EndSARS Protest Update: Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ní àwọn ń wádìí èèyàn 229 lọ́wọ́ lórí làásìgbò tó wáyé l'Eko

Ijọba ipinlẹ Eko ni eeyan igba o le mọkandinlọgbọn lọwọ tẹ fun lilo anfani iwọde #EndSARS lati fi jale ni ipinlẹ Eko
Ileeṣẹ eto idajọ ni ipinlẹ Eko ni ijọba ti n yẹ iwe ẹsun ọkọọkan wọn wo bayii.
- Awọn jàndúkù yabo ilé Sẹ́nétọ̀ Teslim Folarin, wọ́n kó ẹ̀rọ ata, ọ̀kadà, fírìíjì àti àwọn nkan tí owó rẹ̀ tó N200m
- "Apena fẹ́gbẹ́ Oṣugbo, Opa, Akala àtẹ̀yin awo, ẹ wa ọ̀pá àṣẹ Ọ́ba Akiolu jáde"
- Òkú ọ̀dọ́ 15 ni mo kà ní Lekki amọ́ mo kábàámọ̀ pé a gbà kí ológun gbé okù wọn lọ - DJ Switch
- Àwọn tó fara gba ọta ní Lekki ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè láti dáhùn - Ahmed Tinubu
O ni ọwọ ọlọpaa tẹ awọn afunrasi naa fun oniruuru ẹsun iwa ọdaran bii ile jijo, ipaniyan, ole jija biba dukia onidukia jẹ ati ikọlu ṣaaju ati lẹyin ofin konile o gbele ti gomina Babajide Sanwo-Olu kede lati mu alaafia bọ sipo.
O ni lẹyin ti wọn ba gbe faili ẹsun ọkọọkan wọn yẹ wo tan, awọn to ba lẹjọ lati jẹ ninu wọn yoo kọri si ile ẹjọ lọjọ Aje.
Sanwo-Olu kéde ìlànà ìséde tuntun l'Eko

Oríṣun àwòrán, Babajide sanwo-olu
Gomina Babajide Sanwo-Olu ti dẹ okun konile o gbele ọlọjọyipo to fi sita silẹ bayii.
Nibi ikede to ba awọn oniroyin sọ nileejọba ipinlẹ Eko, gomina Sanwo-Olu ni bẹrẹ lati ọjọ Satide, agogo mẹjọ owurọ si mẹfa irọlẹ ni konile o gbele naa yoo maa wa bayii.
Ará Eko, ẹ pariwo ó tó gẹ́ẹ́ lórí làásìgbò tó gbòde torí ìwọ́de EndSARS - Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, LASG
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti sọ pe ibanujẹ lo jẹ fun oun, bí àwọn janduku ṣe ja iwọde ipolongo #ENDSARS gba.
O ni lati ibẹrẹ pẹpẹ iwọde naa ni oun ti fi ara mọ, sugbọn o ni o kọni lomiinu bi awọn janduku ti ko nifẹ ijọba ati araalu, ṣe bẹrẹ si ni ba dukia ijọba jẹ.
O ni bakan naa ni wọn n jo ile, fọ sọọbu, ti wọn si tun pa ọlọpaa eyi to mu ki awọn ọlọpaa naa bẹrẹ si ni gbe ìbọn kaakiri ilu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọ̀tá Yorùbá ló lo ìwọ́de láti dojú ogun kọ wá - OPC
- "Àwọn ọ̀tá Nàíjíríà tó fẹ́ dojú ìjọba bolẹ̀ ló wà lẹ́yìn ìwọ́de EndSARS"
- Ó parí ni ohùn tó gbẹnu ọ̀pọ̀ ọmọ Nàíjíríà lẹ́yìn ọ̀rọ̀ Buhari
- Ìwọ́de EndSARS kìí ṣe ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yàmẹ̀yà, ara ti kan àwọn èèyàn ni - Afenifere
- Buhari kọ́ ni ìṣòro wa, bó ṣe wà láti láéláé rèé - Fr Mbaka
- Àwọn ọ̀dọ́ fi ọ̀nà àrífín pe Tinubu lórí aago àmọ́ ó ní òun kò mọwọ́-mẹsẹ̀ nípa ìpànìyàn Lekki
- Á ràgà bo CCTV Lekki bí i ẹ̀rí tó dájú fún ìwádìí ìpànìyàn - Sanwo-Olu
- SERAP gbé ìjọba àpapọ̀ lọ ilé ẹjọ́ àgbáyé ICC lọrí ẹ̀sùn ìpànìyàn
"Iṣẹlẹ to waye ni Lekki lọjọ Iṣẹgun ba ni lọkan jẹ, gbogbo wa si ti fẹnu kò pe iru iṣẹlẹ naa ko tun ni waye mọ."

