India: Arakunrin ti wọn doola ẹmi rẹ kuro ni Ile igbokusi pada jade laye

Arakunrin Balasubramanyam ti wọn doola ẹmi rẹ kuro ninu ẹrọ amohuntutu to wa ni ile igbokusi ti papoda.Balasubramanyam to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelaadọrin lo n gbe ni ilu Tamil Nadu, lorilẹede India.
Ojo Aje ọsẹ yii ni wọn gbe arakunrin naa lọ si ile iwosan, ti wọn ko si sọ ohun to ṣe e, lẹyin naa ni wọn gbe e lọ si ile igbokusi.
Amọ, ọjọ Keji ti awọn agbokusi de lati lọ sin in ni wọn ba a nibi ti o ti n gbọn, ti wọn si tete mọ wi pe o si wa laaye.
- Jàǹdùkú kọlu gómìnà Oyetola níbi ìwọ́de #ENDSARS, èèyàn méjì kú
- Wo àfiwé owó oṣù Ọlọ́pàá Nàìjíríà pẹ̀lú akẹgbẹ́ wọn lókè òkun
- Wo àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Nàìjíríà àti l'Áfíríkà tó ń wólẹ̀ àdúrà kí Trump lè wọlé ìbò ààrẹ America
- Trump kò yẹ láti jẹ́ ààrẹ lásìkò yìí, èèyàn kò le fi mọ̀kàrúrù ṣe ààrẹ - Michelle Obama
Wọn sare gbe e lọ si ile iwosan, amọ o jade laye ni ọjọ Eti.
Adari ileewosan ijọba ni agbegbe Salem, Dokita Balajinathan ni wọn gbe alaarẹ naa wa pẹlu bi o ṣe n gbọn naa, amọ o ku lẹyin ti o lugbadi aisan ọna ọfun.
Dokita naa ni ohun ko le sọ ni pato, igba ti arakunrin naa ti wa ninu yara igbokusi ninu otutu naa.
Lẹyin ti dokita kan ni ileewosan aladani sọ wi pe o ti jade ni aye ni ọjọ Aje, ni awọn ẹbi rẹ fi pada wa lati gbe oku rẹ losin.
Amọ wọn ko ri iwe ẹri to fihan gbangban pe lootọ, lo ti ku amọ aburo baba naa ni oun buwolu iwe eri pe ẹgbọn oun ti ku.
Ọlọpaa ni agbegbe naa ni awọn ẹbi ati awọn ara naa ko ri sabuke iwe eri pe o ti ju jade.
Nibayii, wọn ti bere ẹjọ pẹlu awọn mọlẹbi baba naa, nitori iwakuwa wọn lo jẹ ki arakunrin naa ku.
Awọn ẹbi rẹ ni o tun ni arun ọpọlọ naa pelu ẹ, Balasubramanyam fi iyawo kan ati ọmọ meji ati aburo rẹ.
Ko i tii ran gbangba boya ijọba yoo ṣewadii ileewosan aladani naa, bakan naa ni awọn mọlẹbi ati dokita naa ko gbe ipe BBC lati ṣewadii naa.













