CACOVID Palliatives: Ọwọ́ Ọlọ́pàá tẹ àwọn tó lọ kó ǹkan ìrọ̀rùn Covid-19

Pipo wey dey pack palliative

Oríṣun àwòrán, Yabgi Mohammed

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Awọn agbofinro ti n fi ṣikun ọba mu awọn to kọlu awọn ile itaja ati ileeṣẹ aladani lati ji ọja ati dukia awọn eeyan ko lẹyin iwọde EndSARS.

Ko din ni irinwo o le mẹsan eeyan ti wọn ti mu ni ipinlẹ Kwara, Plateau, Benue ati Abuja.

Awọn ọlọpaa Plateau fi panpẹ ofin mu afurasi mẹrinlelaadọsan tuntun, eyii to ṣalekun iye eeyan ti wọn ti mu bayii si ọọdunrun o le meje lapapọ.

Ni Calabar, wọn mu afura ọgọrin, gomina Ben Ayade si ti kede ẹbun owo ọgọrun miliọnu naira fun ẹnikẹni to ba le ṣamọna bi ijọba ṣe le ri awọn afurasi to ku.

Iroyin ni ọpọ ninu awọn ẹru ti awọn eeyan ji ko ni wọn n fi silẹ ni oriṣiriṣi kọrọ adugbo lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa bẹrẹ ayẹwo ojule si ojule.

Àkọlé fídíò, Láàrín ìṣẹ́jú díẹ̀, ẹ ka ìwé Akinwumi Ishola, "Nítorí Owó" lórí Akomolede Yoruba

Kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Cross River, Abdulkadir Jimoh sọ pe ọpọ ninu ẹru ti awọn eeyan ji ko ni wọn ti ri pada.

Lara awọn ẹru to ni wọn ti ri pada naa ni kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta atawọn ohun elo amohun bu gbamu to jẹ ti ileeṣẹ Calabar International Conference Centre, CIIC.

Kọmiṣọna ọhun rọ awọn agba adugbo atawọn olori ẹlẹsin lati tu aṣiri gbogbo awọn ti wọn ba fura si pe o lẹbọ lẹru.

O ni "a ti mu afurasi ọgọrin a si ti bẹrẹ iwadi lori wọn, a fun gbogbo awọn to ji ẹru ẹlẹru ko labẹ asia iwọde EndSARS ni wakati mẹrinlelogun lati da awọn ẹru naa pada tabi ki wọn foju wina ofin."

Ni Kwara, ileeṣẹ ọlọpaa ti fi oju afurasi 144 lede ni Ilorin lori awọn ẹru ti wọn ji ko.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo ti bẹrẹ si ni fimu finlẹ lori awọn afurasi kan naa kaakiri ipinlẹ ọhun, ọwọ si ti tẹ eeyan mẹwaa o kere tan.

Àkọlé fídíò, 'Egbò tó ti fẹ́ẹ̀ jiná ni ìtàn bí wọ́n ṣe pa Soun Ogbomoso, Ọba Olayode tẹ ń bèrè'

Eko, Kwara, Osun àtàwọn ìpínlẹ̀ míì tí àwọn èèyàn ti jí oúnjẹ ìrànwọ́ Covid-19 kó

Lẹyin ti ọpọ awọn ipinlẹ ti kede ofin konile-o-gbele nitori iwọde EndSARS, awọn janduku bẹrẹ si nii kọlu awọn ile ti ijọba ko ounjẹ iranwọ Covid-19 si, ti wọn si bẹrẹ si n ji i ko.

Oṣu Kẹjọ ọdun 2020 ni ajọ Coalition Against Covid-19, CACOVID, ni o oun bẹrẹ si n pin awọn ounjẹ iranwọ naa, ṣugbọn ti ọpọ awọn ọmọ Naijiria sọ pe awọn ko ri ohunkohun.

Awọn ipinlẹ wọnyii ni awọn janduku ti lọ ji ounje iranwọ Covid-19 ko.

Taraba

Ni ọjọ Satide, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹwaa ọdun 2020 ni awọn kan bori awọn ẹṣọ alabo, ti wọn si kọlu ile ti ijọba ipinlẹ naa ko ounjẹ Covid-19 si.

Iṣẹlẹ naa mu ki igbakeji gomina ipinlẹ ọhun kede igbele oni wakati mẹtalelọgbọn ni ilu Jalingo.

Osun

Ilu Ede ni awọn eeyan ti rọlu ile ti ijọba ko ounjẹ iranwọ Covid-19 si ni Cocoa House ti wọn si bẹrẹ si n ji ko.

