Rauf Aregbesola sọ bó ṣe yẹ kí òbí máa fètò sọ́mọ bíbí

Oríṣun àwòrán, @AregbeQuotes
Minisita to n ri si ọrọ abẹle lorilede Naijiria to tun jẹ gomina ana ipinlẹ Osun, Ọgbẹni Rauf Aregbesola ti ni ki awọn obi din iye ọmọ ti wọn n bi ku.
Aregbesola sọ eyi gẹgẹ bi ọkan lara awọn koko ọrọ to maa n fi sita lori ayelujara.
O fi ọrọ rẹ gba awọn lọkọ-laya nimọran lati fi eto si bi wọn ṣe n bimọ nitori ipo ti orlẹede Naijiria wa lọwọlọwọ.
Loju opo Twitter ti Ọgbẹni Aregbesola maa n lo fi kọ awọn koko ọrọ kekeke, o ni "a rọ awọn lọkọ-laya lati maa feto sọmọ bibi".
Bí mo bá ṣáájú ìwọ́de ENDSAReS, kẹ́ẹ mọ̀ pé ẹ̀wọ̀n Kirikiri ni wọ́n á gbé mi lọ jàntò - Naira Marley
O tẹnu mọ ọ pe "a ti n bimọ ju iye awọn ti orilẹede ṣetọju lọ. Torinaa, ọmọ meji si mẹta ti to".
Aregbe ni o yẹ keeyan ṣe bo ṣe mọ ni, ẹlẹwa sapọn lori ọrọ ọmọ bibi lorilẹede Naijiria.
Niwọnba iwọn iye owo tabi na atijẹ ti eeyan ni ni Ọgbẹni Aregbesola ni o yẹ keeyan wo ko to maa ka ọmọ jọ.














