EndSARS Protest: Wo bí olùwọ́de EndSARS, Eremosele Adene ṣe gba òmìnira lọ́wọ́ ọlọ́pàá

Eromosele Adene:
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọkan lara awọn oluwọde EndSARS Eromosele Adene ti gba ominira lọ si ile rẹ lẹyin ti wọn gba beeli rẹ tan.

Ileẹjọ Majisireeti gba beeli rẹ lẹyin ti adajọ wọgile aṣẹ ọlọpaa lati fi i silẹ latimọle lọjọ Iṣẹgun.

Ọjọ keje oṣu kọkanla ọdun 2020 ni awọn ọlọpaa mu Adene nile rẹ niluu Eko ti wọn si sọ ọ si atimọle.

Lẹyin naa ni wọn gbe e lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria niluu Abuja fun ifọrọwanilẹnuwo niwaju igbimọ oluwadii FCID.

Ọrọ Adene lu ori ayelujara pa lẹyin tawọn ọlọpaa gbe e nile rẹ nitori o wa lara awọn to kopa ninu ifẹhonuhan EndSARS.

Ọjọ kẹẹdogun ọsun kọkanla ọdun 2020 ni wọn gbe Adene pada si ilu Eko lati Abuja ni deedee aago mẹsan alẹ.

Miliọnu kan naira ni ileẹjọ fi gba beeli Adene ki o to gba ominira lọ si ile rẹ.

N1M ní iléẹ́jọ́ béèrè fún béèlì olùwọ́de EndSARS, Eremosele Adene

Ile ẹjọ́ majisireeti kan ipinlẹ Eko ti gba beeli Eremosele Adene ti wọn fẹsun kan pe o ṣe onigbọwọ awọn oluwọde EndSARS nipinlẹ naa.

Eyi ti sọ awọn ọdọ to wa nile ẹjọ fun idajọ naa sinu ayọ ohun idunu pe nigbẹyin gbẹyin Eromosele yoo le lọ ile.

Eremosele Adene

Oríṣun àwòrán, Eremosele Adene

Lara ohun ti adajọ ti adajọ ṣe ni pe o gba ọrọ ti agbẹjọro ẹni afẹsunkan sọ pe ki wọn faaye gba ẹtọ onibara oun.

Bakan naa o ni onibara oun ni iṣoro ilera nitorinaa ki wọn gba beeli rẹ paapaa toripe ko da ẹṣẹ kankan to fi yẹ ki wọn fiya jẹ ẹ.

Àkọlé fídíò, Bí o bá bá ààrùn ìpẹ́pẹ́ gbígbẹ lára arẹwà obìnrin rẹ̀, kí loó ṣe?

Si eyi, agbẹjọro alatako ni ẹtọ eeyan ṣee bo mọlẹ to ba jẹ pe nitori ifẹ ilu ni.

Nitorinaa, igun mejeeji lo gbe ọrọ wọn kalẹ pẹlu ọgbọn ori.

Ẹwẹ, ile ẹjọ ni awọn yoo gba beeli rẹ pẹlu oniduro meji to gbudọ jẹ awọn to ni ileeṣẹ ara wọn.

Lafikun, ileẹjọ ni awn oniduro mejeeji yoo san miliọnu kọọkan naira wọn si gbudọ jẹ ọmọ Naijiria to n san owo ori deede.

Kò tọ́ sí Ọlọ́pàá láti ti ọmọ mi mọ́lé tórí ore tó ṣe lásìkò ìwọ́de EndSARS!

Aworan Eremosele ati iya rẹ.

Iya to bi ọkan lara awọn oluponlongo to ṣe agbatẹru iwọde EndSARS to waye laipẹ yii ni ipinlẹ Eko, Eromosele Adene to wa latimọle ọlọpaa ti faake kọri nile ẹjọ.

Arabinrin naa sọ fun BBC Yoruba pe o yẹ ki ijọba pese iṣẹ ọwọ fun awọn ọmọ Naijiria to ti kẹkọ gboye ṣugbọn ti ko ni iṣẹ lọwọ.

O ni idi gaan niyi ti ọmọ oun, Eremosele nigba to ba ara rẹ laarin awọn oluwọde EndSARS pinu lati gbọ bukata wọn nipa ṣiṣe onigbọwọ awọn oluwọde naa to jẹ ọdọ bii tirẹ.

Eremosele nile ẹjọ
Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Awọn ọlọpaa kọkọ de awọn ọdọ lọna lati wọle

Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn naa too jẹ olorin ati oluṣe ẹyinju aanu farahan nile ẹjọ lẹyin ọjọ mẹsan ti wọn fi ẹsun kan an pe o da omi alafia ilu ru.

Lẹyin eyi ni ileeṣẹ ọlọpaa tun kọwe si ile ẹjọ lati fun wọn laṣẹ lati ti i mọle fun ọgbọn ọjọ mii ki wn lee raye ṣe iwadii wọn daadaa. Ṣugbọn agbẹjọro tirẹ naa n ba wọn fa a pe wn n tẹ ẹtọ rẹ loju mọlẹ ni wipe ohun to tọ ni ki wọn yaa gba beeli rẹ.

Ni ile ẹgbọn rẹ obinrin ni awọn ọlọpaa ti lọ gbe e, ẹgbọn rẹ si ni awọn ọlọpaa o tilẹ fi to agbẹjọro rẹ tabi mọlẹbi r leti ki wọn to tun ti i lọ si ipinlẹ Eko. O ni ọna awọn ọlọpaa lori ẹjọ yii ko mọ rara.

Àkọlé fídíò, Awọn oluwọde ENDSARS ba BBC sọrọ

"Eyi ni wọn n da ọmọ mi lẹjọ fun o leyi to si jẹ pe ohun to maa n wu u lati ṣe latinu ọkan rẹ ni o ṣe yii". Iṣẹ ounjẹ tita naa ni arakunrin yii n ṣe gẹg bi iya rẹ ṣe fi to awọn oniroyin leti.

Koda iya yii ni Eremosele ja fitafita fun awọn ọlọpaa Naijiria ti wọn si wa n rẹrin musẹ bayii ti wọn n gba owo oṣu gọbọi nitoripe igbesẹ awọn ọdọ Naijiria mu wọn ja gbangba.

Gba gba gba lawọn ọlọpaa wa ni ile ẹjọ Majisireeti Yaba ti wọn ti n gbọ ẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan Eremosele.

Ni kete ti o farahan nile ẹjọ ni wọn ti gbe e fii lọ sinu ile lai jẹ ko foju kan awọn eniyan rara.

Àkọlé fídíò, Eégun àti orò, bí wọ́n ṣe jọ bí Ẹ̀ṣà Egúngún nílẹ̀ Yorùba rèé