EndSARS Protest Update: Iléèṣẹ́ ọlapàá sọ pé Ọlọ́pàá mẹ́fà ni jàndùkú pa, wọ́n tún kọlù àgọ́ ọlọ́pàá márùn-ún lásìkò ìwọ́de

Awọn janduku pa ọlọpaa mẹfa, wọn ṣe akọlu si agọ ọlọpaa marun un lasiko ifẹhonuhan #EndSARS nipinlẹ Ọyọ
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti ṣe afihan awọn afurasi ọdaran to dana sun agọ ọlọpaa nilu Isẹyin.

Lara awọn afurasi naa ni;
Taoreed Hamsat ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn,
Tajudeen Ibrahim ẹni ogoji ọdun,
Moshood Fatai ẹni ọdun mọkandinlogoji,
Musibau Abubakar ẹni ọdun mọkanlelogun.
Bakan naa ni Sikiru Aliu ẹni ọdun mẹẹdọgbọn,
Fasasi Fatai, ẹni ọdun mẹrinlelogun,
Isiaka Olaniyi, ẹni ọdun mejilelọgbọn,
Raheem Toheeb, ẹni ọdun mejidinlọgbọn
Ati Adeleke Akeem, ẹni ọdun mejilelogoji.
Lasiko to n ṣe afihan awọn ọdaran naa l'Ọjọru ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to n bẹ ni agbegbe Ẹlẹyẹle ilu Ibadan, kọmisana ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Joe Nwachukwu Enwonwu ṣe alaye wi pe ọlọpaa mẹfa ni wọn da ẹmi wọn legbodo.

Bẹẹ sini awọn ọdaran naa tun dana sun agọ ọlọpaa marun un ọtọọtọ, ti wọn si tun ji awọn nnkan ijagun lọ.
Enwonwu parọwa si awọn eeyan awujọ lati ọrọ to ileeṣẹ ọlọpaa leti ti wọn kẹẹfin awọn ọdaran to ji awọn ohun elo ijagun ọlọpaa lọ.
Lara ohun elo ti wọn ri gba pada lọwọ awọn afurasi naa ni ẹrọ amunawa kekere kan, aago ara ogiri mẹsan an, alupupu Bajaj kan, alupupu Hero marundinlaadoje ati alupupu TVS kan pẹlu nọmba iforukọsilẹ DGB 215QK.
Ohun tí gómìnà Seyi Makinde fẹ́ ṣe lórí ìwọ́dé EndSARS lẹ́yìn ìpàdé rẹ̀ pẹ̀ láwọn tọ́rọ̀ọ kàn
Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn èèkàn ní Ìpínlẹ̀ náà lórí ọ̀nà àbáyọ sí ìfẹ̀hónúhàn #EndSARS àti nǹkan tó jẹyọ lórí ẹ̀.
Makinde ní ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ ni ìjọba rẹ̀ yóò ṣe àgbékalẹ̀ ìgbìmọ̀ ìwádìí lórí ìfìyàjẹni ọlọ́pàá ní Ìpínlẹ̀ náà.
"Mo tun fẹ fi asiko yii fi da awọn eeyan Oyo loju daadaa pe iṣejọba wa yoo tẹsiwaju lati maa fi ti ẹyin araalu ṣaaju".
Ọrọ yii jẹ jade nigba ti gomina naa pe ipade awọn lọba lọba, igbimọ awọn alaga ijọba ibilẹ, ati awọn igbimọ idagbasoke ilu to fi mọ awọn alufaa.