Gẹgẹ bi nnkan ti ijọba ipinlẹ naa sọ, ounjẹ naa wa fun pinpin fun awọn eeyan ilu, ṣugbọn wọn n duro de aṣẹ lati ọdọ ọọfisi CACOVID ni Abuja ki wọn to bẹrẹ pinpin rẹ.

Lẹyin naa ni ijọba ipinlẹ ọhun kede konile-o-gbele tuntun fun wakati mẹrinlelogun.

Àkọlé fídíò, 'Egbò tó ti fẹ́ẹ̀ jiná ni ìtàn bí wọ́n ṣe pa Soun Ogbomoso, Ọba Olayode tẹ ń bèrè'

Kwara

Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹwaa ọdun 2020 ni awọn eeyan ipinlẹ Kwara ya bo ibi ti ijọba ko ounjẹ iranwọ Covid-19 si niluu Ilorin.

Ijọba ipinlẹ ọhun sọ pe ijọba ibilẹ kan lo ni ounjẹ naa nitori wọn ti pinpin gbogbo eyii to ku fun awọn ara ilu.

Plateau

Agbegbe Buruku ni awọn eeyan ipinlẹ Plateau ti ri ile ti ijọba ko awọn ounjẹ naa si, wọn si ji gbogbo rẹ ko daadaa.

Lẹyin iṣẹlẹ naa ni ijọba sọ pe oun kò kó ounjẹ naa pamọ ṣugbọn oun n duro ki iwọde EndSARS tan nilẹ ki oun to pin ni.

Kogi

Lẹyin ti ijọba Kogi sọ pe oun ti pin ounjẹ iranwọ Covid-19 ni awọn ara ilu ri ile to ko ounjẹ naa pamọ si.

Ekiti

Ni ti ipinlẹ Ekiti, ijọba ti sọ pe oogun pakopako ati ajilẹ ni awọn eeyan ji ko dipo ounjẹ iranwọ Covid-19.

Wọn ni ileeṣẹ ijọba to n ri si iṣẹlẹ pajawiri lo ni awọn ajilẹ ati pakopako ti wọn ji ko, kii ṣe ounjẹ.

Kaduna

Ọjọ Abamẹta ni awọn eeyan yabo Gwari, ti wọn si ko gbogbo ounjẹ Covid-19 to wa nibẹ lọ.

Ijọba ipinlẹ naa sọ lẹyin iṣẹlẹ naa pe, lara ibi ti wọn kọlu jẹ ti ajọ NAFDAC, nibi ti wọn n ko awọn oogun to ti bajẹ pamọ si.

Adamawa

Ijọba ipinlẹ Adamawa kede igbele oni wakati mẹrinlelogun lẹyin ti awọn eeyan ya bo ile to ko ounje naa pamọ si lọjọ Aiku.

Gomina ipinlẹ naa, Ahmadu Umaru Fintiri sọ pe wọn ti pin awọn ounjẹ ọhun ṣugbọn awọn to ku ni wọn n gbe igbesẹ lati pin lọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020, ki wahala to bẹ silẹ.

Eko

Agbegbe Maza-maza ni awọn eeyan kọkọ kọlu lati ji ounjẹ iranwọ Covid-19 to wa nibẹ.

Iṣẹlẹ na waye leyin ikọlu ti ileeṣẹ ọmọ ogun ṣe si awọn oluwọde EndSARS ni Lekki Toll Gate.

Awọn ipinlẹ to ti pin ounjẹ tiwọn tan:

Ipinlẹ Zamfara ati Bauchi wa lara awọn ipinlẹ to sọ pe wọn ti pin ounjẹ Covid-19 awọn tan nitori wọn ni ko si ounjẹ Kankan mọ nile ti wọn ko pamọ si.

Ni ti Bauchi, gomina Bala Mohammed sọ pe awọn janduku naa gbiyanju lati kọlu ile ti awọn ko ounjẹ naa si ṣugbọn ofo ni wọn ba, nitori wọn ti pin gbogbo rẹ tan.

Ilẹ̀ Yorùbá pátá ló ni oúnjẹ ìdẹ̀rùn Covid-19 tẹ kó l'Eko - Ìjọba Eko figbeta

Ijọba ipinlẹ Eko ti sọrọ lori awọn erojẹ ounjẹ fun eto idẹrun Coronavirus, tawọn araalu kan ji ko nibudo ẹru ti wsn ko pamọ si, lọjọ bọ.

Atẹjade kan tijọba fisita ni awọn eroja ounjẹ naa, to pọ babi, kii se ti ipinlẹ Eko nikan, gbogbo ẹkun iwọ oorun Guusu Naijiria lo ni.

