World Teachers Day: Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé rèé nípa ìlànà àkànṣe owó oṣù tuntun fáwọn òlùkọ́

Olukọ kan n kọ awọn akẹkọ ni kilaasi

Oríṣun àwòrán, Google

Ni Ayajọ Ọjọ awọn olukọ lagbaye, World Teachers Day ni Aarẹ Buhari kede ilana tuntun fun owo oṣu awọn olukọ ni Naijiria.

Minisita fun eto ẹkọ, Adamu Adamu to ṣoju aarẹ Buhari, lo ka ikede naa jade fun awọn eniyan ni ibi ayẹyẹ ohun ni ilu Abuja.

Ọpọlọpọ awọn eniyan si lo ti n beere pe bawo ni ilana owo oṣu tuntun yii yoo ṣe lọ, ati wi pe, ki ni awọn alakalẹ tuntun naa da le lori.

Idi ree ti BBC Yoruba fi se akojọpọ alaye nipa ilana owo osu tuntun ti aarẹ́ Buhari kede fawọn olukọ naa.

Ẹkunrẹrẹ alaye nipa ilana owo osu tuntun fawọn olukọ:

  • Ijọba yoo ṣe agbekalẹ ilana tuntun ti wọn yoo gba lati ma a san owo oṣu awọn olukọ
  • Nibayii, ijọba ti fi ọdun marun kun ọjọ ori ifẹyinti awọn olukọ lati ọgọta ọdun si marundinlaadọrin
  • Bakan naa ni wọn ti fi kun iye ọdun ti olukọ yoo fi ṣiṣẹ ko to fẹyinti, lati ọdun marundinlogoji si ogoji ọdun
  • Awọn olukọ to wa ni igberiko yoo ma gba owo iranwọ pataki
  • Ijọba yoo fikun owo iranwọ imọ sayẹnsi
  • Awọn olukọ yoo ma a gba owo iranwọ pataki
  • Awọn ọmọ olukọ yoo ma lọ si ileewe lọfẹ ni ileewe ti awọn obi wọn ti n ṣiṣẹ
  • Wẹrẹ ti awọn akẹkọọ imọ ẹkọ olukọ ni fasiti ba ti n jade ni ileewe giga, ni wọn yoo ma ri iṣẹ gba lọwọ ijọba
  • Awọn akẹkọọ imọ ẹkọ yoo ma gba owo iranwọ pataki lasiko ti wọn ba wa ni fasiti
  • Owo ami ẹyẹ pataki yoo wa fun awọn akẹkọọ imọ ẹkọ ni fasiti
  • Ijọba yoo ma lo owo iranwọ TETFund lati fun awọn olukọ ni ẹkọ imọ ti wọn nilo lati ṣe iṣẹ wọn bi iṣẹ
  • Awọn akẹkọọjade ni fasiti to yan isẹ olukọ laayo yoo ma tete ri iṣẹ gba lọwọ ijọba
  • Owo iranwọ pataki yoo wa fun awọn olukọ to ti ṣiṣẹ fẹyinti ni Naijiria.

Ẹ̀yin olùkọ́, ìlànà àkànṣe owó oṣù tuntun dé fún yín

Saaju la ti kọkọ mu iroyin wa fun yin pe aarẹ Muhammadu Buhari ti kede ilana akanse owo osu fawọn olukọ lorilẹede yii.

Ikede yii si lo n waye ni oni ọjọ Isẹgun, ọjọ Karun osu kẹwaa, tii se ayajọ ọjọ awọn olukọ lagbaaye.

Olukọ kan n kọ awọn akẹkọ ni kilaasi

Oríṣun àwòrán, @OfficialSeyiMakinde

Minisita feto ẹkọ, Adamu Adamu , to soju aarẹ Buhari nibi eto ti wọn fi n sami ọjọ olukọ nilu Abuja, lo sisọ loju ọrọ yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adamu ni Buhari gbe igbesẹ naa lati se iwuri fawọn olukọ jakejado Naijiria, ki wsn lee sa ipa wọn lati sisẹ kara siwaju si, ki wsn si tun lee dantọọ lẹnu isẹ.

Àkọlé fídíò, Ojú àwọn èèyàn Ondo ti là pé ìnira ni ẹgbẹ́ APC mú wá - Jegede PDP

Bakan naa ni aarẹ Buhari tun sisọ loju r pe, lati akoko yii lọ, awọn olukọ ko ni fẹyin ti mọ lẹnu isẹ lẹyin ti wọn ba ti lo ọdun marundinlogoji, amọ o tun fi ọdun marun kun ọdun ifẹyinti wọn.

Eyi tumọ si pe ogoji ọdun ni awọn olukọ yoo maa lo lẹnu isẹ bayii, ki wọn to fẹyin ti.