Lagos Senatorial Elections: Abiru ṣ'àbẹ̀wò sí Tinubu lẹ́yìn tó wọlé àtúndi ìbò Sẹnẹtọ ìlà oòrùn ìpínlẹ̀ Eko

Bola Tinubu pẹlu Tokunbo Abiru

Oríṣun àwòrán, Twitter/RitaAdubaBlog

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Lẹyin ti ajọ eleto idibo INEC kede rẹ tan gẹgẹ bi oludije to jawe olubori ninu atundi ibo sẹnẹtọ ẹkun ila-oorun ipinlẹ Eko, Tokunbo Abiru ti lọ ṣabẹwo si Asiwaju Bola Tinubu.

Tinubu gbaleji Abiru toun ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nile rẹ rẹ nibi ti wọn ti n yọ ayọ iṣẹgun ẹgbẹ oṣelu naa ninu ibo ọjọ Abamẹta.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Tinubu gbe ọwọ Abiru soke laarun ọpọ eeyan ti wọn n dunnu lori bi Abiru ti jawe olubori.

Ninu ọrọ tiẹ, Abiru ni oun ṣetan lati ṣoju ẹkun ila oorun ipinlẹ daadaa, bẹẹ ni oun ko si ni jawọn oludibo kulẹ.

Abiru wọlé àtúndi ìbò Sẹnẹtọ l'Eko, olùdíje méjì ṣojú APC ní Imo, òṣìṣẹ́ INEC méjì sọnù ní Zamfara

Awọn sẹnẹtọ tuntun ti foju han lẹyin atundi ibo to waye kaakiri orilẹede Naijiria lọjọ Satide, ọjọ karun un oṣu kejila, ọdun 2020.

Bala Lukshi(APC) bori ninu Atundi ibo Bauchi

Bala Lukshi ti ẹgbẹ oṣelu APC lo jawe olubori ninu atundi ibo ile aṣofin agba l'Abuja to waye lọjọ Abamẹta.

Awọn oludije to wọle atundi ibo

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ọga ajọ eleto idibo INEC, Ọjọgbọn Ahmed Mohammed to kede Lukshi gẹgẹ bi ẹni to bori ninu ibo naa kede pe 12, 299 ibo ni Lukshi ni to fi jawe olubori.

Ọjọgbọn Mohammed ṣalaye pe oludije fẹgbẹ oṣelu PDP, Lawal Wandi lo ṣe ipo keji lẹyin to ri ibo 11,062.

Oludije meji ṣoju APC to wọle atundi ibo Ariwa Imo

Ọrọ di un-un nigba ti ọga INEC, Hakeem Adikum kede pe ẹgbẹ oṣelu APC lo jawe olubori ninu atundi ibo ile aṣofin agba l'Abuja ti ẹkun ariwa ipinlẹ Imo lai darukọ oludije to bori gan an.

Ọgbẹni Adikum ni APC ri ibo 36, 811 nigba Emmanuel Okewulonu ẹgbé oṣelu PDP ṣe ipo keji pẹli ibo 31, 903.

Ajọ INEC kọ lati darukọ oludije APC to bori nitori awọn meji Ifeanyi Araraume ati Frank Ibezim lo duro gẹgẹ bi oludije ẹgbẹ naa ninu idibo ọjọ Abamẹta.

Oriṣiiriṣii aṣẹ nile ẹjọ ti pa pe ti ẹnikan fi ipo oludije fẹgbẹ oṣelu APC silẹ fun ẹnikan, ṣugbọn ko si eyi to kẹsẹ jari.

Àkọlé fídíò, Ìgbátí ìgbámú àná látọwọ́ sọ́jà obìnrin ti bá arákùnrin náà dé iléèwòsàn

Oṣiṣẹ INEC meji sọnu nibi atundi ibo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Zamfara ti ko fẹnu ko

Ajọ INEC ti kede pe atundi ibo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Zamfara ọjọ Satide ko fẹnu ko sibi kan.

