Lizzy Anjorin: Owó iná ọba kọjá agbára wa, ìjọba kò fẹ́ ká nísinmi

Oríṣun àwòrán, Instagram/ Lizzy Anjorin
Gbajugba oṣere lorilẹede Naijiria, Lizzy Anjorin ti kesi awọn ọdọ, lati ri wi pe wọn ṣe iwọde tako ifiyajẹni ati ipaniyan awọn ọlọpaa ni pẹlẹ putu.
Anjọrin sọ eyi lori ẹrọ ayelujara, nigba to n kaakiri awọn ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni agbegbe Ajah nipinlẹ Eko.
Lara awọn agọ ọlọpaa to kan si ni, nibi to ti ba awọn ọga ọlọpaa ibẹ sọrọ ni Ajiwe, Langbasa, Maroko, Ilasan ati Ikota.
Ninu fidio naa ni Anjorin ti rọ awọn ọdọ lati ri wi pe wọn fi suuru ṣe iwọde naa, nitori awọn obi awọn ọdọ naa ṣi nilo wọn.
- Lizzy Anjorin: Mi ò bẹ Toyin o! Ẹ̀yin olólùfẹ́ mi àti ẹbí ni mo bẹ̀
- Ọkọ mi kò fẹ́ràn oúnjẹ òyìnbó àfi ti ìbílẹ̀ - Lizzy Anjorin
- Toyin Abraham kìí bá èmi náà yọ̀, ni kò jẹ́ kí ń gbé e lárugẹ fún ayọ̀ ọmọ - Lizzy Anjorin
- Ariwo ló ń mú owó wọlé fún mi, kò wù mí láti gbé ayé tó dákẹ́ rọ́rọ́ - Lizzy Anjorin
- Gbẹgẹdẹ gbiná! Toyin Abraham fẹ́ wọ́ Lizzy Anjọrin lọ sílé ẹjọ́
''Awọn obi wa ran wa lọ si ileewe lati le jere awọn ọmọ wọn, nitori naa ẹ pada si ile layọ ati alaafia ki ireti le wa fun awọn obi''
''Mo rọ yin ki ẹ ṣe jẹjẹ nitori awọn onijagudujagan le lo ifẹhonuhan naa lati fi hu iwa buburu lasiko yii''.

Oríṣun àwòrán, Lizzy Anjorin/Instagram
Oṣere naa ni oun wa lẹyin awọn ọdọ to n fẹhọnuhan nitori ọdọ ni oun naa, ti wọn si gbọdọ ja fun ifẹ ara ilu.
Bakan naa ni o fikun wi pe, awọn ọdọ kii ṣe adari ni ọla mọ, adari loni ni awọn ọdọ, nitori naa ni wọn gbọdọ ja fun eto awọn ọmọ Naijiria.
O rọ awọn eniyan lati ṣe ifẹhọnuhan ninu ile wọn, tabi ki wọn bọ si adugbo wọn ni ọkọọkan ati ejeeji lati ṣe ifẹhọnuhan tako iṣekupani awọn ọlọpaa.
''Awọn ọlọpaa ko le e dun mahuru-mahuru mọ wa nitori ẹtọ wa ni lati fẹhọnuhan tako nnkan ti ko ba ba wa lara mu.''
'' Jẹun ki o yo daradara ki o to lọ ṣewode, ma lọ lai si ounjẹ ninu rẹ.''
''Ẹni to ba ni ounjẹ ko fun ọmọnikeji rẹ, pẹlu omi, awa ọdọ asiko yii kii ṣe alajẹbanu tabi wọbia''
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn ọ̀dọ́ se ìrẹsì jọ̀lọ̀ọ́fù ní márosẹ̀ Benin sí Ore láti fẹ̀hónú hàn
- Afárá Marina àti Eko yóò di ṣíṣí padà lọ́la
- Wo àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Nàìjíríà àti l'Áfíríkà tó ń wólẹ̀ àdúrà kí Trump lè wọlé ìbò ààrẹ America
- Iléeṣẹ́ ológun bẹ̀rẹ̀ 'Operation Crocodile Smile' yíká Naijiria fún oṣù méjì
- Òkú tó jí lọ́jọ́ kejì ní mọ́ṣúárì padà kú síléèwòsàn
- Ṣé lóòtọ́ ni àjọ ọlọ́pàá dá Abayomi Shogunle àti Dolapo Badmus dúró?
''Bakan naa ti wahala ba ṣẹlẹ, ẹ ma kọkọ ma a yaworan, ẹ sa asala fun ẹmi yin ati ẹnikeji rẹ''
Ẹwẹ, gbajugba osere lorilẹede Naijiria, Lizzy Anjorin naa tun sọrọ lori owo gọbọi ti awọn ẹka amunawa lorilẹede Naijiria mu wa fun wọn loṣu.
O ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrun naira, ₦100,000 ni wọn mu wa fun oun gẹgẹ bi owo ina to lo laarin oṣu kan, ti ko si si ina naa deede.
''Ohun gbogbo di owo gogo, ₦28,000 si ₦35,000 ni wọn n ta irẹsi ni ọja, nitori naa a fẹ ayipada ti ijọba ṣeleri fun wa.
Nibayi naa, Lizzy Anjorin ti lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Ajiwe, ni Ajah, lati gba beeli awọn ọdọ to n se iwọde, tawọn ọlọpaa mu si ahamọ wọn.
Amọ nibẹ ni awọn ọlọpaa ti sọ fun wi pe, awọn ko fi panpẹ ọba mu ẹnikẹni to jẹ afẹhọnuhan, o ni ọga ọlọpaa ni agbegbe naa ti kilọ fun osisẹ rẹ lati maṣe mu afẹhọnu kankan lagbegbe naa.
Bakan naa ni awọn ọlọpaa naa fi da loju pe, ko si rogbodiyan ni agbegbe naa, nitori awọn afẹhọnuhan naa ṣe iwọde wọn ni pẹlẹ putu.
Awọn ọlọpaa naa sọ fun Lizzy Anjorin pe, awọn to ṣe magomago ti awọn eniyan wa fi ẹjọ wọn sun, lo wa ni ọgba ẹwọn nibẹ.
Ọkan lara awọn ọdọ to jẹ afẹhọnuhan lagbegbe naa fidi rẹ mulẹ fun Lizzy pe, ko si wahala kankan nitori pẹlu suuru ni wọn fi aidunnu wọn han.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Amọ, o fikun wi pe awọn ọlọpaa ni agbegbe Surulere nipinlẹ Eko ni wọn mu awọn ọdọ to n ṣe ifẹhọnuhan lagbegbe naa ni oru mọjumọ.
Bẹẹ si ni Lizzy Anjorin tẹsiwaju lati ma lọ si awọn ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni agbegbe naa, to si n rọ awọn araalu atawọn ọdọ lati maa fi ọwọ fun ẹlomiran, ki wọn le gba ohun ti wọn fẹ.
O ni bi oun ko ba le darapọ mọ awọn oluwọde to wa loju popo, o yẹ ki oun le seranwọ lati gba awọn ọdọ ti ọlọpaa ba ko silẹ.
Bakan naa lo rọ awọn gbajumọ miran lati lọ sawọn agọ ọlọpaa to wa ladugbo wọn, lati gba awọn ọdọ to n se iwọde, ti ọlọpaa ba mu si ahamọ silẹ.















