EndSARS Protest Update: Àwọn olórí orílẹ̀èdè yí nígbàkanrí sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà láti dẹ́kun ìwọ́de ọ̀dọ́ lọ́jọ́ iwájú

Oríṣun àwòrán, Presidency nigeria
Awọn olori orilẹede Naijiria nigbakan ri ti mu amọran wa lori bi orilẹede Naijiria ṣe le dena irufẹ iwọde to waye lori #EndSARS eleyii to fa rogbodiyan ti ko lẹgbẹ lawọn ipinlẹ kan lorilẹede Naijiria.
Nibi ipade finukonu ti wọn ṣe pẹlu aarẹ Muhammadu Buhari lori wahala to ṣẹyi lasiko ati lẹyin iwọde naa lawọn olori orilẹede Naijiria nigba kan ri naa ti jẹ ko di mimọ pe omi nii poro ina, ojo ni poro ọgbẹlẹ, ohun to lee pa oro irufẹ wahala bẹẹ ni ipese iṣẹ fun awọn ọdọ, mimu ọrọ aje gbooro sii ati ṣiṣeto ọna fun awọn oludokoowo lati ilẹ okeere lati wọle wa.
- Òkú ọ̀dọ́ 15 ni mo kà ní Lekki amọ́ mo kábàámọ̀ pé a gbà kí ológun gbé okù wọn lọ - DJ Switch
- Awọn jàndúkù yabo ilé Sẹ́nétọ̀ Teslim Folarin, wọ́n kó ẹ̀rọ ata, ọ̀kadà, fírìíjì àti àwọn nkan tí owó rẹ̀ tó N200m
- ₦147m la rí kójọ fún ìwọ́de, a kò fẹ́ owó mọ́, ìwọ́de ti parí - Feminist Coalition
- Májèlé olóró lẹ gbé l‘Ekiti dípò èròjà oúnjẹ Covid-19 - Ariwo sọ lórí ayélujára
Lara awọn olori orilẹede Naijiria to kopa ninu ipade naa eleyii ti wọn ṣe lori ayelujara ni Ọgagunagba Yakubu Gowon, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, Ọgagun Ibrahim Babangida, Oloye Ernest Shonekan, Ọgagun Abdusalami Abubakar pẹlu aarẹ ana, Goodluck Jonathan.
Awọn olori orilẹede Naijiria naa ṣalaye, ninu atẹjade kan ti Fẹmi Adeṣina to jẹ agbẹnusọ fun aarẹ Buhari, pe ko tọna bi awọn eeyan kan ṣe lo anfani rukerudo naa lati maa tan ina ipinya lorilẹede Naijiria.
Bakan naa ni wọn tun ba mọlẹbi awọn eeyan to padanu ẹmi wọn lasiko rogbodiyan naa kẹdun.
Wọn fi kun un pe lootọ lawọn araalu lẹtọ lati se iwọde wọọrọwọ, ko si si ijọba kan to lee tako eyi.
Ikú Aráàlú 51, ọlọ́pàá 11, Sọ́jà 7 tó kú lásìkò ìwọ́de EndSARS dùn mí - Buhari

Oríṣun àwòrán, @MBuhari
Aarẹ Muhammadu Buhari ti fidi rẹ mulẹ pe, ẹmi eeyan mọkandinlọgọrin lo sọnu nitori rogbodiyan to waye ninu iwọde EndSARS kaakiri Naijiria.
Buhari lo fidi ọrọ naa mulẹ nigba to n ṣe ipade pẹlu awọn Aarẹ Naijiria tẹlẹ ri.
Àwọn tó wà níbi ìpàdé náà ni Oloye Olusegun Obasanjo, Goodluck Ebele Jonathan, Yakubu Gowon, Abdusalam Abubakar àti Ernest Shonekan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Apena fẹ́gbẹ́ Oṣugbo, Opa, Akala àtẹ̀yin awo, ẹ wa ọ̀pá àṣẹ Ọ́ba Akiolu jáde"
- Ẹ wo ọ̀rọ̀ àwọn Wòlíì tó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ saájú nípa làásìgbò EndSARS
- Májèlé olóró lẹ jí l‘Ekiti dípò èròjà oúnjẹ Covid-19 - Ariwo sọ lórí ayélujára
- Ẹ sọ́ra fún ìwà olè àti jàgídíjàgan nílẹ̀ Yorùbá-Sunday Igboho
- ₦147m la rí kójọ fún ìwọ́de, a kò fẹ́ owó mọ́, ìwọ́de ti parí - Feminist Coalition
- Sanwo-Olu kéde ìlànà ìséde tuntun l'Eko
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn kan se lọ pín "CaCovid 19 Palliative" ní Ilorin pé...
- Àìsọ̀rọ̀ Buhari lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki, ìkọjú ìjà sí Yoruba ni - YWC
- Kò sọ́rọ̀ nínú ọ̀rọ̀ Buhari, àtúntò Nàíjíríà nìkan lọ̀nà àbáyọ - Àgbà Yorùbá
O ni lara awọn to ku ni ara ilu mọkanlelaadọta, ọlọpaa mọkanla ati ṣọ́ja meje.
Buhari wa kede pe iku awọ̀n eeyan naa dun oun pupọ, to si ni irufẹ ajalu bayii ko yẹ ko waye rara, ti ko si nitumọ.

