US Elections 2020: Primate Ayodele ní òun ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Trump yóò fìdírẹmi, tí kò bá ṣọ́ra ṣe

Oríṣun àwòrán, Primate Ayodele
Oludasilẹ ijọ Inri Evangelical Spiritual Church, Primate Elijah Ayodele, ti tu aṣiri bo ṣe kilọ fun aarẹ ilẹ America, Donald Trump, ṣaaju ko to o gbe apoti ibo fun saa keji.
Ayodele sọ fun iwe iroyin Tribune pe, oun kilọ fun Trump lati ṣọra ṣe lori ilana iṣejọba to n lo, ati ofin to n gbe jade, to ba fẹ ki wọn dibo yan oun lẹẹkeji.
O ni "lati ọdun 2017 ni mo ti ki Donald Trump nilọ lori erongba rẹ fun saa keji, ṣugbọn ko gbọran. Mo sọ ọ daadaa pe, Joe Biden yoo bori, ti ẹgbẹ oṣelu Democrats ba fi yan-an ni aṣoju wọn.
"Mo sọ asọtẹlẹ pe aarẹ ilẹ America yoo sọ awọn ọrọ ti ko tọ ọ, lasiko ipolongo ibo. Mo si ri i pe diẹ lara awọn to finu tan yoo kọwe fipo silẹ ninu iṣakoso rẹ."
Ko tan sibẹ o, o ni oun tun sọtẹlẹ pe 'Trump yoo ja fitafita lati bori, yoo si gbe awọn igbesẹ kan to le mu iyapa ba orilẹ-ede America.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Olori Badra sọ̀rọ̀ nípa ayé rẹ̀, ó ní ẹ́ bá òun sọkún
- Akọ tó fẹ́ akọ ṣayẹyẹ ìgbéyàwó ọdún kẹrin, wọ́n ra ilé kejì
- Jàndùkú ṣọṣẹ́ lọ́jà Agbeni, àwọn àti agbófinró kọjú ìbọn síra wọn
- Díẹ̀ ló kú kí owó tán l‘ápò mi torí ìrànwọ́ Coronavirus - Pasuma
- Mo ṣèlérí láti rí sí ìrẹ́pọ̀ àti ìwòsàn Amẹ́ríkà - Joe Biden
- Ìjọba Oyo gbé ilé ẹ̀kọ́ gíga kan tìpa torí àrùn Coronavirus
Igba akọkọ kọ niyii ti Primate Ayodele sọ asọtẹlẹ nipa awọn oloṣelu. O sọ nipa Godwin Obaseki, ti ipinlẹ Edo, ati Rotimi Akeredolu, ti ipinlẹ Ondo.
Wo àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Nàìjíríà àti l'Áfíríkà tó ń wólẹ̀ àdúrà kí Trump lè wọlé ìbò ààrẹ America

