EndSARS protest Update: Afẹnifẹre ní ara ti kan àwọn èèyàn, ìjọba sì ló fà á

Ẹgbẹ afẹnifẹre ti sọ pe atunto ni ọna abayọ kan ṣoṣo si iṣoro.
Akọwe ẹgbẹ naa, Yinka Odumakin lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba.
Odumakin sọ pe, ohun to n ṣẹlẹ lọwọ pẹlu iwọde EndSARS kii ṣe ọrọ ẹlẹyamẹya, ṣugbọn o ti pẹ ti ara ti n kan awọn eeyan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Buhari kọ́ ni ìṣòro wa, bó ṣe wà láti láéláé rèé - Fr Mbaka
- Àwọn ọ̀dọ́ fi ọ̀nà àrífín pe Tinubu lórí aago àmọ́ ó ní òun kò mọwọ́-mẹsẹ̀ nípa ìpànìyàn Lekki
- Á ràgà bo CCTV Lekki bí i ẹ̀rí tó dájú fún ìwádìí ìpànìyàn - Sanwo-Olu
- SERAP gbé ìjọba àpapọ̀ lọ ilé ẹjọ́ àgbáyé ICC lọrí ẹ̀sùn ìpànìyàn
- "Jàǹdùkú gún ẹ̀gbọ́n mi lọ́rùn, jó ilé àti mọ́tò wa méjì, kòròfò la wà"
- Olùwọ́de 12 kú ni Lekki, 38 lapapọ kú lọ́jọ́ Isẹ́gun, 56 ni àròpọ̀ àwọn tó bá ìwọ́de lọ - Amnesty International
- Osinbajo gbarata lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki, ó ní ìdájọ́ òdodo yóò wà
- Ooni Ogunwusi àti Wole Soyinka kòrò ojú sí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Tollgate
O ni "awa ko fi ọwọ si pe ija ti awọn eeyan n ja jẹ ti ẹlẹyamẹya, ṣugbọn ara n ni awọn eeyan naa, ni wọn fi ṣe ohun ti wọn n ṣe."

Oríṣun àwòrán, @AmnestyNigeria
Akọwe Afenifere naa ni ohun to yẹ ki ijọba ṣe ni ko wa ọna lati yanju iṣoro to wa nilẹ dipo ko maa yinbọn pa awọn eeyan ilu.
Odumakin wa gba ijọba ni imọran pe o yẹ ko dahun ohun ti awọn eeyan n beere.
O ni "lọna kinni, o yẹ ki ijọba ṣe ohun ti awọn eeyan n bere, lẹyin naa, o yẹ ki a bẹrẹ atunto ilu yii ni kiakia.
Ọmọ ẹgbẹ Afenifere ọhun sọ pe iya n jẹ awọn eeyan, nitori naa o yẹ ki ijọba wa gbogbo ọna lati tan ijiya wọn dipo ko maa ṣina ibọn bo wọn.
ShopRite, SPAR, Cash 'N' Carry àtàwọn dúkìá míì tí jàǹdùkú jó níná

Oríṣun àwòrán, Reuters
Lati igba ti iṣẹlẹ isekupani awọn oluwọde End SARS ti waye ni Lekki, ni awọn janduku ti bẹrẹ si n da ilu ru ni ipinlẹ Eko.
Bi wọn ṣe n jo agọ ọlọpaa, ni wọn n ṣe wọn leṣe, ti wọn si tun n kọju ija si araalu, ọba alaye atawọn ileesẹ ijọba pẹlu ti aladani.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Muyiwa Adejobi sọ fun BBC Yoruba pe, awọn janduku ti jo ọọfisi ọlọpaa marundinlogun lapapọ.Ọ̀rọ̀ Nàíjíríà kúrò ní sinimá àwòrẹ́rìn-ìn, Buhari gbé ìgbésẹ̀ bíi òbí àti olórí - Obasanjo gbarata
Adejobi ni bi awọn oluwọde ṣe n sọ oko si awọn oṣiṣẹ wọn naa, ni wọn n yinbọn si wọn lati pa wọn tabi se wọn leṣe.