Atẹjade kan to wa loju opo Twitter ijọba Eko, ti adele Kọmisana feto ọgbin, Abisola Olusanya fọwọsi, lo sisọ loju ọrọ yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ijọba Eko ni ọjọ kejilelogun osu Kẹsan ọdun 2020 ni Gomina Babajide Sanwo-Olu tẹwọgba awọn eroja ounjẹ naa latọwọ ajọ to n pese eto idẹrun arun Coronavirus, CACOVID.

Ijọba ipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, @followlasg

O ni ijọba n tun awọn eroja ounjẹ naa di lọwọ ni to si n pin kaakiri, ko to di pe iwọde EndSARS wọle de, to si se idiwọ fun wọn lati tẹsiwaju lori rẹ.

"Koda, ibudo ikẹru si ọhun kii se ti ijsba, wọn kan gbe silẹ fun wa lati lo ni."

Ijọba ipnilẹ Eko wa kabamọ lori bi awọn araalu se ya bo ibudo ọhun, to si mọ riri atilẹyin ajọ CACOVID, to pin fun.

"Àwọn ọ̀tá Nàíjíríà tó fẹ́ dojú ìjọba bolẹ̀ ló wà lẹ́yìn ìwọ́de EndSARS"

Awọn gomina ẹkun ariwa

Oríṣun àwòrán, @GovKaduna

Awọn gomina lẹkun ariwa Naijiria ti sọrọ lori rogbodiyan to gbode kan lati ipasẹ iwọde EndSARS.

Awọn gomina naa lo gbe atẹjade kan sita lẹyin ipade pajawiri ti wọn se lọjọbọ nilu Kaduna, eyi ti gomina Simon Lalong ti Plateau fọwọ si.

Wọn woye pe, ete ati doju ijọba Buhari bolẹ ni iwa ipa, janduku ati ẹlẹyamẹya to gbode nitori ipe fun wiwọgile awọn ọlọpaa SARS.

Awọn gomina naa wa n kọminu pe, ki lo de ti iwọde naa si tẹwaju lẹyin ti ijọba apapọ ti wọgile awọn ọlọpaa SARS naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bi atẹjade naa ti wi, awọn gomina naa forikori, ti wọn si jiroro pupọ nipa eto aabo orilẹede yii, paapaa iwọde EndSARS to mu ọpọ ẹmi ati dukia lọ.

Awọn gomina ẹkun ariwa

Oríṣun àwòrán, @GovKaduna

"A sakiyesi pe ejo lọwọ ninu iwọde janduku, ẹlẹyamẹya ati ẹlẹsinjẹsin pẹlu ti oselu to gbode, tawọn alainikanse naa si setan lati wo orilẹede yii palẹ, ti wọn si n fẹ ki ayipada isejọba waye."

Ẹgbẹ awọn gomina lẹkun ariwa Naijiria naa wa n ke sawọn ọmọ Naijiria nile loko, lati tako awọn ọta orilẹede yii nipa sise atilẹyin fun aarẹ Buhari, ijọba apapọ ati eto ijọba alagbada.

Awọn gomina ẹkun ariwa

Oríṣun àwòrán, @GovKaduna

Bakan naa ni wọn tun ni awọn se akiyesi awọn alẹnulọrọ lati ilẹ okeere, ti wọn n lọwọ ninu isẹlẹ yii, ti wọn si kesi gbogbo ọmọ Naijiria lati foju sọri, paapaa awọn ọdọ.

"A wa n rọ awọn araalu lati dẹkun iwa ọyaju, ati atako sawọn ẹya miran to n gbe ni ipinlẹ yin nitori ara isẹ ọwọ awọn ọta to n fẹ ayipada ijọba niyi lai seto idibo."

Awọn gomina naa wa n beere fun agbekalẹ ajọ eleto idajọ ti yoo sewadi iwa idaluru ati ipaniyan to waye lasiko iwọde EndSARS.

Á ràgà bo CCTV Lekki bí i ẹ̀rí tó dájú fún ìwádìí ìpànìyàn - Sanwo-Olu

Babajide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu tun ti sọrọ lori isẹlẹ ipaniyan to waye ladugbo Lekki lọjọ isẹgun.

Sanwo-Olu sọrọ fun igbakeji lori ipaniyan to waye ni Lekki ati bawọn janduku se soro nilu Eko lọjọru lasiko to n kopa lori eto ori mohunmaworan kan nipinlẹ Eko.

"Gbogbo ifẹhonuhan yii ti n waye saaju ki wọn to bura fun mi bii gomina, ki ijọba ipinlẹ ni ọlọpaa tiẹ si lo le yanju ọrọ yii nitori wọn yoo jẹ ọlọpaa agbegbe."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni gomina ipinlẹ Eko ni wọn yoo daabo bo ẹrọ ayaworan CCTV to wa ni Lekki, tawọn yoo si pe awọn akọsẹmọsẹ lati ri daju pe wọn ko ba ẹrọ naa jẹ.