Koda awọn iṣiṣẹ ajọ eleto idibo idibo INEC meji lo tun di awati ninu eto idibo naa.

Ọga INEC, Ọjọgbọn Ibrahim Magawata ṣalaye pe ibo naa ko fẹnu ko sibi kan nitori ajọ naa ti wọgile esi ibo ni ibudo idibo marun un.

O ni ibo 11,429 lo wa lawọn ibudo idibo marun un eleyi ti yoo ni ipa to lagbara lori ibo ti yoo sọ ẹni to wọle.

Amọ, o ṣalaye pe Alhaji Ibrahim Tudu, oludije ẹgbẹ oṣelu PDP lo si n lewaju ninu ibo naa.

Ọga INEC sọ pe ajọ naa yoo maa kede igba ti atundi ibo mii yoo waye lawọn ibudo idibo marun un tọrọ kan.

Àkọlé fídíò, India: Ẹ wo bí àwọn ènìyàn ṣe dóòlà èmí erin tó jálulẹ̀

APC lo wọle atundi ibo ile aṣofin Katsina

Ọmọwe Ibrahim Aminu Kurami lo bori ninu atundi ibo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Katsina ti ẹkun Bakori.

Ọmọwe Kurami la alatko rẹ lati ẹgbẹ oṣelu PDP, Alhaji Aminu Magaji mọlẹ lati jawe olubori ninu eto idibo ọhun.

Ọga INEC, Ọjọgbọn A. D. Kankia kede pe Ọmọwe Kurami ni ibo 20,444 eyi ti o fi la oludije PDP, Magaji mọlẹ.

Abiru jáwé olúborí nínú àtúndi ìbò Sẹnatọ ìlàoorùn ìpínlẹ̀ Eko

Olùdíje lábẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) fún ipò sẹ́nátọ̀ nínú àtúdi ibó Tokunbo Abiru ló jáwé olúborí.

Abiru jáwé olúborí nínú ìdìbò Sẹnatọ ìpínlẹ̀ Eko

Oríṣun àwòrán, Abiru/ Twitter

Àjọ INEC kéde ní òwúrọ̀ ọjọ́ ìsìnmi pé Abiru ní ìbò 89, 204 nígbà tí Babatunde ti ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party (PDP) ní ìbò 11, 257

Àlàfo tó pọ ni Abiru fi ẹyin alátako rẹ̀ janlẹ̀ ní àwọn ìjọba ìbílẹ̀ márun tó gbé ẹkùn náà ró

Atundi Ibo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lonii, ipinlẹ Eko, Kogi, Bayelsa, Borno, Cross River, Plateau ati Zamfara n ṣe atundi ibo lọjọ Satide ọjọ karun un oṣu kejila ọdun 2020.

Wo ohun to yẹ koo mọ nipa bi eto idibo ṣe n lọ

Lagos

Ọkan ni idibo atundi to n waye ni Eko.

Idibo yi n waye fun ipo aṣofin ẹkun idibo Lagos East Senatorial District ati Kosofe 11 Constituency si ile igbimọ aṣofin ipinlẹ.

Àkọlé fídíò, India: Ẹ wo bí àwọn ènìyàn ṣe dóòlà èmí erin tó jálulẹ̀

Idibo naa yoo waye ni awọn ijọba ibilẹ Epe, Ibeju Lekki, Kosofe, Somolu, ati Ikorodu. Ileeṣẹ ọlọpaa si ti fi ofin sita lati bẹgi dina irina lawọn ijọba ibilẹ yii laarin ago mẹfa owurọ si mẹfa irọlẹ.

Atundi ibo naa yoo waye lati rọpo aaye to gbofo lẹyin ti Sẹnetọ Adebayo Osinowo papoda ninu oṣu kẹfa ọdun yii.

Oludije meji loke tente sipo Sẹnetọ ni Bayelsa

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Bayelsa

Atundi ibo meji ni yoo waye si ẹkun idibo aarin gbungbun ati Iwọ Oorun ipinlẹ Bayelsa.

