Wasiu Alabi Pasuma: Àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19 kọ́ mi láti má a ṣọ́wó ná

Pasuma

Oríṣun àwòrán, Instagram/@officialpasuma

Gbajugbaja akọrin Fuji nni, Wasiu Alabi Pasuma, sọ pe ẹkọ ti ko ni akawe ni ajakalẹ aarun Covid-19 kọ oun.

Pasuma sọ ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu iwe iroyin The Punch pe, diẹ lo ku ki apo asunwọn oun gbẹ fun owo, nitori awọn toun se iranlọwọ fun lasiko ti arun naa gbilẹ ni Naijiria.

O ni "Ajakalẹ aarun naa kọ mi lati ma a ṣọ owo na, ati lati ṣe eto ọna abayọ silẹ ninu okoowo to wu ki eeyan ma a ṣe."

Pasuma

Oríṣun àwòrán, Instagram/@officialpasuma

"O to asiko kan to jẹ pe, owo diẹ bayii lo ku ki owo tan ni asunwọn mi ni banki, nitori bi mo ṣe n ṣe yafun-yafun fun awọn ti mo ranlọwọ.

Sugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe, a ti n bọ ninu rẹ diẹdiẹ."

Laipẹ yii ni iroyin jade lori ayelujara pe, awọn ọdọ kan koro oju si Pasuma lasiko iwọde #ENDSARS.

Iroyin sọ pe niṣe ni awọn ọdọ naa le e kuro laarin wọn bi ẹni le ajá, nibudo iwọde kan, ti wọn ko si gba a laaye lati ba wọn sọrọ.

Àkọlé fídíò, Bose Okeowo: Àárẹ̀ kékeré ló sọ mi dí aláàbọ̀ ara yìí ṣùgbọ́n...

Amọ ṣa, akọrin naa sọ pe iṣẹlẹ naa ko waye rara.

O ni tako iroyin ti awọn eeyan n sọ kiri, gbọyi-sọyi lati ọdọ awọn to korira oun ni iroyin naa.

"Lati ibẹrẹ pẹpẹ ni mo ti n ṣatilẹyin fun awọn oluwọde naa, gẹgẹ bi akọrin Fuji, ọpọlọpọ awọn akẹẹgbẹ mi si lo ṣe bẹẹ."

O ni "ọmọ Naijiria ni gbogbo wa, ti Naijiria ba si dara ju bo ṣe wa yii lọ, gbogbo wa la o ni ibi ti a le pe nile, ti a si ma a gbe ninu irọrun."