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Pẹlu oniruuru ọrọ to ti sọ si awọn orilẹede Afirika, sibẹ awọn ẹlẹsin Kristẹni to n fọ fun aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump ṣi wa.
"Ẹ gbadura fun un (Trump) tori ti Ọlọrun ba gbe ọkan lara awọn ọmọ rẹ si ipo;
Ogun ọrun apaadi maa n fẹ ṣe ohun gbogbo lati ba ti ẹni bẹẹ jẹ".
Eyi ni gbajugbaja Pasitọ ijọ Naijiria kan, Chris Oyakhilome sọ ninu iwaasu rẹ loṣu kẹfa.
O tun ni awọn to n pẹgan oludije ẹgbẹ oṣelu Republican to n gbe apoti ibo fun saa keji ko fẹran awọn alatilẹyin rẹ.
"Inu n bi wọn pe Trump n ti Kristẹni lẹyin ni, kẹẹ yaa tete mọ. Torinaa, ẹyin tẹẹ jẹ Kristẹni gangan ni wọn korira".
Kaakiri aye ni wọn ti maa n wo iwaasu Pasitọ Chris to fi mọ ni Amẹrika.
Bakan naa aarẹ Trump ti gbajumọ daadaa lawọn orilẹede to wa ni Afirika bii Naijiria ati Kenya gẹgẹ bi iwadii ṣe fihan ninu oṣu kinni ọdun to si jẹ pe awọn to gba tiẹ ko bikita pe o ṣapejuwe Afirika gẹgẹ bi ibi ẹgbin ti wọn n da ilẹ si lọdun 2018.
Ilu to fẹran ṣiṣe ẹsin pupọ ni orilẹede Naijiria ati Kenya.
Awọn ijọ nla nla lo kun iha Guusu Naijiria tii ṣe orilẹede to pọ ju ni Afirika. Bakan naa ni Kenya, ọpọ oloṣelu a maa lọ ṣọọṣi lati ba awọn alatilẹyin wọn sọrọ.
Ọpọlọpọ ijọ ajihinrere ni Afirika ti ko fọwọ si ofin ṣiṣẹ oyun ati ki ọkunrin maa fẹ ọkunrin gẹgẹ bi aya ni ko naani Barack Obama to jẹ aṣaaju Trump pẹlu bo ṣe niru nidi to tan mọ ilẹ Afirika.
"Ijọba Obama ti n pete awọn akanṣe aato kan nilẹ Afrika eyi to si n kọ awa adari Kristẹni kan lominu.
Itura lo wa jẹ lasiko Trump pe ko ṣẹlẹ", Richard Chogo, pasitọ ni ijọ onitusilẹ kan ni Nairobi lorilẹede Kenya sọ fun Akọroyin BBC.
O kan saara si iṣejọba Trump pe o ṣe nkan sọrọ awọn ileeṣẹ to n pese rọba idaabobo atawọn to n ṣẹ oyun lawọn orilẹede Afirika.
Awọn ijọ ajihinrere alawọfunfun naa n gbaruku ti Trump bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan dudu to jẹ ọmọ ijọ aye ode oni to n pẹlu ẹgbẹ Democrat bu ẹnu atẹ lu igbesẹ aarẹ Trump pọ.
Venerable Emeka Eze to jẹ alufaa ati archdeacon ni ijọ Angilika nipinlẹ Enugu naa ni iwoye oun nipa oṣelu maa n tẹle ohun ti iwe mimọ ba sọ.
O ti n gbadura pe ki Ọgbẹni Trump fi ẹyin Joe Biden janlẹ ninu idibo oṣu kẹrinla o si ya akoko sọtọ lojoojumọ lati maa gbadura fun imularada aarẹ Trump laipẹ yii to wa nile iwosan tori aisan coronavirus.

Oríṣun àwòrán, AFP
Bii ti pasitọ Chogo, oun naa gbagbọ pe ki wọn ma fi aṣiṣe kinkin ti Trump ba ṣe bo daadaa rẹ mọlẹ.
Fun apẹrẹ bo ṣe tu awọn oluwọde "Black Lives Matter" ka eyi to June bii igbesẹ ikorira.
Aarẹ Trump ti fọwọ sọya pe oun ni aarẹ to ṣe fun awọn alawọdudu to ti di ọmọ Amẹrika daadaa ninu itan paapaa lori ọrọ iṣẹ.
Rev Juliet, Alufaa kan ni ilu Eko ni "Ọlọrun lo yan Trump pe o ni ... iranṣẹ mi ti yoo ṣe ifẹ mi ni".
"Ọlọrun n fẹ Digbolugi"
Ololufẹ Ọgbẹni Trump kan lo n ṣe eto adura lọsọọsẹ fun atunyan rẹ to si ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi Trump pẹlu ọpọlọpọ ọrọ iwuri loju opo Facebook.
O ni Ọlọrun fun oun ni iran nipa Trump: "O sọ fun mi pe oun n wa digbolugi, ọkurin to ni igboya tori awọn iṣẹ kan wa ti oniwapẹlẹ ko lee ṣe". Rev Bintie sọ bẹẹ.
"A fẹ ẹni ti yoo faaye gba ẹtọ awọn onigbagbọ".

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Pasitọ Chogo tilẹ tun sọ pe "koda koo jẹ Saddam Hussein tabi Muammmar Gaddafi, ohun kan tabi meji ṣi wa ti o ti ṣe fawọn eeyan rẹ ni daradara".
Ọgbẹni Trump ti sọ fawọn Kristẹni alatilẹyin ninu ọpọ atẹjade Twitter pe bi oun ko ba wọle ninu oṣu kọkanla, ẹtọ ṣiṣe ẹsin ara ẹni ati ofin to de oyun ṣiṣẹ wa lewu.
- Ọlọ́pàá tún dé o! Wọ́n fún obìnrin kan lọrùn pa, awuyewuye ti ń wáyé
- Ẹ wo Daniel tí wọ́n fẹ́ yẹgi fún lẹ́yìn tí US kò ṣe irú ẹ̀ fún odidi ọdún 17
- Mí ò le nífẹ̀ẹ́ obìnrin Nàìjíríà kankan mọ lẹ́yìn ti mo ti tọ́ obìnrin òyìnbó wò- Issa
- Ẹ foríjìn wá ọmọ Nàìjíríà, mó mọ̀ pé ẹ̀ ń bínú tórí a kò tètè gbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ EndSARS- Osinbajo
