Kolokuma/Opokuma LGA, Yenegoa LGA, Southern Ijaw LGA, Ekeremor LGA, Sagbama LGA lawọn ijọba ibilẹ tọrọ kan.

Pẹlu iyansipo Gomina ipinlẹ Bayelsa, Douye Diri ati igbakeji rẹ, Sẹnetọ Lawrence Ewhrujakpo, aye meji ti ṣofo nitori Diri lo n ṣoju ẹkun aarin gbungbun Bayelsa tẹlẹ ti igbakeji rẹ si n ṣoju ẹkun idibo Iwọ Oorun Bayelsa.

Àkọlé fídíò, Ìgbátí ìgbámú àná látọwọ́ sọ́jà obìnrin ti bá arákùnrin náà dé iléèwòsàn

Wọn ti ko ọlọpaa ẹgbẹrun marun un sita lati mojuto aabo, ṣaaju, lasiko ati lẹyin idibo yii.

Ẹwẹ, ijọba ti fi ọrọ sita pe ofin aisi irina yii ko kan awọn to n kọ idanwo aṣekagba girama WAEC nipinlẹ Eko ati ni Bayelsa.

Àkọlé fídíò, Kayeefi: 'Ọkọ mi ṣẹ̀ṣẹ̀ ní kí n lọ se mọ́í-mọ́í, tó ṣẹ̀ bá mi ṣeré tán ni mo gbọ́ pé "Mopol" yìnbọn pa á'

Cross River

Idibo naa yoo waye ni ijọba ibilẹ marun un lati rọpo awọn aaye to ṣofo ni ẹkun Ariwa Cross River nile aṣofin agba Naijiria ati ile igbimọ aṣoju-ṣofin.

Bakan naa, awọn ipinlẹ mii ti atundi ibo yoo ti waye ni Kogi, Borno, Plateau, Zamfara ati Imo.

Kí ni itumọ "Atundi Ibo"?

Atundi ibo jẹ idibo tajọ eleto idibo ṣeto lati fi aṣoju mi rọpo tabi di awọn aaye to ṣofo lẹyin idibo apapọ lorilẹede.

Àwọn agbègbè tí àtùndi ìbò náà yóò kàn nípìnlẹ̀ Eko rèé

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko ti fi òfin de àwọn ìjọba ìbílẹ̀ Márùn-ún kan tí àtúdì ìdìbò sẹnatọ yóò ti wáyé lọ́ja àbámẹ́ta.

Ìgbélé náà yóò wáye láti ààgo mẹ́fà òwúrọ̀ sí ààgo mẹ́fà ìrọ̀lẹ́.

Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ náà ni Epe, Ibeju Lekki, Kosofe, Somolu àti Ikorodu.

Àkọlé fídíò, 'Ọkọ mi wa ọkọ̀ tẹ "Poly Bag" lásán, àfi gbùùàà! Àdó okoró búrẹ́kẹ'

Èyí túmọ̀ sí pé kò sí ẹni ti yóò ni ànfàni láti gbà àwọn ìjọba ìbílẹ̀ lọ sí ibi kankan, ọkọ̀ gan kò ni le gba ibẹ̀ kọjá pẹ̀lú.

Ètò yìí sì ti mú kí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá fí àwọn òṣìṣẹ́ tó dín díẹ̀ ni ẹgbẹ̀rún méjì sí àwọn bùdó ìdìbò tí ìdìbò yóò ti wáyé

Àwọn òṣìṣẹ́ tó pọ̀ndandan fún láti lọ ṣíṣẹ́ nìkàn ló pọ̀dandan fún láti jáde.

Àwọn míràn tó tún ni ànfààní ni àwọn tó n mójútó ètò ìdìbò àti àwọn elétò ìdìbò gan.

Àkọlé fídíò, Kayeefi: 'Ọkọ mi ṣẹ̀ṣẹ̀ ní kí n lọ se mọ́í-mọ́í, tó ṣẹ̀ bá mi ṣeré tán ni mo gbọ́ pé "Mopol" yìnbọn pa á'