Ọkùnrin kan dèrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tó jí súùtì àti àwọ̀tẹ́lẹ̀ ọkùnrin nílé ìtàjà ìgbàlódé Abuja

Idajọ ile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, others

Ọkùnrin kan rí ẹ̀wọ̀n he lẹ́yìn tó jí súwìtì àti àwọ̀tẹ́lẹ̀ ọkùnrin l'Abuja,

Ọkunrin ẹni ogoji ọdun kan ti ri ẹwọn ogoji ọjọ he lẹyin ti ile ẹjọ kan niluu Abuja sọ pe o jẹbi jiji suwiti ati awọtẹlẹ ọkunrin nile itaja igbalode kan.

Adajọ naa, Inuwa Maiwada ṣedajọ ọhun lẹyin ti Kabiru Zakari ni oun gba pe lootọ ni oun jẹbi ẹsun ti wọn fi ka noun.

Ṣugbọn Adajọ naa fikun pe Zakari le san owo itanran ẹgbẹrun mẹwaa naira dipo ko lọ fi ẹwọn jura, ko si tun ṣeleri pe oun ko ni ṣe bẹẹ mọ.

Adajọ ọhun tun pa lasẹ ki ọdaran naa lọ kẹkọọ nipa imọ Islam lasiko to ba n sẹwọn lọwọ ki ayipada le de ba aye rẹ.

Olupẹjọ, Ayotunde Adeyanju ni ọkunrin kan, Agida Stephen, to jẹ oludari ile itaja igbalode Fordmart to wa lagbegbe Karu, ni Abuja lo fẹsun kan Zakari pe o jale ninu ile itaja oun.

O ni Zakaru dibọn bi onibara, o wọ ile itaja naa o si ji igo omi, suwiti, ati awọtẹlẹ ọkunrin ti iye owo rẹ to ₦4,500.

Oludari ile itaja naa ṣalaye pe Zakari ko awọn ohun to ji ọhun pamọ sabẹ awọtẹlẹ re, to si san owo igo omi nikan.

Ṣugbọn ọdaran naa ko mọ pe ẹrọ CCTV ile itaja naa ti ka gbogbo ohun to ṣe silẹ.

Olupẹjọ naa sọ pe iwa ti Zakari wu yii lodi si ofin iwa ọdaran ti ẹsẹ 348 ati 288 ti orilẹ-ede Naijiria, o si yẹ ki ile ẹjọ fi iya to tọ jẹ ẹ.

Àkọlé fídíò, Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá: Kọ̀ síi nípa iṣẹ́ tí oúnjẹ ń ṣe lára níbí