Lekki Shooting: Wole Soyinka ní ìnú òun dùn pé àwọn ọ̀dọ́ ń jà fọ́jọ́ ìwajú wọn lójú ayé òun

Awọn osisẹ alaabo

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni pe ọgbà ẹ̀wọ̀n to wa ni Ikoyi n jona lọwọ.

Agbenusọ fun gomina ipinlẹ Eko, Gboyega Akosile to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC, sọ pe awọn kan lo kọlu ọgbà ẹ̀wọ̀n naa.

Awọn kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ lori ayelujara Twitter, pẹlu fidio kan pe eefin ina ati iro ìbọn ni wọn kọkọ n gbọ lati ọna ibi ti ọgbà ẹ̀wọ̀n naa wa ni adugbo Alagbon ni Lagos Island.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni nkan bi aago mejila ọsan ni iroyin naa jade.

Eyi waye lẹyin ọjọ diẹ ti awọn janduku kọlu ọgbà ẹ̀wọ̀n meji nipinlẹ Edo. Àwọn alasẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n sọ pe ẹlẹ́wọ̀n to to ẹgbẹrun meji, 1,900,lo sa kuro lasiko ikọlu naa.

Ooni Ogunwusi àti Wole Soyinka kòrò ojú sí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Tollgate

Ooni Ife ati Ojogbon Wole Soyinka

Oríṣun àwòrán, Premium times

Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi ati agba onkọwe nni, Wole Soyinka, ti koro oju si ikọlu ati bi awọn ologun ṣe yinbọn lu awọn oluwọde lagbegbe Lekki Toll Gate lọjọ Iṣẹgun.

Ninu atẹjade kan to fi sita, Ọọni Ogunwusi ni bi o ti pọn dandan pe ki ijọba daabo bo awọn dukia ilu, ko yẹ ko jẹ awọn ologun to yẹ ko maa daabo bo araalu, ni yoo wa yipada maa yinbọn pa wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O nijọba apapọ gbọdọ rii daju pe awọn ọlogun to ṣọṣẹ naa foju winna ofin ati pe, awọn ọbalaye lorilẹede Naijiria ti n gbe igbesẹ lati jẹ alarinna laarin ijọba apapọ atawọn onigbọwọ iwọde naa.

Ooni Adeyeye Enitan Ogunwusi II

Oríṣun àwòrán, Facebook/Ooni Adeyeye Enitan Babatunde Ogunwusi II

O ni asiko to bayi lati rii daju pe awọn alaṣẹ n tẹti si awọn ọdọ naa, ki wọn si ṣiṣẹ pọ pẹlu wọn lati rii daju pe orilẹede Naijiria goke de ibi ti mutumuwa n fẹ.

Ọọni Ile Ifẹ wa gbadura fun awọn ti o ti padanu ẹmi wọn kaakiri Naijiria nitori iwọde naa ati imularada awọn to fara gbọgbẹ gbogbo.

Kí ni Ọjọgbọn Wole Soyinka sọ ni tirẹ?

Wole soyinka

Oríṣun àwòrán, Thisisafrica.me

Ẹwẹ, agba Onkọwe, Wole Soyinka ti kesi awọn gomina ipinlẹ ti iwọde #ENDSARS ti mu ki wọn o kede isede, lati ṣọ fun ijọba apapọ pe ko ko awọn sọja kuro laarin igboro.

Ninu atẹjade kan to fi sita lọjọru, Soyinka sọ pe isede kọ ni ọna abayọ, bi ko ṣe pe ki wọn o sọ fún ijọba apapọ lati ko awọn sọja to ko sita nitori iwọde naa, kuro.

Yatọ si eyi, o ni o yẹ ki wọn o pe ipade apero pẹlu awọn araalu.

Àkọlé fídíò, Eegunjobi Omotanbaje Ajobiewe- Èébú ní wọ́n kọ́kọ́ ń bù mí nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣà pípé ní

O ni "o se koko lati jẹ ki ijọba o mọ pe ileesẹ ologun Naijiria ti rọpo ọlọpaa SARS, ti awọn eeyan n polongo tako".

Ati pe iduunu lo jẹ fun oun lati ri i pe awọn ọdọ n ja fun ọjọ iwájú wọn, nigba ti oun wa laaye.

