Omotara: Mo kábámọ̀ ìwà tí mo hù sí ọmọ alágbe, mo wá a títí ṣùgbọ́n mi ò mọ ibi tó wà

Aworan Motara

Oríṣun àwòrán, MOtara/instagram

Gbajumọ ori ayelujara Naijiria tiṣẹ bọ lọwọ rẹ Omotara ti ni oun kabamọ iwa aibowọfọmọlakeji ti oun hu si ọmọde alagbe kan.

Ninu fọnran fidio kan to gboju ayelujara kan la ti ri ti o ti n fi ọti ẹlẹrindodo la ọmọde yi loju ti iwa yi si mu kawọn eeyan faraya si.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ BBC, Omotara sọ pe lati alẹ ọjọ ti fọnran fidio naa jade loun ti n sunkun toun ko si ri orun sun.

Omotara ni: ''Mo kan fẹ tọrọ aforijin nitori gbogbo nkan to ṣẹlẹ kan n waye lera wọn ni. Mi o kan ti ẹ mọ nkan ti mo fẹ se bayi.''

''Mo ti wa ọmọ naa titi. Mo lọ lọjọ Aje, ọjọ Iṣẹgun. Titi di ba ṣe n sọrọ yi mo tun wa a lọ ti mi o si ri''

O ni bi oun ṣe n wa ọmọ naa lọ ni oun n gbe nkan lọwọ lati fun un ṣugbọn awọn ko pade.

Omotara lose her Brothers Keeper

Oríṣun àwòrán, The LadyMOTARA

Omotara ni: ''Gbogbo nkan ti mo gbe lọ bi i ọti ẹlẹrindodo niṣe ni mo maa n gbe e fawọn ti mo ba ri nibẹ.

Wọn ni wọn ti gbe ọmọ naa lọ si ilẹ Ariwa pada''

Kini o ṣẹlẹ sẹyin?

Ladugbo Ketu ni iṣẹlẹ yiti waye. Awọn eeyan ilu Eko si faraya nigba ti wọn ri fidio naa to ya ninu ọkọ rẹ to n fi ọti ẹlẹrindodo la ọmọde naa loju.

Niṣe ni Motara n fi ọmọ naa ṣe yẹyẹ bo ti ṣe n tọrọ ọti ẹlẹrindodo to si n sare tẹle ọkọ.

Àkọlé fídíò, Eégun àti orò, bí wọ́n ṣe jọ bí Ẹ̀ṣà Egúngún nílẹ̀ Yorùba rèé

Awọn onibara to wa ni adugbo naa sọ pe awọn ko fẹ ki Omotara mọ ibi tọmọ naa wa nitori awọn ko fẹ ki nkankan ṣẹlẹ sii.

Gẹgẹ bi alaye ti Omotara ṣe pe alumajiri ni ọmọ naa.

Omotara ṣalaye siwaju fun ileeṣẹ BBC pe ''Nigba ti mo pada de ibẹ ni mo to mọ bi iwa ti mo hu ti ṣe buru to.''

Akẹkọgboye jade ni Poly Ibadan ọhun ni ''Mo ri awọn alagbe to ku ti wọn si bẹnu atẹ lu mi. Ẹbẹ ni mo ṣaa n bẹ ki wọn maa binu si mi. Mi o mọọmọ''

"Ọmọ atapata dide lemi naa, mo si tun jẹ Kristẹni. Eelo ni mo ti ni?

Kini mo ti da laye ti maa ma fi eeyan ṣe yẹyẹ?

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́

Lowurọ oni ti i ṣe ọjọ Kẹrindinlọgbọn, oṣu Kọkanla, oju opo ayelujara Twitter gbọn akanti rẹ yọ kuro loju opo wọn tori o tako ilana Twitter ati Instagram.

Ilana to dabi ẹni pe Motara tapa si ni eleyi to ni i ṣe pẹlu''Bibu eeyan tabi didunkooko mọ ẹni keji'' tabi eyi to ni i ṣe pẹlu Bibọwọ fawọn alabase loju opo Instagram.

