Prophet Israel Oladele: Ẹ̀tanú pé Olùṣọ́ CCC Genesis Global kò fẹ́ Laide Williams-Oni ló ṣe rán an lọ́ sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan

Oríṣun àwòrán, Genesis Global
Igbakeji oluṣọ CCC Genesis Global, Olusọ Oba lo ṣiṣọ loju eegun lori iroyin pe wọn ti ran olusọ Israel Oladele Ogundipe lọ si ẹwọn ọdun kan lootọ eyi to jẹ awuyewuye tẹlẹ.
Olusọ Oba sọ fun BBc Yoruba wipe lọọto ni oluṣọ Genesis ti lọ si ọgba ẹwọn bayii ti yoo si lo ọdun kan nibẹ, amọ ọrọ naa ni kọnu-nkọhọ ninu.
Olusọ Oba fi ẹsun kan Laide Williams-Oni pe nitori ọrọ ifẹ ti ko wọ laarin awọn mejeeji nitori olusọ Genesis kọ lati fẹ arabinrin naa ni ọrọ ṣe ri bayii.
- CCC Genesis Global: Ǹkan mẹ́wàá tí ẹ ò gbọ́ rí nípa Israel Oladele, Woli ìjọ Genesis Global
- Wo àwọn èèkàn, ìlúmọ̀ọ́ka olórin tó ṣàbẹ̀wò sí ijọ Celestial Church ti Genesis Global
- Irọ́ ni CNN ń pa, àwọn ọmọ ogun Naijiria kò pa ẹnikẹ́ni ní Lekki Toll Gate - Lai Mohammed
- Àjọ AMCON gbẹ́sẹ̀lé gbogbo ǹkan ìní Jimoh Ibrahim tó lé ní N69 bíliọ̀nù
- Ìtàn ayé Abiola Peller, ọlọ́wọ́ idán tó fi ọ̀bẹ gé ìyàwó rẹ̀ sí méjì
- Wòlíì míì, tún wọ gàù lẹ́yìn tó tàpá sí ìlànà béèlì tí wọ́n fún un nílé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Genesis Global
Bawo ni aawọ laarin Laide Williams-Oni ati oluṣọ CCC Genesis Global ṣe ṣẹlẹ?
Igbakeji olusọ CCC Genesis Global, Olusọ Oba ni ọdun 2002 si ọdun 2006 si ni awọn mejeeji fẹ ara wọn gẹgẹ bi ololufẹ.
"O gbero lati fẹ ẹ sile gẹgẹ bi aya ni amọ nigba ti o di ọdun 2007 ni Genesis fi silẹ nitori o ri wi pe Laide ni ọkọ tirẹ si oke okun, pẹlu awọn ọmọ ti o ti bi sibẹ".

Oríṣun àwòrán, Facebook/Genesis Global
''Genesis bere imọran lọwọ ijọ pe ṣe ki oun fẹ ẹ, ki wọn to wa gba a ni imọran pe ko fi silẹ nitori o le ba ọjọ ọla rẹ jẹ''
''Wọn ni ki o fi silẹ nitori o le tabuku ba ọjọ ọla rẹ'.'
Bakan naa ni Genesis ri atẹjiṣẹ ti ọkọ rẹ kọ si Laide pe ko ma fi awọn silẹ ni oke okun pẹlu ọmọ ti o gbe lọwọ.
Nitori Laide ma n ṣe bii ẹni ti ko ni ọkọ to ba ti wa ni Naijiria, amọ ọkọ rẹ wa ni oke okun.''
Amọ, ni ọdun 2007 ti Genesis wa fẹ iyawo rẹ ni wahala bẹrẹ, ti Laide sọ wipe ki Genesis wa da gbogbo nkan to gba ni ọwọ ohun pada.
Ki lo mu ki adajọ ni ileẹjọ ni Naijiria ran Genesis lọ si ẹwọn ọdun kan?
Olusọ Oba ni Laide mọ awọn eniyan daadaa ni ipinlẹ Eko, paapaa awọn adajọ ni wọn ṣe da iru idajọ bẹẹ fun un.
Oba ni Laide ti leri wi pe ti Genesis ko ba fẹ oun, gbogbo ohun ini ti oun fun un ni o ma da pada fun oun.
''Lootọ ni Laide ran Genesis lati ba ohun ra ilẹ ni ọna mẹta, amọ Laide ri meji gba pada.''