O fi kun ọrọ rẹ pe, gbogbo iwadii oun fihan pe gomina ipinlẹ, Babajide Sanwo-olu, ko lọwọ si bi awọn sọja ṣe kọlu awọn ọdọ to ṣe iwọde ni Lekki.

Jàǹdùkú jó agboolé Sanwo-Olu, Iléeṣẹ́ Channels ń kógbá wọlé

Ile awọn Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, @ChinasaNworu

Nitẹsiwaju rogbodiyan to n lọ lọwọ nilu Eko, awọn janduku tun ti dana sun agboole gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu.

Iroyin naa ni se ni awọn ẹbi Sanwo-Olu to n gbe ninu ile naa, to wa ni opopona Omididun lagbegbe Lagos Island sa asala fun kmi wọn.

Isẹlẹ naa la gbọ pe o waye ni owurọ Ọjọru, ti wọn si jo ile naa kanlẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn eeyan kan tisẹlẹ naa soju wọn salaye pe, awọn janduku naa bẹrẹ ikọlu yii pẹlu sisọ okuta sinu ile naa, ko to di pe wọn da epo bẹntiro si lara, ti wsn si jo kanlẹ.

Awọn oluwọde niwaju ile awọn Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, @BadmosWaliu

Ẹnikan ti isẹlẹ naa soju rẹ ni deede aago mẹjọ ku isẹju mẹẹdogun lawọn janduku naa pejọ si ayika agboole awọn Sanwo-Olu, ti wọn si n fi oko fọ awọn ferese digi to wa nibẹ.

Ileesẹ Channels fẹ so isẹ rọ:

Wayi o, ileesẹ agbohunsafẹfẹ Channels, to gbaju gbaja yika agbaye ti n kede pe kawọn osisẹ rẹ fi agbegbe ileesẹ naa silẹ, ki wọn si maa lọ sile wọn.

Ami idamọ ileesẹ Channels

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Gẹgẹ bi ileesẹ Channels ti n kede loju mohunmaworan rẹ, o ni oun le ma sisẹ mọ nitori idunkooko pe awọn janduku fẹ wa ba ileesẹ naa jẹ.

Ọ̀dọ́ 30 ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ nílé ìwòsàn torí ọ̀gbẹ́ ìbọn ní Lekki - Sanwo-Olu ṣàlàyé

Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti sọ ko pe din ni eeyan ọgbọn to to wa nile iwosan bayii, lẹyin ti ọta ibọn ba wọn nibi iwọde End SARS to waye ni Lekki Toll Gate lọjọ Iṣẹgun.

Sanwo-Olu lo sọ ọrọ naa loju opo Twitter rẹ lẹyin to ṣabẹwo si awọn eeyan naa ni ilu Eko.

O ni "Eeyan mẹwaa lo ti n gba itọju lọwọ nile iwosan ijọba, ọdọ mọkanla si wa nile iwosan adani Reddington, awọn mẹrin wa ni Vedic, nigba ti awọn meji miran wa ni nibi ti wọn ti n doola ẹmi wọn lọwọ."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gomina ọhun fi kun pe, wọn ti tu awọn mẹta miran silẹ ki wọn maa lọ sile wọn lẹyin ti wọn gba itọju tan.

O ni gẹgẹ bii gomina, oun mọ iru ẹru to wa lori oun, nitori naa ni oun yoo ṣe ṣiṣẹ pẹlu ijọba apapọ lati ṣe iwadii bi ọrọ naa ṣe ṣẹ.

Wayii o, Gomina Sanwo-Olu ti kede pe oun yoo bawọ̀n eeyan ipinlẹ́ Eko sọ̀rọ̀ ni aarọ ọjọbọ oni.

Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu

Iwọde End SARS bẹyin yọ ni ilu Eko lọjọ Iṣẹgun lẹyin ti Sanwo-Olu kede ofin konile-o-gbele oni wakati mẹrinlelogun bẹrẹ lati aago mẹrin irọle.

Ko pẹ si asiko naa ti awọn ologun ṣina ibọn bolẹ ni Lekki, eyii to jẹ ojuko kan gboogi ti ifẹhonuhan End SARS ọhun ti milẹ julọ ni ilu Eko, ti ibọn si ba ọpọ eeyan.

Ṣaaju akoko naa, awọn janduku kan ti rapala wọn saarin awọn oluwọde, ti wọn si kọlu ọọfisi ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Orile, ti wọn si dana sun.