Akwa-Ibom:Mílíọ́nù mẹ́wàá Náírà ni ilé ẹjọ́ ni kí Kábíyèsí san gẹ́gẹ́ bí owó ìtaran ilẹ̀ tí ó gbà lọ́nà àìtọ́

Akwa-Ibom:Mílíọ́nù mẹ́wàá Náírà ni ilé ẹjọ́ ni kí Kábíyèsí san fún owó ìtaran ilẹ̀ tí ó gbà lọ́nà àìtọ́

Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́run kan tó fi ìlú Calabar ṣe ìbùjókòó, ti dája lórí ẹja ilẹ̀ kan láàrín ìjọba ìbílẹ̀ méjì ní Akwa Ibom.

Ó kéré tán ènìyàn márùn ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn, tí ọ̀pọ̀ ǹkan ìní sì sòfò ní ọdún 2017

Àwọn ìlú méjì kan, Ifa Ikot Akpan ní ìjọba ìbílẹ̀ Uyo àti Ibiaku Ishiet ní ìjọba ìbílẹ̀ Uruan tí àwọn ọba ìlú méjèejì, Etteidung Edem Aniedi Ebong àti olóyè William Effiong Etim sì ń léwájú nínú ìjà ilẹ̀ láti ọdún mẹ́ta sẹ́yìn.

Sùgbọ́n ìdájọ́ Adájọ́ Charles Ikpe to dá ẹja náà nù nítorí pé kò ní ẹ̀rí arígbámú tó dájú, èyí sì ló mú kí wọ́n mórí lé ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.

Nibe ni adájọ́ Hamma Akawu Barka, ni ilé ẹja gíga tó kọ́ka dá ẹja náà ko ṣe dáada tó pàápàá jùlọ̀ ni ti ìhà, Etteidung Ebong àti ìlú Ikot Akpan.

Nínú ìgbẹ́jọ́ ìgbìmọ̀ ẹlẹni mẹ́ta sàlàyé pé, ilé ẹja gíga kùnà, bi ó ṣe kọ̀ láti gba ẹrí tí wọ́n mú wá sílé ẹjọ́.

Ó dájọ́ pé, gbogbo ìlẹ náà ti wọn fi ṣe gáràjì kẹ̀kẹ́ ni agbàgbè náà ti olupẹjọ ti gbé fún ilé iṣẹ́ Gitto Construzioni Generali Nig Limited, agbègbè abúlé Ikot Akpan lo wa ni Etoi ìjọba ìbílẹ̀ Uyo ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom lo wa.

Ilẹ̀ náà ti di ti olùpẹjọ sílé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, bótilẹ il òun ti wa lọ́wọ́ olóye Etim àti awọn ará ìlú Ibiaku Ishiet níjọba ìbílẹ̀ Uruan yóò san mílíọ̀nù mẹ́wàá Naíra.

Ọba Etteidung Ebong dúpẹ lọ́wọ́ àwọn adájọ́ tó si ni ìgbàgbọ́ òun nínú ètò ìdája Nàìjíríà túbọ̀ ru sókè síi ni, o fí kun pé, òjú òun ri tó lásìkò tí ẹja náà ń lọ lọ́wọ́ lọ́wọ́ olùjẹ́jọ́.

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́