"A le se agbekalẹ igbimọ igbimọ oluwadii aladani lopin ọsẹ, to si seese ki wọn bẹrẹ isẹ lọjọ Aje.

Babajide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu

Ọkọ nla marun la padanu lanaa, ti wọn si tun kọlu ọkọ ipe pajawiri wa, wọn jo ileesẹ LASEMA, tawọn osisẹ ibẹ si sa asala fun ẹmi wọn, eyi ti ko jẹ ki wọn le lọ pa ina to jo awọn idudo lanaa."

Goomina ipinlẹ Eko naa salaye pe oun wa n bi ara oun leere pe "Bawo la se rin, ta fi ba ara wa niru ipo yii? Ta fi n jo ọkọ akero ijaba ati ile ẹjọ to ti wa lati aye baye?"

O ni ẹnu wa n ya oun pe ki lo de ta fi maa ba awọn dukia ijọba jẹ.

Awọn ile to jo

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu

"A gbọdọ fopin si iwa ibinu yowu to le wa nitori ilu Eko nikan ni ko ti si iwa ẹlẹya mẹya abi ẹlẹsinjẹsin, nitori ọkan soso ni wa."

O wa gba gbogbo ara ilu nimọran lati fimọ sọkan ju ti tẹlẹ lọ, ka si wo egbo ọkan wa san nitori ko ni dara, ka jẹ ki ohun rere tawọn baba nla wa fisilẹ fun wa bajẹ.

Amọ o fikun pe olori osisẹ ni ọọfisi aarẹ wa pe oun pada lẹyin ipade igbimọ alasẹ ijọba naa.

Ara agọ ọlọpaa to jona

Oríṣun àwòrán, @Odolz

Ẹ̀ẹ̀mejì ni mo pe ààrẹ Buhari lánàá lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki, àmọ́ ń kò ri bá sọ̀rọ̀ - Sanwo-Olu

Sanwo-Olu tun salaye pe oun ko tii ri aaye ba aarẹ Muhammadu Buhari sọrọ lori isẹlẹ naa, titi di akoko yii.

O ni oun pe aarẹ Buhari lori isẹlẹ ipaniyan naa laarọ ana, amọ wọn n bun mi gbọ pe ko tii de si ọọfisi.

O fikun pe oun tun pada pe lori aago, amọ ti wọn sọ fun oun pe o wa ni ipade igbimọ alasẹ ijọba ilẹ yii to n waye lana.

Bakan naa ni Sanwo-Olu ni olori ileesẹ ọmọ ologun ilẹ wa ti pe oun lori isẹlẹ to waye lọjọ Isẹgun ọhun.

Gomina ipinlẹ Eko, ninu ifọrọwanilẹnuwo ọhun tun sisọ loju rẹ pe ijọba oun ti gbe igba miliọnu naira kalẹ bii owo gba ma binu fawọn eeyan to fori sọta iwọde EndSARS naa.

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

O wa rawọ ẹbẹ sawọn ọdọ to n sewọde lati fi orukọ eeyan meji silẹ, ti yoo soju wọn ninu igbimọ oluwadii ti ijọba gbe kalẹ lori ẹhonu wọn.

Gomina ipinlẹ Eko ni asiko to to yẹ ki wọn faaye gba awọn ipnilẹ lati ni ọlọpa tiwọn, koda, o ni ọrọ naa ti pẹ ju.

Osinbajo gbarata lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki, ó ní ìdájọ́ òdodo yóò wà

Igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo

Oríṣun àwòrán, @ProfOsinbajo

Igbakeji aarẹ nilẹ wa, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo ti sọrọ lori isẹlẹ to waye ni ẹnu iloro bode Lekki lọjọ Isẹgun.

Osinbajo, ẹni to fi atẹjade sita loju opo Twitter rẹ lọjọru lẹyin ọjọ kan ti isẹlẹ naa waye ni orilẹede Naijiria yoo gba idajọ ododo fawọn oluwọde EndSARS to kagbako iku ojijij naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igbakeji aarẹ wa fi ika hanu pe, ọpọ awọn ohun ta padanu lati ipasẹ iwọde naa ni a ko le ri wọn pada mọ titi laelae.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Osinbajo, ẹni to fidi rẹ mulẹ pe oun ti ba ọpọ awọn oluwọde to fara gbọgbẹ, ti wọn wa nile iwosan sọrọ, tun wa kẹdun pẹlu awọn araalu ati ọlọpaa yika ilẹ wa, ti ikọlu naa kan.