EndSARS Protest Updates: Feminist Coalition sọ fáwọn ọ̀dọ́ láti fòpin sí ìwọ́de

Ẹgbẹ kan to n lewaju ninu eto akoso iwọde EndSARS ni Nigeria, The Feminist Coalition, ti kede pe oun ti yọwọ yọsẹ kuro ninu iwọde naa.
Bakan naa lo kede pe oun ti se alaye lori owo ti wọn ri ko jọ fun iwọde naa, ti apapọ rẹ jẹ miliọnu mẹtadinlaadọjọ naira.
Ọjọbọ ni ẹgbẹ Feminist Coalition kede pe oun ko ni ni ohunkohun se pẹlu iwọde kankan mọ. O salaye pe asẹ ti aarẹ Muhammadu Buhari pa ninu ọrọ to ba awọn ọmọ Naijiria sọ, pe ki wọn fi opin si iwọde wọn, lo mu ki oun se ipinnu ọhun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ìròyìn, àwòrán àti fídíò èké nípa ìwọ́de EndSARS
- Super Eagles, ẹ máṣe gbá bọ́ọ̀lù fún Nàìjíríà mọ́ nítorí ìhà tí ìjọba kọ sí ìwọ́de EndSARS - John Ogu
- Ará Eko, ẹ pariwo ó tó gẹ́ẹ́ lórí làásìgbò tó gbòde torí ìwọ́de EndSARS - Sanwo-Olu
- Ọ̀tá Yorùbá ló lo ìwọ́de láti dojú ogun kọ wá - OPC
- "Àwọn ọ̀tá Nàíjíríà tó fẹ́ dojú ìjọba bolẹ̀ ló wà lẹ́yìn ìwọ́de EndSARS"
- Ó parí ni ohùn tó gbẹnu ọ̀pọ̀ ọmọ Nàíjíríà lẹ́yìn ọ̀rọ̀ Buhari
- Ìwọ́de EndSARS kìí ṣe ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yàmẹ̀yà, ara ti kan àwọn èèyàn ni - Afenifere
- Buhari kọ́ ni ìṣòro wa, bó ṣe wà láti láéláé rèé - Fr Mbaka
O wa rọ awọn alatilẹyin ẹgbẹ naa nilẹ yii ati loke okun, lati dẹkun fifi owo sọwọ sinu apo asunwọn ẹgbẹ naa ti wọn fi n ko owo jọ, eyi towo inu rẹ bayii jẹ miliọnu lọna mẹtadinlaadọjọ naira.

Oríṣun àwòrán, @feminist_co
Bakan naa ni ẹgbẹ Feminist Coalition tun rawọ ẹbẹ sawọn ọdọ pe ki wọn dẹkun iwọde naa, niwọn igba ti aarẹ ti ba araalu sọrọ, ti ko si mẹnuba ohunkohun to nii se pẹlu ibọn yinyin to waye ni Lekki.
O ni dipo bẹẹ, se ni aarẹ Buhari se atilẹyin fun ikede konile o gbele to wa lawọn ipinlẹ kan lorilẹede yii, to si rọ awọn eeyan lati dẹkun iwọde fun aabo ẹmi wọn.
Ko tan sibẹ, ẹgbẹ Feminisit Coalition tun pẹlu alaafia ni awọn oluwọde EndSARS fi n se iwọde wọn yika Naijiria, ti wọn si safihan iwa ọlọgbọn.

Oríṣun àwòrán, @feminist_co
"Amọ nibi ti ọrọ de bayii, a gbọdọ daabo bo ẹmi ara wa ati tawọn ọmọ ẹgbẹ wa pẹlu."
Nipa ti owo ti wọn ri kojọ, tii se miliọnu lọna mẹtadinlaadọjọ naira fun iwọde naa, o ni awọn ti na miliọnu lsna ọgọta ninu rẹ laarin ssẹ meji, gẹgẹ bi alaye to wa lori ayelujara wọn.
Alaye bi wọn si se na owo naa ree:
- Itọju awọn oluwọde to farapa - N20,114,087.25
- Owo amofin - N15,741,459.59
- Iranwọ owo fawọn ẹbi oloogbe - N40,228,174.51
- Iranti awsn oloogbe - N5,247,153.197
- Awọn to ni arun ọpọlọ nibi iwọde naa - N6,121,678.73
Super Eagles, ẹ máṣe gbá bọ́ọ̀lù fún Nàìjíríà mọ́ nítorí ìhà tí ìjọba kọ sí ìwọ́de EndSARS - John Ogu

