Taye Currency: Seyi Makinde fún Taye Currency lẹ́bùn ọkọ̀ bọ̀kìnnì Toyota Prado 2020

Oríṣun àwòrán, Instagram/Taye Currency
Ori lo mọ iṣẹ aṣela laye. Awọn kan yan iṣẹ orin kikọ laayo, amọ wọn o ri ṣe nibẹ nitori iṣẹ orin kọ lori ran wọn.
Ṣugbọn bii ti olorin Fuji, Ọgbẹni Taiwo Akande Adebisi ti ọpọ mọ si Taye Currency kọ nitori iṣẹ orin kikọ juu ṣe fun un.
Lopin ọsẹ yii ni Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde fi ọkọ jiipu bọginni Toyota Prado 2020 ta a lọrẹ.
- Wo àwọn èèkàn, ìlúmọ̀ọ́ka olórin tó ṣàbẹ̀wò sí ijọ Celestial Church ti Genesis Global
- Tí mi ò bá fẹ́ ìyàwó mi, n ó tí di àgbégbìn- Ayodele Fayose
- Wo bi wọ́n ṣe n ṣe àmójútó ilé ìjọsìn Prophet Israel Oladele, CCC Genesis Global
- Ẹ jọwọ, ẹ ba mi bẹ ìyàwó mi kí ìgbéyàwó mi ma baà túká - 9ice
- A kò tíì lè sọ pé ọmọ Ọba tuntun ni yóò jẹ Ooni lọ́jọ́ iwájú - Elebuibọn
- Èyí ni bí wọ́n ṣe pín fásitì LAUTECH láàrín ìpínlẹ̀ Oyo àti Osun
- Ọkùnrin tó pe ìyàwó rẹ̀ lájẹ̀ẹ́ tì í mọ́lé fọ́dún mẹ́rin, fún un lóyún nígbà mẹ́ta!
Taye Currency to fi ilu Ibadan ṣe ibugbe fi fidio ọkọ naa soju opo Instagram rẹ nibi to ti dupẹ lọwọ Gomina Makinde fun ẹbun nla to fun un.
''O ṣe Ọlọrun mi, eyi pọju. @seyi_amakinde jọ mi loju, o ya mi lẹnu. Mo dupẹ gan an fun ọkọ Toyota Prado 2020,'' ọrọ ti Taye Currency sọ niyii loju opo Instagram rẹ niyii.
Taye Currency ni ''ibukun aṣalẹ leleyi lati ọdọ Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde.
Olorin Fuji naa gbadura pe ki Eleduwa bukun orilẹede Naijiria, ki o si tun bukun ipinlẹ Oyo.
''Omi tuntun, igba ọtun, ipinlẹ Oyo, iṣẹ ya. Mo dupẹ lọpọlọpọ,'' Taye Currency lo sọ bẹẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Ẹwẹ, oṣu kejila ọdun 2019 ni Makinde yan Taye Currency gẹgẹ bi oludamọran rẹ lori ọrọ aṣa ati irinajo igbafẹ nipinlẹ Oyo.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Iroyin ti a gbọ nipe Gomina Makinde yan an sipo naa nirori iṣe takun takun to ṣe ṣaaju ibo gomina ọdun 2019 to gbe e wọlẹ gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Oyo.
















