Kwam1: Kìí ṣe emí ni mó ràn ẹni tó sọ̀rọ̀ abùkù sí FIBAN níṣẹ́- Wasiu Ayinde

Kwam1: Kìí ṣe emí ni mó ràn ẹni tó sọ̀rọ̀ abùkù sí FIBAN níṣẹ́- Wasiu Ayinde

Oríṣun àwòrán, k1deultimate/Instagram

Ọba orin fuji Wasiu Olasunkanmi Marshal K1 tí fi ọ̀rọ̀ síta pé, òun jìnà gédégédé sí ọ̀rọ̀ kan tí alákoso orin rẹ̀ sọ pẹ̀lú BBC News Yoruba lọ́jọ́ Aiku.

Nínú ọ̀rọ̀ alakoso orin Wasiu, Adebayo Olasoju lásìkò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nu lórí ǹkan tó ṣẹlẹ̀ níbi ayẹyẹ tí wọ́n ti fẹ̀sùn kan pé Wasiu Ayinde lu gbájugbàja sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kan ni ìpínlẹ̀ Ogun ló ti sọ̀rọ̀ àlufànsá sí ẹgbẹ́ FIBAN.

Ọ̀rọ̀ yìí sì ló yọ idà lápó àwọn FIBAN ti wọ́n si tí ni àfi tí Wasiu Ayinde ba gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan kí àwọn tó dẹ̀yìn lẹ́yìn lílọ sí ọ̀dọ̀ Aáàfìn Oyo láti gba oyè Máyégun to jẹ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ tí ẹgbẹ́ FIBAN bá BBC Yorùbá sọ lánàá ni wọ́n ti sọ̀pé'Nítori ààbò ẹmí MC Murphy ló fi gbá #100,000 lọ́wọ́ K1 lọ́jọ́ ìṣẹ̀lẹ̀', èyí si ni wọ́n sàlàye pé, nígbà ti Wasiu Ayinde ba túba ni àwọn yóò mọ̀ bóya àwọn yóò dá owó náà padà tàbí bẹ́ẹ̀kọ́.

Nínú àtẹjáde ti agbẹnusọ K1 Kunle Rasheed fi sọwọ́ sí BBC News Yoruba ló ti sàlàyé pé àwọn ọ̀rọ̀ àbùkù tí amúgbálẹ́gbẹ̀ K1 Adebayo Olasoju sọ si ẹgbẹ́ FIBAN yì kìí ṣe ìṣèsí tàbi ìwòye K1 rárá.

Àtẹjáde náà ni K1 ko fún ẹni tó sọ̀rọ̀ náà lásẹ láti sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, nítórí náà K1 yọ ara rẹ̀ pátápátá kúrò nínú gbogbo ǹkan tó sọ si ẹgbẹ́ FIBAN. Bákan náà ni K1 rọ FIBAN àti gbogbo àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn tó kù láti tẹ̀síwájú nínú àjùmọ̀ṣe wọ́n tó dánmọ́nrán.

Kwam1: Kìí ṣe emí ni mó ràn ẹni tó sọ̀rọ̀ abùkù sí FIBAN níṣẹ́- Wasiu Ayinde