Gomina Sanwo-Olu sọ pe ko si ẹni to fun awọn sọja to yinbọn mọ awọn oluwọde ni Lekki nipinlẹ Eko ni àṣẹ lati ṣe bẹ ẹ.
"Gbogbo nnkan to ṣẹlẹ yii la fi ọwọ wa tun ṣe, mo ṣe tan lati sisẹ, sugbọn mo nilo iranlọwọ yin. "
O fi kun ọrọ rẹ pe, ijọba yoo gbe igbimọ kalẹ lati ṣe iwadii àwọn nkan to fa awọn wahala to waye ọhun.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Gomina ipinlẹ Eko wa rawọ ẹbẹ si awọn obi lati ba awọn ọmọ wọn sọrọ pe, ki wọn ma ṣe darapọ mọ awọn janduku to n ba dukia ijọba jẹ.
"Ẹ kilọ fawọn ọmọ yin lati gba alaafia laaye, ẹ pariwo o to gẹẹ lori laasigbo to n lọ lọwọ yika ipinlẹ Eko lati ipasẹ iwọde EndSARS."
Bakan lo kesi awọn ọba, baalẹ ati awọn olori ẹṣin musulumi, Kristẹni ati ẹṣin ibilẹ lati fi ọwọ sowọpọ pẹlu ijọba, ki opin le ba rogbodiyan to n waye nipinlẹ Eko.
Wo ohun táwọn jàǹdùkú ṣe sí ilé ẹjọ́ Igboṣere l'Eko
Kò sáyè iwọ́de mọ́ l'Eko ẹ lọ tọwọ́ yín bọṣọ - Ọlọ́pàá
Ileeṣẹ ọlọpaa ti fi ikilọ sita pe ko saye iwọde mọ ni ipinlẹ Eko bẹrẹ lati agogo mẹrin ọjọ Iṣẹgun Ogunjọ oṣu kẹwaa ọdun 2020.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lo kede bẹẹ ninu Atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa naa, Muyiwa Adejobi fi sita lọjọ Iṣẹgun.

O ṣalaye pe lẹyin agbeyẹwo awọn ikọlu to waye lasiko iwọde naa lawọn ibikan nipinlẹ Eko ni wn se ipinnu ọhun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìwọ́de #EndSARS rán èèyàn méjì sọ́run n‘Ibadan, Seyi Makinde da ikọ̀ Operation Burst sígboro
- N kò ní buwọ́ lu ìṣúná tí kò pèsè owó fún ẹ̀bí àwọn tó kú nínú ìwọ́de EndSARS - Gbajabiamila
- "Ẹ ràn wá lọ́wọ́ láti rí àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó sálọ ní Oko àti Benin padà"
- Ìwọ́de EndSARS ló ń sọ pé inú ń bí àwọn ọ̀dọ́, ìjọba, ẹ náání wọn - Obasanjo
- Ẹni iyì àti akíkanjú tó ṣe gbẹ́kẹ̀lé làwọn èèyàn Akure, ilú ìyá mi - Seyi Makinde
- Ẹ̀yin ọ̀dọ́ ti rí èrè ìwọ̀de yín lórí EndSARS àmọ́ ẹ ṣọ́ra, kẹ má baà sọ èrè náá nù - Tinubu
- Owó ìrànwọ́ Covid-19 dé, ìjọba fẹ́ san ₦75bn fún 54,000 olókoòwò
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti iléèwé pa nítorí ìwọ́de #EndSARS
- Ìrẹ̀wẹ̀sì ń bá wa torí ìdánwò NECO tẹ ń ṣún síwájú lọ́pọ̀ ìgbà - Akẹ́kọ̀ọ́, ọ̀gá iléèwé
Adejobi ni awọn ikọlu yii lo nii se pẹlu kikọlu awọn ọlọpaa ati ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu awọn araalu.

O ni eyi fihan pe awọn janduku ti sa asawọ wọnu iwọde naa, wọn si ti n lo anfani iwọde ọhun lati fi dana iwa laabi kaakiri ipinẹ Eko.
O ni pẹlu bi gomina Babajide Sanwo-Olu si ti kede ofin konile o gbele bayii, ileeṣẹ ọlọpaa ti ko awọn ọlọpaa kogberegbe da sigboro lati lati rii daju pe aṣẹ koni o gbele ọlọjọyipo naa fidi mulẹ daadaa.
Ni owurọ ọjọ Iṣẹgun lawọn janduku kan nibi iwọde ENDSARS l'Eko kọlu agọ ọlọpaa kan lagbegbe Orile ti wọn si dana sun un.
Bí o bá fẹ́ darapọ̀ mọ́ ikọ̀ ọlọ́pàá SWAT tí yóò rọ́pò SARS, wo àmúyẹ tí o gbọ́dọ̀ ní

Oríṣun àwòrán, PMNews
Lẹyin ti ọga ọlọpaa patapata lorilẹede Naijiria wọgile ikọ SARS gẹgẹ bi ara ipe awọn ọdọ to n wọde fun fifi opin si iwa aṣemaṣe ikọ naa ati ileeṣẹ ọlọpaa lapapọ, ikọ tuntun ti wọn fẹ da silẹ yoo bẹrẹ igbaradi ni ọjọ Aje.
Eyi ni awọn amuyẹ ti ileeṣẹ ọlọpaa ni yoo wa fun awọn ọlọpaa ti yoo darapọ mọ ikọ naa.
Ọga agba patapata nileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Muhammed Adamu ṣalaye ni ọjọ Aiku pe awọn ọlọpaa ti yoo darapọ mọ ikọ kogberegbe ti wọn fẹ fi rọpo SARS naa gbọdọ ni awọn amuyẹ wọnyii.
Ọga ọlọpaa Adamu ṣalaye pe awọn ọlọpaa ti oun yan si ikọ naa
1.Wọn jẹ ọdọ ẹlẹjẹtutu
2.Wọn ni okun ati agbara.
3.Wọn ti lo ọdun meje tabi jubẹẹ lọ lẹnu iṣẹ ọlọpaa
4.Wọn ko ni abawọn lẹnu iṣẹ wọn
5.Wọn ko ni ẹsun iwa ibajẹ kankan lẹnu i'sẹ
6.Wọn ko ni ẹsun titẹ ẹtọ araalu mọlẹ tabi ṣi ibọn lo.
7.Wọn sangun lati farada eto idanilẹkọ ati igbaradi ikọ SWAT
Ọga ọlọpaa Adamu ṣeleri pe awọn ọlọpaa iks naa yoo ṣe iṣẹ wọn bi iṣẹ bi o ti tọ ati bi o ti tọna.













