EndSARS: Àwọn ayédèrú ìròyìn tó gbà'gboro kan lásìkò ìwọ́de #EndSARS

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn ọdọ kan lorilẹede Naijiria ya wọ igboro lati wọde tako wahala ati iwa kotọ awọ ọlọpaa lorilẹede Naijiria fun bi ọsẹ meji ki awọn janduku to ja a gba mọ wọn lọwọ.
Nibayii awọn ọdọ ti wa ya wọ ile, bẹẹni ijọba kaakiri awọn ipinlẹ lorilẹede Naijiria si ti wa kede konile o gbele lati lee da alaafia pada silu ṣugbọn awọn eeyan ṣi n sọrọ lori ayelujara nipa rẹ.
Ara awọn ohun to ṣokunfa laaṣigbo to ti ara iwọde naa ṣẹyọ ni oniruuru iroyin ofege gbogbo to lu ori ayelujara pa.
Diẹ lara awọn iroyin naa ni a fẹ gbe yẹwo lati mọ awọn to jẹ ayederu ninu wọn atawọn to jẹ otitọ.
Arabinrin oluwọde ti ọlọpaa ko pa awọn arakunrin rẹ

Aworan kan jade lori ayelujara to ṣafihan arabinrin kan, Ugwu Blessing Ugochukwu to joko sori ere kan pẹlu omije loju ati aṣia orilẹede Naijiria lọwọ rẹ eyi to rinlẹ lori ayelujara.
Arabinrin naa ni awọn ọlọpaa ti pa awọn arakunrin oun, wọn si ti ju wọn si inu kọnga.
Lootọ ni aworan naa han pe arabinrin yii darapọ mọ iwọde ni ẹkun ila oorun gusu orilẹede Naijiria, ṣugbọn ikọ ọlọfintoto BBC ti a mọ si BBC Reality Check kan si arakunrin kan to sun mọ arabinrin Ugochukwu, ti wọn pe orukọ́ rẹ ni Gideon Obianime. O ni ko sohun to jọ ọ.
O ni lootọ ni ikọ SARS ti arabinrin naa mọle lawọn akoko kan ni ọdun 2018 ṣugbọn ko si eyikeyi arakunrin rẹ kankan ti ikọ naa pa.
Bi eeyan gbe aṣia orilẹede Naijiria dani, ko daabo bo lọwọ ikọlu ologun

Ahesọ ọrọ yii jade pe ṣọja ko lee yinbọn pa ẹnikẹni to ba n mu aṣia orilẹede Naijiria dani.
Pẹlu pe ko si ẹri fun eyi, nṣe ni ahesọ yii di kale n kako lori ayelujara.
Amọṣa, ko si ẹri to gbe ọrọ yii nidi.
A ti beere lọwọ awọn ologun boya wọn kii yinbọn fun ẹnikẹni to ba di aṣia orilẹede mu, ṣugbọn wọn ko tii dahun.
Ko si igba kankan ti agbẹnusọ fun aarẹ Buhari, Fẹmi Adeṣina pe iwọde #EndSARS ni "ere Ọmọde"

Nigba ti iwọde naa kọkọ bẹrẹ, fidio kan jade sita eyi to ṣafihan agbẹnusọ fun aarẹ Buhari, Fẹmi Adeṣina bi ẹni pe o n pe iwọde naa ni ere ọmọde
Ọpọ lo n wo Fẹmi Adesina gẹgẹ bi ẹni to n fi iwọde naa ṣe yẹyẹ.
Amọṣa, fidio ọjọ to ti pẹ sẹyin ni lasiko ti agbẹnusọ fun aarẹ Buhari, Fẹmi Adeṣina fi n ba ikọ ileeṣẹ iroyin abẹle Channelstv sọrọ lori iwọde miran to waye nigba naa.
Iwọde ẹbẹ kan ti a mọ si Revolution Now ni agbẹnusọ fun aarẹ Buhari, Fẹmi Adeṣina n sọrọ nipa rẹ ninu fidio naa, oṣu meji sẹyin ki iwọde #EndSARS Now to waye ni iwọde ti a n sọrọ rẹ yii ti waye, ti ọrọ naa si ti jade.
'Ayederu' fifọ ile itaja nla, ṣugbọn ti kii ṣe ayederu

Fidio kan jade nipa wahala to waye ni ile itaja nla kan ni ipinlẹ Ọṣun nibi ti awọn eeyan kan ti lọ fọ ileetaja nla naa ti wọn si ko ẹru olowo iyebiye lọ.
Ori oju opo Twitter kan to jẹ ti ẹgbẹ oṣelu APC nilẹ Gẹẹsi ni o ti jade pe awọn oluwọde lo n ji ẹru ko.
Amọṣa awọn eeyan kan lori ayelujara ti ṣalaye pe irọ nla gbaa ni iroyin ti ẹgbẹ oṣelu naa gbe. Wọn ni kii ṣe fidio EndSARS ni koda fidio iṣẹlẹ laaṣigbo 'ẹ kuro lorilẹede wa'to waye ni South Africa ni fidio naa jẹ.
Nigba ti BBC ba ọkan lara awọn to ni ile itaja naa sọrọ o fi idi rẹ mulẹ pe lootọ ni wọn fọ ṣọọbu awọn lasiko laasigbo naa ni South Africa, amọṣa awọn ti pada si ẹnu owo bayii.
Awọn Biṣọọbu ijọ Aguda ni Naijiria ati iwọde EndSARS

Ọkan lara awọn iroyin to jade loju opo Twitter ti ọpọlọpọ si gba bi ẹni gba igba ọti ni iroyin kan to tọka si awọn Biṣọọbu ijọ Aguda kan pe awọn naa wọde lati ṣatilẹyin fun iwọde EndSARS.
Amọṣa, aworan yii kii ṣe ti isinyi, ti ọjọ pipọ sẹyin ni.
Ayẹwo aworan lọna igbalode lori ayelujara fihan pe ni oṣu kẹta ọdun 2020 ni aworan iṣẹlẹ naa ti waye lasiko ti awọn Biṣọbu ijọ Aguda lorilẹede Naijiria ṣe ipade apapọ wọn, (CBCN) ni ilu Abuja ti wọn si wọde lati fi ẹhonu han lori iṣẹlẹ ipaniyan ati ijinigbe to wa di tọrọfọnkale nigba naa.
Lootọ awọn ẹgbẹ Bisọbu Aguda fi atẹjade sita ti wọn fi fi atilẹyin han fun iwọde awọn ọdọ lori wahala awọn ọlọpaa to waye ṣugbọn ko si igba kankan ti wọn jade sita lati darapọ mọ iwọde naa.
Afikun iroyin lati ọwọ Linnete Baahati ti ẹka BBC Monitoring ati Yẹmisi Adegoke ti BBC Africa.