O fidi rẹ mulẹ pe, ko din ni ọlọpaa meji toun lee fidi rẹ mulẹ pe wọn dagbere faye lati ipasẹ awọn ikọlu to waye yika ilu Eko naa.
Yatọ si awọn ọọfisi ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn dana sun, tun wo diẹ lara awọn ileeṣẹ miran ti awọn janduku ọhun tun ti ṣọṣẹ l'Eko.
- Tolla gate to wa ni Lekki-Ikoyi
- Ile itaja ShopRite

Oríṣun àwòrán, TVC
- Ile itaja Cash n Carry, ni Lagos Island
- Ile itaja Spar ni Surulere
- Afin Ọba ilu Eko

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu
- Ileeṣẹ ọkọ oju omi ni Marina
- Ile iya Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu to wa ni Akerele
- Bakan naa ni wọn tun jo ọọfisi awọn VIO ni Ojodu.
- Ile ẹjọ magisireti ni Igbosere
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
- Ileeṣẹ iroyin The Nation.
- Ọpọ ọkọ akero Bus Rapid Transit, BRT ni Oyingbo
Olùwọ́de 12 kú ni Lekki, 38 lapapọ kú lọ́jọ́ Isẹ́gun, 56 ni àròpọ̀ àwọn tó bá ìwọ́de lọ - Amnesty International

Saaju la ti sọ fun yin pe gudugbẹ ọrọ ti jabọ lati ẹnu ẹgbẹ ajafẹtọ ẹni lagbaye, Amnesty International, ẹka ti orilẹede Naijiria lori iwa ipaniyan to waye ni Lekki lọjọ Isẹgun.
Atẹjade kan ti ẹgbẹ Amnesty naa fi soju opo rẹ lori Twitter, lo pe akọle rẹ "Ẹ se iwadii bawọn ologun se pa awọn oluwọde EndSARS".
Atẹjade naa ni salaye pe awọn oluwọde mejila ni awọn agbofinro yinbọn pa ni Lekki lọjọ Isẹgun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Osinbajo gbarata lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki, ó ní ìdájọ́ òdodo yóò wà
- Ooni Ogunwusi àti Wole Soyinka kòrò ojú sí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Tollgate
- Ọ̀rọ̀ Nàíjíríà kúrò ní sinimá àwòrẹ́rìn-ìn, Buhari gbé ìgbésẹ̀ bíi òbí àti olórí - Obasanjo gbarata
- Ilẹ̀ Amẹ́ríkà wà lẹ́yìn àwọn olùwọ́de, Buhari dẹ́kun ìpànìyàn - Joe Biden
- Mọ̀ nípa DJ Switch, akíkanjú obìrin sàfihàn fídíò ìpànìyàn Lekki bó ṣe ń wáyé
- Buhari, máṣe gbá ìpànìyàn Lekki sórí ààtàn, kò yẹ́ kí ológun yin ọ̀dọ́ níbọn - Bode George
- Ọ̀kan lára olùwọ́de tó fara gbọgbẹ́ ní Lekki jáde láyé - Sanwo-Olu
Bakan naa lo ni iwa isekupani ọhun tun waye ni Alausa, tawọn osisẹ sọja ati ọlọpaa to pa wọn si gbe oku wọn pamọ, gẹgẹ bi wọn ti maa n se.

Oríṣun àwòrán, @AmnestyNigeria
Bakan naa ni ẹgbẹ ajafẹtọ ẹni ọhun tun sisọ loju rẹ pe lati igba ti iwọde EndSARS ti bẹrẹ, eeyan mẹrindinlọgọta lo ti ba isẹlẹ naa lọ.
O ni lọjọ Isẹgun nikan, eeyan mejidinlogoji lapapọ lo jade laye lasiko iwọde ọhun yika orilẹede wa.
Ẹgbẹ Amnesty ni iwadii oun lori isẹlẹ naa lati ipasẹ awọn fidio to jade, ọrọ awọn ti isẹlẹ naa soju wọn ati abẹwo sile iwosan lo fidi isẹlẹ naa mulẹ.

Oríṣun àwòrán, @AmnestyNigeria
O ni awọn ẹri yii fihan pe awọn sọja yinbọn mọ awọn oluwọde lootọ ni Lekki laarin aago meje ku isẹju mẹẹdogun si mẹsan alẹ.
Ẹgbẹ ajafẹtọ ẹni naa wa koro oju si iwa ika naa pẹlu afikun pe iwa kikọju ibọn sawọn oluwọde jẹ ara titẹ ẹtọ wọnsi ipejọpọ, isọrọ sita ati igbe aye loju.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Bakan naa lo bu ẹnu atẹ lu iwadii kan to ni awọn osisẹ ijọba yọ ẹrọ ayaworan to n ka isẹlẹ silẹ, CCTV to wa ni bode Lekki nibi tawọn oluwọde naa wa lati ọsẹ meji sẹyin.












