Prophet Israel Oladele: Wo bi wọ́n ṣe n ṣe àmójútó ilé ìjọsìn CCC Genesis Global

Oríṣun àwòrán, Genesis global
Gẹgẹ bi akọsilẹ to wa lori ayelujara itakun agbaye ijọ CCC Genesis Global ṣe sọ, oun ni ijọ Celestial to tobi julọ, to si n yara dagba soke julọ ni agbaye.
Eeyan to le ni ẹgbẹrun mẹta lo ma n jọsin ninu ijọ naa ninu isin ọjọ Aiku.
Oludasilẹ ijọ naa, Alufaa Isreal Oladele Ogundipe, ni Oluṣọ ijọ naa.
Lẹyin rẹ, awọn oludari ati iranṣẹ Ọlọrun mejidinlogoji lo tun wa lẹyin rẹ.

Oríṣun àwòrán, Genesis global
Awọn ọkunrin ọlọla
Eyi ni ẹgbẹ awọn ọkunrin to n jọsin ninu ijọ CCC Genesis Global. Ohun ti wọn n ṣe ninu ẹgbẹ naa ni lati ma a kọ ara wọn ni ẹkọ lati jẹ ọkunrin gidi, gẹgẹ bi ọkọ, baba, oṣiṣẹ inu ijọ ati adari.

Oríṣun àwòrán, ccc genesis global/instagram
Ile ijọsin awọn ọmọde
Ibi yii ni awọn ọmọ wẹwẹ ati ọdọ ti ọjọ ori wọn wa labẹ ọdun kan si ọdun mẹtadinlogun ti ma n jọsin.
- Àwọn ìwàásù akọnilẹ́nu hàà tí Prophet Israel Oladele CCC Genesis Global ti ṣe rèé
- Wòlíì míì, tún wọ gàù lẹ́yìn tó tàpá sí ìlànà béèlì tí wọ́n fún un nílé ẹjọ́
- CCC Genesis Global: Ǹkan mẹ́wàá tí ẹ ò gbọ́ rí nípa Israel Oladele, Woli ìjọ Genesis Global
- Ẹ̀tanú pé Olùṣọ́ Genesis kò fẹ́ Laide Williams-Oni ló ṣe rán an lọ́ sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan - CCC Genesis Global
Ẹgbẹ awọn woli ọkunrin ati obinrin
Awọn wọnyii ni ariran, agbẹnusọ, iranṣẹ, oluṣọ. Ati aṣoju ninu ijọ naa, to ma n fi adura jagun. O jẹ akojọpọ awọn awọn woli to ma n sọ asọtẹlẹ, awọn to ma n la ala, ariran ati awọn to ma n fi ede oriṣiriṣi sọrọ.
Ẹgbẹ awọn ọmọ Sioni
Ẹka yii ni ti iṣẹ iranṣẹ awọn obinrin inu ijọ. Ikorajọpọ wọn ni lati ma a kọ awọn obinrin lati dagba ninu ẹmi. Awọn obinrin ti ọjọ ori wọn bẹrẹ lati ọdun mejidinlogun soke lo wa ninu ẹgbẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Genesis global
Ẹgbẹ awọn aladura
Awọn wọnyii lo ma n fi adura jagun fun awọn ọmọ ijọ naa, ati ẹnikẹni to ba fi ẹbẹ adura ranṣẹ sinu ijọ naa.
Ẹka igbani nimọran
Awọn to wa ninu ẹgbẹ yii lo ma n gba awọn ọmọ ni imọran lori lori ohunkohun ti wọn ba n la kọja.

Oríṣun àwòrán, Genesis global
Awọn aṣọna
Awọn wọnyii lo ma n duro ni awọn ẹnu ọna to wọ inu ṣọọṣi naa. Lara wọn lo tun ma n tun pẹpẹ ile ijọsin ṣe, ti wọn si tun ma n gba ọrẹ.
Yatọ si awọn ti a ka silẹ yii, awọn ẹka oriṣiriṣi lo tun wa ninu ijọ CCC Genesis Global, to ma n ko ipa lasiko isin.

Oríṣun àwòrán, Genesis global
Awọn akọrin-Ẹka awọn to n mojuto igbohunsafẹfẹ eto isin ninu ijọ naa.
Awọn lo ma n ya aworan ati fidio ti isin ba n lọ lọwọ, ati amojuto iṣẹ iranṣẹ ori amohunmaworan ijọ naa.
Ẹgbẹ awọn olukini -Awọn eeyan to ma n ki awọn alajo kaabọ sinu ijọ naa.
Ẹgbẹ awọn olufifunni -Awọn to wa ninu ẹgbẹ yii lo ma n ṣoju ijọ lati fun awọn ọmọ ijọ ti ko ni i, ni ounjẹ, owo ati aṣọ.

Oríṣun àwòrán, ccc genesis global/instagram
Wọn tun ma n ṣeto fifun awọn alaini awujọ ni iranlọwọ loṣooṣu.
Ẹgbẹ eleto ilera - Eyi ni ẹgbẹ awọn onimọ iṣegun oyinbo to ma n tọju awọn alaisan lasiko iṣẹ iranṣẹ ilera ọfẹ, ati ẹnikẹni to ba nilo itọju lasiko ti isin n lọ lọwọ.
Awọn eleto aabo - Ojuṣe awọn to wa ni ẹka yii ni lati daabo bo ile ijọin, awọn oṣiṣẹ ati awọn olujọsin ati dukia wọn, lọwọ ole, ati awọn iṣẹlẹ buruku miran.

Oríṣun àwòrán, Genesis global
Ikọ awọn alatunṣe - Awọn to wa ninu ikọ yii lo ma n tun inu ati ayika ile ijọsin ṣe lasiko ijọsin ati lẹyin rẹ.
Awọn olubẹwo - Awọn eeyan yi lo ma n ṣe amojuto awọn to ba ṣẹṣẹ darapọ mọ ijọ CCC Genesis Global. Wọn si tun ma n bẹ wọn wo lẹyin rẹ.
Awọn ajihinrere - Awọn to wa ni ẹka yii lo ma n kede ihinrere kaakiri lati jere ọkan fun Jesu.

