Oluso Oba fi kun un pe 'kKo ri ẹyọkan gba pada nitori awọn to onilẹ ni wọn ko gbọdọ de ibi ilẹ naa mọ.''
Bakan naa ni Genesis jẹwọ wi pe lootọ ni oun sọ wi pe oun yoo da gbogbo owo ti oun gba pada ni ọwọ rẹ pada.
Ati awọn aṣọ pẹlu ohun ini to fi ranṣẹ si oun tabi to ra fun oun to ba n pada wa si Naijiria.
Nitori naa ni adajọ ṣe ni o jẹbi ẹsun iwa ole nitori o gba owo lọwọ obinrin naa, ti ko si da ilẹ rẹ pada fun un.
Ni adajọ wa ni ko lọ si ẹwọn ọdun kọọkan fun ẹsun ole ati iwa jibiti, amọ yoo lọ si ẹwọn naa papọ lẹẹkan.
Ṣe Genesis to wa ni ẹwọn yoo da ijọsin durọ ni Ọjọ Isinmi?
Olusọ Oba ni Genesis to wa ni ẹwọn fun ọdun kan ko ni da ẹsin durọ ninu ile ijọsin naa.
O ni pasitọ to lọ si ẹwọn ko le da isin duro nitori pe ijọ duro fun ara rẹ ni yatọ si olusọ.
Olusọ fi kun un wi pe eniyan daadaa ni Genesis, amọ ibanilorukọjẹ ni gbogbo ohun to waye yii.
Amọ, titi di asiko yii, a ko tii ri Laide Williams-Oni ba sọrọ lati sọ ti ẹnu rẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Genesis Global
Ṣaaju, awuyewuye to gbode ni pe ṣé lóòtọ́ ni pásítò ìjọ Celestial, Israel Oladele Ogundipe rẹ́wọ̀n he?
Ọpọlọpọ iroyin lo n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara lori iroyin pe olusọ ijọ Celestial Church of Christ, Genesis Global, Israel Oladele Ogundipe ti rẹwọn ọdun meji he lori ẹsun pe o lu obinrin kan to wa ni orilẹede Amerika ni jibiti.
Iroyin naa ni Adajọ Olabisi Akinlade ti ileẹjọ giga ni ipinlẹ Eko to ran an lọ si ẹwọn lori ẹsun oniga meje, amọ ti o da ẹsun marun un nu nitori ko fi idi mulẹ.
Wọn ni o lu arabinrin Olaide William Oni ni jibiti miliọnu mọkanla naira.
Amọ, iroyin naa ni Genesis sọ wi pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi pe e.
Igbiyanju wa lati pe olusọ Genesis sọrọ lori aago jasi pabo, amọ ọmọ ijọ rẹ to ba wa sọrọ ni wọn n ṣe isin lọwọ ni ile isin, amọ ko le fi idi rẹ mulẹ pe boya Genesis wa ninu ẹsin naa.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Genesis Global
Ẹwọn ọdun kan ni pásítò ìjọ Celestial ti Genesis Global, Israel Oladele Ogundipe ri he kii ṣe meji..
Bakan naa ni akọroyin kan sọ wi pe oun ba agbẹjọrọ Pasitọ Israel Oladele Ogundipe rẹ sọrọ, ati wi pe ẹwọn ọdun kan lo ri he kii ṣẹ ọdun meji.
'' Ohun to ṣẹlẹ ni wi pe Aunty Laide ati Genesis jẹ ololufẹ akọkọ si ara wọn, ati wi pe ọrọ naa ni bo ṣe jẹ ninu.''
Bakan naa ni akọroyin naa ni Ilẹ Gẹẹsi ni Aunty Laide wa kii ṣẹ orilẹede Amerika ti iroyin naa gbe jade.
O tun fikun wi pe ọdun 2007 ni wọn ti wa lori ọrọ naa, ti arabinrin Laide naa gbimọpọ pẹlu Bukky Jesse lati ran an lọ si ẹwọn bi wọn ṣe ṣe ni ọdun 2011'.
O pari ọrọ rẹ wi pe ki awọn eniyan gbọdọ kọ ọgbọn lara iṣẹlẹ naa nitori ti o ko ba ni fẹ obinrin gẹgẹ bi aya, ma gba owo ni ọwọ rẹ.
Bakan naa ni atẹjade kan fihan bi adari ijọ CCC Praiseville, Kunle Hamilton se bu ẹnu atẹ lu awọn olusọ ti wọn ko ko ara wọn nijanu.
















