yii lo maa n kọju ija arun to le ṣuyọ ninu agọ ara.

3. Ẹja ati ẹran adiẹ

Ẹran adiẹ ati ẹja

Oríṣun àwòrán, Getty Images

''Jijẹ ẹja bi ẹja abori tabi ẹja crocker yoo ṣeranwọ lati maa sanra ju tabi yọkun,''Adanna lo sọ bẹẹ.

O fikun ọrọ rẹ pe ẹran adiẹ ati tolotolo naa wulo nitori wọn maa n dena arun ninu ara.

Adanna ni irufẹ ẹran bayii ko ni jẹ ki ara sun soju kan naa eyi to le nu eeyan yọkun tabi sanra ju.

4. Ounjẹ afara lokun

Irẹsi

Oríṣun àwòrán, Food Ace

Adanna ṣalaye siwaju pe awọn ounjẹ afara lokun bi irẹsi ti eeyan ba kore rẹ ninu oko dara fun ara.

O ṣalaye pe iru ounjẹ bẹẹ to fi mọ ananmọ maa n ko ni jẹ ki ọra pọ lara eeyan eleyi to le mu tobi tabi yọkun.

5. Awọn ounjẹ ọlọra aṣaraloore

Piẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ounjẹ bi ẹpa, ororo olifi, ẹja mọnkẹrẹ ati avocado ni ọra to le ṣe ara loore ninu.

Adanna ni awọn ounjẹ yii dara fun ọkan ṣugbọn ajẹju wọ ko dara.

Akọṣẹ-mọṣẹ nipa ounjẹ ọhun ajẹju awọn ounbjẹ yii le mu ki eeyan sanra ju tabi yọkun.

Omi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lakotan, Adanna rọ awọn eeyan lati maa mu omi to pọ tabi jẹ eso to ni omi ninu daadaa..

Àkọlé fídíò, Promise Akinlade: ọmọ ọdún mọ́kànlá tó ń fi ìlù dárà bíi àgbàlagbà sọ̀rọ̀ nípa tálẹ́ǹtì rẹ