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident
Wahala bẹ silẹ lọjọ Iṣẹgun ni nnkan bii aago meje ku iṣẹju marundinlogun, nigba ti awọn ọmọ ologun dana ibọn ya awọn oluwọde ni Lekki Toll Gate, to wa ni ilu Eko.
Lẹyin iṣẹlẹ naa ni awọn eeyan tu si igboro ti wọn si bẹrẹ si n dana sun awọn agọ ọlọpaa, ile ijọba ati dukia ilu.
Buhari sọ fun awọn Aarẹ tẹlẹri naa pe, gbogbo ohun ti awọn oluwọde n beere fun ni ijọba oun ti gbọ, awọn yoo si ṣiṣẹ le lori.

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina
Agbẹnusọ Aarẹ kan sọ fun BBC pe, Aarẹ fidi rẹ mulẹ fun awọn Aarẹ tẹlẹ naa pe, eeyan mọkandinlọgọrin lo ku nitori iṣẹlẹ naa, ṣugbọn ko ṣalaye boya awọn eeyan to gbẹmi mi ni Lekki wa lara awọn ti Buhari darukọ.
Buhari wa fọwọ gbaya pe oun yoo ri daju pe aabo wa fun ominira ati ẹtọ araalu, ti oun si setan lati raga bo isọkan orilẹede Nàíjíríà.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Kunle Olajide ni Ìjọba tó ń tẹ̀lé òfin kò ní wu ìwà tí Buhari ń wù

Oríṣun àwòrán, @MBuhari
Awọn ọmọ Naijiria kan tun ti sọ ero ọkan wọn lori ọrọ ti Aarẹ Muhammadu Buhari ba wọn sọ lẹyin rogbodiyan to waye nitori iwọde EndSARS.
Akọwe agba ẹgbẹ awọn agbaagba ilẹ Yoruba, Yoruba Council of Elders, Dokita Kunle Olajide lo sọ bẹẹ fun BBC Yoruba.
O ni Aarẹ ko sọrọ nipa ohun ti awọn ọmọ Naijiria n reti ko sọ, ṣugbọn ọna miran lo ya si.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo nǹkan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọba tí wọ́n bá gbé ọ̀pá àṣẹ rẹ̀ lọ nílẹ̀ Yorùbá
- Àìsọ̀rọ̀ Buhari lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki, ìkọjú ìjà sí Yoruba ni - YWC
- ₦147m la rí kójọ fún ìwọ́de, a kò fẹ́ owó mọ́, ìwọ́de ti parí - Feminist Coalition
- Wo ìròyìn, àwòrán àti fídíò èké nípa ìwọ́de EndSARS
- Super Eagles, ẹ máṣe gbá bọ́ọ̀lù fún Nàìjíríà mọ́ nítorí ìhà tí ìjọba kọ sí ìwọ́de EndSARS - John Ogu
- Ará Eko, ẹ pariwo ó tó gẹ́ẹ́ lórí làásìgbò tó gbòde torí ìwọ́de EndSARS - Sanwo-Olu
- Ọ̀tá Yorùbá ló lo ìwọ́de láti dojú ogun kọ wá - OPC
- "Àwọn ọ̀tá Nàíjíríà tó fẹ́ dojú ìjọba bolẹ̀ ló wà lẹ́yìn ìwọ́de EndSARS"
- Ó parí ni ohùn tó gbẹnu ọ̀pọ̀ ọmọ Nàíjíríà lẹ́yìn ọ̀rọ̀ Buhari
Olajide sọ pe "lakọkọ, o yẹ ko kọkọ ba awọn ẹbi awọn to padanu ẹmi wọn ni Lekki kẹdun, ko si gbadura pe iru rẹ ko ni waye mọ."
"Lẹyin naa, ko tun fi da wọn loju pe gbogbo awọn to lọwọ ninu ikọlu naa ni ijọba yoo fi imu wọn danrin."
Akọwe YCE ọhun ni o yẹ ki Aarẹ Buhari rawọ ẹbẹ si awọn ọdọ, ko si rọ awọn obi wọn pe ki wọn bawọn sọrọ, ki wọn le dawọ iwọde naa duro dipo bawọn ologun ṣe ṣina ibọn fun wọn.
Olajide wa gba Aarẹ nimọran pe o yẹ ki atunto de ba bi ijọba Naijiria ṣe n lọ, ki alaafia le jọba.
Ẹwẹ, agbẹjọro ati ajafẹtọ ọmọniyan kan, Dele Farotimi sọ pe, isọkusọ ni ọrọ ti Aarẹ ba awọn ọmọ Naijria sọ ninu igbohunsafẹfẹ to ṣe.
Farotimi sọ fun BBC Yoruba pe, Aarẹ Buhari ko tẹle ofin lo jẹ ki wọn maa pa eeyan ninu ijọba rẹ, ti ko si ṣe bi ẹni pe nkan babara n ṣẹlẹ.
O ni awọn fidio to wa kaakiri to ṣafihan bi awọn ọlọpaa ṣe n pa eeyan ju mẹwaa lọ, ṣugbọn Aarẹ sebi ẹni ti nnkankan ko ṣelẹ.
Ni ti awọn oluwọde, o ni ki wọn kọkọ pada sinu ile wọn na, ki wọn si ṣe ijiroro lori igbesẹ to kan.
Àwọn ọmọ Nàìjíríà bu ẹnu àtẹ́ lu Ààrẹ Buhari lórí ọ̀rọ̀ tó bá ará ìlú sọ