Oríṣun àwòrán, @VillaUpdates1
Atamatase ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles, John Ogu ti ke si awọn akẹgbẹ rẹ, lati maṣe kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ Naijiria to n bọ lọjọ iwaju.
O ni oun n pe ipe naa nitori iha ti ijọba apapọ kọ si iwọde End SARS.
Agbabọọlu naa, to ti gba bọọlu fun Naijiria ni igba mẹrindinlọgbọn sọ pe, ṣiṣe bẹẹ yoo jẹ ki ijọba apapọ mọ bi ọrọ ṣe gbona si lara wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ará Eko, ẹ pariwo ó tó gẹ́ẹ́ lórí làásìgbò tó gbòde torí ìwọ́de EndSARS - Sanwo-Olu
- Ọ̀tá Yorùbá ló lo ìwọ́de láti dojú ogun kọ wá - OPC
- "Àwọn ọ̀tá Nàíjíríà tó fẹ́ dojú ìjọba bolẹ̀ ló wà lẹ́yìn ìwọ́de EndSARS"
- Ó parí ni ohùn tó gbẹnu ọ̀pọ̀ ọmọ Nàíjíríà lẹ́yìn ọ̀rọ̀ Buhari
- Ìwọ́de EndSARS kìí ṣe ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yàmẹ̀yà, ara ti kan àwọn èèyàn ni - Afenifere
- Buhari kọ́ ni ìṣòro wa, bó ṣe wà láti láéláé rèé - Fr Mbaka
- Àwọn ọ̀dọ́ fi ọ̀nà àrífín pe Tinubu lórí aago àmọ́ ó ní òun kò mọwọ́-mẹsẹ̀ nípa ìpànìyàn Lekki
- Á ràgà bo CCTV Lekki bí i ẹ̀rí tó dájú fún ìwádìí ìpànìyàn - Sanwo-Olu
- SERAP gbé ìjọba àpapọ̀ lọ ilé ẹjọ́ àgbáyé ICC lọrí ẹ̀sùn ìpànìyàn
O ni kawọn oloselu kesi awọ̀n ọmọ wọn lati maa lọ soju Naijiria ninu ifẹsẹwọnsẹ Super Eagles to n bọ
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Kii ṣe Ogu nikan ni ọmọ Naijiria to jẹ agbabọọlu to bu ẹnu atẹ lu ọwọ ti ijọba fi mu iwọde naa, paapaa lẹyin ifẹmiṣofo to waye ni Lekki.
Ṣaaju ni Odion Ighalo, to n gba bọọlu fun Manchester United nilẹ Gẹẹsi, ti kọkọ sọ pe "itiju nla gbaa" ni ijọba Naijiria jẹ lẹyin ikọlu Lekki.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ajọ ajafẹtọ ọmọniyan lagbaye, Amnesty International sọ pe ko din ni eeyan mejila to ku nibi iṣẹlẹ naa.
Ṣugbọn ileeṣẹ ologun ti sẹ pe ohun ko mọ ohun nipa iṣẹlẹ to waye ni Lekki, bẹẹ na ni ijọba ipinlẹ Eko naa ni oun ko mọ ohunkohun nipa rẹ, ti Aarẹ Muhammadu Buhari naa ko si sọrọ.
Iwọde End SARS bẹrẹ lati pe fun opin si ẹka ileeṣẹ ọlọpa to n ri si iwa idigunjale, SARS, lori iwa aṣemaṣe ti wọn n wu ati bi wọn ṣe n tẹ oju ẹtọ awọn eeyan mọlẹ.