Awọn ilana yii ti tako ki eeyan maa tabuku ọmọlakeji loju opo ayelujara.

Nibi tọrọ yi de bayi, awọn eeyan ilẹ Faranse naa ti mu ọrọ Omotara gbọ loju opo Twitter ti wọn si faraya gidi gan an.

Àkọlé fídíò, Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá: Kọ̀ síi nípa iṣẹ́ tí oúnjẹ ń ṣe lára níbí

Omotara pàdánù isẹ́ olówó ńlá nítorí ó fi ọtí ẹlẹ́rìndòdò sódà lá ọmọ alágbe lójú

Aibọwọ fọmọlakeji ti koba gbajugbaja orí ayélujára kan to fi padanu ìṣe àkànṣe olówó ńlá to n ṣe fun ileeṣẹ ọti ẹlẹrindodo Naijiria kan.

Ọrọ yi ko ṣyin bi fidio kan to ṣafihan bi o ṣe n fi ohun mimu naa la ọmọ alagbe kan to n tọrọ jẹ lọwọ rẹ loju ninu ọkọ lasiko sunkẹrẹ fakẹrẹ ṣe gbode.

Eekan ori ayelujara yii tawọn eeyan mọ si Motara fi fidio bi o ṣe n fi mínírà la ọmọdebinrin kan to n bẹ ẹ loju.

Motara si jẹ ki ọmọ yii sare le ọkọ rẹ tori ko kan le re kekere mu lara ọti ẹlẹrindodo naa.

Awọn ọmọ Naijiria ti gbana jẹ lorii fidio yii to bẹẹ tawọn kan n wọn kobiewu epe fun gbajugbaja ori ayelujara yii.

Harrison tweet

Oríṣun àwòrán, Twitter screenshot

Twitter screenshot

Oríṣun àwòrán, Twitter screenshot

Fidio to tan kalẹ yii jade lẹyin ọjọ diẹ ti Motara ṣẹṣẹ kọ itan soju opo rẹ to n ṣalaye bi nkan ṣe le fun oun ati iya rẹ ti iya n kiri ọja loju popo ko to wa di pe papa oko rẹ di tutu to di ọlọrọ.

Lawọn eeyan ba n fọnmu pe loun to mọ aawọ iṣẹ to si tọ ọ wo daadaa, ko yẹ ki Motara ṣe ọmọbinrin kekere yẹn bẹẹ.

Omotara lose her Brothers Keeper

Oríṣun àwòrán, The LadyMOTARA

Arabinrin Motara to n gbe niluu Ibadan yii fi sita pẹlu alaye pe oun kan n mu ọmọ naa ṣere ni ati pe oun pada fun un lowo.

Ṣugbọn alaye yii ko dabii pe o tẹ awọn ileeṣẹ to n ṣe ọti ẹlẹrindodo ti Motara fi n la ọmọ naa loju lọrun.

Ileeṣẹ Brothers Keeper to n ṣe ọti naa eyi ti Mọtara mu lọwọ ninu fidio ọhun ti fi atẹjade sita gbangba pe awọn yoo da gbajugbaja ori ayelujara yii duro gẹgẹ bii alukoro ati agbẹnusọ ileeṣẹ awọn.

Twitter screenshot

Oríṣun àwòrán, Twitter screenshot

Ileeṣẹ naa kọjalẹ pe ohun ti Motara ṣe lodi si igbagbọ ati afojusun awọn pe o n foju tẹmbẹlu eeyan.

Ni idahun, Motara ti fi ọrọ itọrọ aforiji sita fawọn ololufẹ rẹ pe oun ro pe ẹfẹ lohun ti oun ṣe yoo mu wa ni amọ oun tọrọ aforiji.

Ko jẹ bo ṣe jẹ, awọn ọmọ Naijiria ti n wa ọna ati kowojọ lati mu ọmọdebinrin alagbe naa kuro loju popo ki wọn si ran an lọ ileewe.

Twitter screenshot

Oríṣun àwòrán, Twitter screenshot

Twitter screenshot

Oríṣun àwòrán, Twitter screenshot