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina
Ọpọ awọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ si n fi ero wọn han lẹyin ti Aarẹ Buhari ba wọn sọrọ tan lalẹ Ọjọbọ.
Ninu igbohunsafẹfẹ naa ni Aarẹ ti kọkọ ka awọn aṣeyọri rẹ lati igba to ti gori alefa, lẹyin naa lo kede pe, ijọba ti n gbe igbesẹ lati ṣeto ẹkunwo owo oṣu fun awọn oṣiṣẹ ọlọpaa.
Bakan naa lo tun paṣẹ fun awọn agbofinro lati pana iwọde to n da rogbodiyan silẹ ni Naijria.
- SERAP gbé ìjọba àpapọ̀ lọ ilé ẹjọ́ àgbáyé ICC lọrí ẹ̀sùn ìpànìyàn
- "Jàǹdùkú gún ẹ̀gbọ́n mi lọ́rùn, jó ilé àti mọ́tò wa méjì, kòròfò la wà"
- Olùwọ́de 12 kú ni Lekki, 38 lapapọ kú lọ́jọ́ Isẹ́gun, 56 ni àròpọ̀ àwọn tó bá ìwọ́de lọ - Amnesty International
- Osinbajo gbarata lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki, ó ní ìdájọ́ òdodo yóò wà
Ṣugbọn pupọ awọn ọmọ Naijiria lo n sọ pe, ohun ti awọn n reti pe ki Aarẹ sọ, kọ lo ba awọn sọ.
Koda, o pari ni ọrọ ti ọpọ ọmọ Naijiria n kọ loju opo Twitter wọn, to si foju han pe, ohun to wa ninu ọrọ aarẹ naa ti toju su wọn.

Oríṣun àwòrán, State House
Bi wọn ṣe n sọko ọrọ lori ikanni ayelujara Twitter naa, ni wọn bu ẹnu ẹtẹ lu Aarẹ loju opo Facebook.
Bakan naa ni awọn kan naa n sọ pe, adiye Buhari kuku n laagun ṣugbọn iyẹ ara rẹ ni ko jẹ ka mọ.
Eyes Allison lori Twitter sọ pe, "o yẹ ki awa ọdọ orilẹ-ede yii ji giri, kii ṣe akoko yii lo yẹ ka simi, iranu ni gbogbo eyi ti Aarẹ n sọ."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Kenolisa ni "ọlọlajulọ, ẹ jọ ibeere temi ni pe, ki ni ohun gan pato ti ẹ ni fun awọn ọdọ orilẹ-ede yii?
Edwared Boye ni tirẹ sọ pe "Aarẹ, o dami loju pe ẹ ko tii ri awọn fidio to n tan ka lori ayelujara nibi ti wọn ti pa awọn oluwọde ni Lekki."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ni ti Titilope Oyewusi, epe lo fi ranṣẹ si Aarẹ nigba to n ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lọwọ.