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Ipade rẹ pẹ́lú awọn eekan yii waye lati jiroro lorii ọna itẹsiwaju fun ipinlẹ naa lẹyin ọpọpọlọ ọsẹ titi iwọde ifẹhonuhan EndSARS ti fa.
Bakan naa, Makinde fi kun un pe awọn yoo mojuto iṣoro ọrọ aje to ti pa awọn araalu lara.
"A ti da ẹẹdẹgbta miliọnu naira sọtọ fun iranwọ idokoowo kekeke a o si gba ọdọ ẹgbẹrun marun-un si iṣẹ ijọba ni oṣu diẹ si isisiyii".
Bakan naa o ni awọn yoo pin iṣi kaarun nkan iranwọ Covid-19 lopin ọsẹ yii.
O ni gẹgẹ bo ṣe wa ninu ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 1999, awọn yoo maa da abo bo ẹtọ gbogbo ara ipinlẹ Oyo.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ diẹ sẹyin ni wahala bẹ silẹ lagbegbe Iwo Road niluu Ibadan latari iwọde EndSARS ti gomina Seyi Makinde si lọ ṣabẹwo sibẹ.
Ìró ìbọn dún lákọ ní Iwo road n'Ibadan, Seyi Makinde yọjú síbẹ̀
Gomina Ṣeyi Makinde ti yọju si Iwo Road lorii rogbodiyan to n ṣẹlẹ nibẹ.
Lati owurọ ni ariwo ibọn ti n dun ni kikan kikan ni agbegbe Iwo road lọ si Abayọmi-Idi-Apẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "7000 Jàǹdùkú ló fọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n Okitipupa, jó mọ́tò, tí wọn si se òṣìṣẹ́ léṣe"
- Buhari kọ́ ni ìṣòro wa, bó ṣe wà láti láéláé rèé - Fr Mbaka
- Àwọn ọ̀dọ́ fi ọ̀nà àrífín pe Tinubu lórí aago àmọ́ ó ní òun kò mọwọ́-mẹsẹ̀ nípa ìpànìyàn Lekki
- Wo díẹ̀ lára dúkìá tí jàǹdùkú sun níná l‘Eko torí ìwọ́de EndSARS
- Á ràgà bo CCTV Lekki bí i ẹ̀rí tó dájú fún ìwádìí ìpànìyàn - Sanwo-Olu
- SERAP gbé ìjọba àpapọ̀ lọ ilé ẹjọ́ àgbáyé ICC lọrí ẹ̀sùn ìpànìyàn
- "Jàǹdùkú gún ẹ̀gbọ́n mi lọ́rùn, jó ilé àti mọ́tò wa méjì, kòròfò la wà"
- Olùwọ́de 12 kú ni Lekki, 38 lapapọ kú lọ́jọ́ Isẹ́gun, 56 ni àròpọ̀ àwọn tó bá ìwọ́de lọ - Amnesty International
- Osinbajo gbarata lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki, ó ní ìdájọ́ òdodo yóò wà
Iroyin ti a gbọ ni pe, awọn janduku kan fẹ yawọ agọ ọlọpaa to wa ni Testing Ground ni opopona Iwo road, lẹyin ti wọn dana sun ọkọ Operation Burst kan ni agbegbe naa.
Bi awọn ọlọpaa ṣe n yin ibọn, ni wọn n fin tajutaju naa pẹlu.

O ṣoju mi koro ni awọn ọlọpaa meji ni awọn janduku naa pa, ti wọn si dana sun wọn.
Ọgọrọ awọn olugbe adugbo naa lo n sa asala fun ẹmi wọn bayii.
Ìwọ́de #EndSARS rán èèyàn méjì sọ́run n'Ibadan, Seyi Makinde da ikọ̀ Operation Burst sígboro

Saaju la ti sọ fun yin pe ko din ni eeyan meji ti wọn ti pa lagbegbe Ọjọọ nilu Ibadan lasiko ti awọn eeyan kan ti wọn funra si pe wọn jẹ janduku kọlu agọ ọlọpaa kan nibẹ lasiko iwọde #EndSARS.
Gẹgẹ bi ohun ti awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan sọ, ohun ti awọn eeyan n sọ ni pe awọn ọẹọpaa lo ṣeeṣe ki wọn ṣina ibọn bolẹ fawọn eeyan naa.
- N kò ní buwọ́ lu ìṣúná tí kò pèsè owó fún ẹ̀bí àwọn tó kú nínú ìwọ́de EndSARS - Gbajabiamila
- Tẹ́ bá fẹ́ lo ìwọ́de láti gba àkóso ìjọba, wọn yóò dá yín lẹ́kun - Tinubu
- "Ẹ ràn wá lọ́wọ́ láti rí àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó sálọ ní Oko àti Benin padà"
- Ọ̀pọ̀ aráàlú ló ti pàdánù ọwọ́ àti ẹsẹ wọn sọ́wọ́ jàǹdùkú - Sanwo-Olu
Iroyin sọ pe iwọde naa n lọ wọọrọwọ ki awọn janduku kan to jaagba ti wọn si bẹrẹ si nii ju okuta ati igo si agọ ọlọpaa naa. Eyi lawọn eeyan kan ni o mu ki awọn ọlọpaa o ṣina ibọn bolẹ sawọn oluwọde naa ti meji si ku.

Oríṣun àwòrán, Seyi makinde/twitter
Nnkan bi wakati kan ni wọn ni iro ibọn fi n dun lakọlakọ ti kaluku si sa asala fun ẹmi wọn.
Bakan naa ni gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde tun ti paṣẹ ki gbogbo ileewe wa ni titi pa nitori wahala to n jẹyọ nipasẹ iwọde #EndSARS ni ipinlẹ naa.
Bakan naa ni Makinde tun ko awọn ikọ agbofinro Operation Burst si igboro lawọn agbegbe ti ina wahala ti n jo julọ lati mu ki alaafia jọba nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Seyi makinde/twitter
Bakan naa lo tun ṣalaye pe ileeẹ eto idajọ ni ipinlẹ Ọyọ ti fa gbogbo iwe ifisun ti wọn fi kan awọn oluwọde #EndSARS ni ipinlẹ naa ya, bẹẹni wọn si ti tu gbogbo awọn ti wọn fi si atimọle silẹ.
Bakan naa lo rọ awọn araalu lati ma foya ki wọn si maa gbe igbe alaafia lọ. O wa fi nọmba ipe pajawiri 615 sita pe ki ẹnikẹni tawọn eeyan tabi ẹgbẹ ba n da iṣẹ aje rẹ laamu pe fun iranwọ ni kiakia.