Oríṣun àwòrán, Facebook
Imọran ti Aminat Yetunde Olanrewaju Aminu fun Aarẹ ni ti rẹ ni pe, ko fi ijọba silẹ fun awọn ọdọ lati maa dari.
Wo awọn nnkan miran ti awọn ọmọ Naijiria n sọ si Aarẹ.


Ààrẹ̀ Buhari ní ọ̀dọ́ tó bá tún ba dúkìá ìlú jẹ́ yóò fojú winá òfin kíkọlu àbò ìlú

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina
Saaju la ti sọ fun yin pe, Aarẹ Buhari ti ke si awọn ọdọ to n wọde kaakiri orilẹede Naijiria lati pada sile olukaluku wọn ki wọn si dẹkun iwa bẹẹ nitori ẹdun ọkan wọn ti wọn fẹ ki ijọba gbọ ti dun korokoro leti oun ati ijọba oun.
Aarẹ Buhari ti ni ijọba oun ko ni faaye gba ẹnikẹni lati maa ba awọn dukia ilu jẹ ati pe ẹnikẹni to ba ṣe bẹẹ n gbena woju abo orilẹede Naijiria ni ati pe ẹnikẹni to ba ṣe bẹẹ yoo foju wina ofin to ba yẹ.
Aarẹ Muhammadu Buhari ba awọn ọmọ orilẹede Naijiria sọrọ loni lori wahala to ti jẹyọ pẹlu iwọde #EndSARS to gbode lorilẹede Naijiria.
Aarẹ Buhari ni oun ko ṣai mọ ipenija araalu lori iwa kotọ awọn ọlọpaa ikọ SARS naa.
O ni lootọ araalu lẹtọ lati wọde ki wọn si fi ẹhonu wọn han gẹgẹ bi iwe ofin Naijiria ṣe laa kalẹ,
Amọṣa ofin naa jẹ ko di mimọ pe ko si araalu ti iwe ofin fun laaye lati fi erongba ti fi ẹhonu rẹ han fi di araalu miran lọwọ.
O nigbogbo awọn ẹhonu marun un ti wọn fi kalẹ ni ijọba oun tẹwọgba ti oun si ti bẹrẹ igbesẹ lori rẹ.
Aarẹ Buhari mẹnu ba awọn iwa ikọlu gbogbo tawọn oluwọde naa ti gbe ṣe eleyi to si ni o mu ibanujẹ ba oun gẹgẹ bi aarẹ, paapaa julọ iku awọn eeyan kan lasiko naa.
Bakan naa ni aarẹ Buhari tun bu ẹnu atẹ lu ohun to pe ni iroyin ofege kaakiri awọn iroyin ori ayelujara gbogbo eleyi to ni o ti kun orilẹede Naijiria ni awọ ti ko tọ lawujọ agbaye.
O ni irọ ni pe ijọba oun ko ni itara nipa aabo ẹmi ati dukia awọn ọmọ orilẹede Naijiria nitoripe oniruuru igbesẹ ati eto ni oun ti gbe kalẹ lati rii pe aye dẹrun fun araalu.
Aarẹ Buhari fi kun un pe ijọba oun ti dari ajọ to n ri si eto owo oṣu fawọn oṣiṣẹ ọba lorilẹede Naijiria lati tete ṣe iṣẹ lori afikun owo oṣu awọn ọlọpaa atawọn oṣiṣẹ ajọ alaabo yoku lorilẹede NAijiria ki o lee kun oju iwọn.
Aarẹ ni ki awọn orilẹede agbaye maa gbọ ọrọ lagbọye ki wọn to maa gbe ọrọ kalẹ nipa orilẹede Naijiria.
Saaju ni BBC ti beere pe:
Kí làwọn kókó ohun tí Ààrẹ Buhari yóò bá ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀ l''aago méje alẹ́ òní?
Aarẹ Muhammadu Buhari yoo ba awọn ọmọ orilẹede Naijiria sọrọ ni agogo meje ọjọbọ.
Amugbalẹgbẹ fun aare lori ọrọ iroyin, Fẹmi Adesina lo sọ eyi.
O ni lẹyin ipade rẹ pẹlawọn ọmọ igbimọ abo ni Naijiria aarẹ yoo sọrs lori hilahilo to n waye lati igba ti iwọde #EndSARS ti dẹsẹru bi ẹsẹ telọ.
A n se akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin yajoyajo lọwọ, a o maa gbe ẹkunrẹrẹ iroyin naa sori atẹ iroyin wa laipẹ. Ẹ jọwọ, ẹ tun oju opo iroyin yi yẹwo, ki ẹ lee ri ẹkunrẹrẹ iroyin ọtun laipẹ.















