Ondo Election 2020:Tani Akeredolu tó ń díje dupò gómìnà fún ìgbà kejì nípìnlẹ̀ Ondo

Tani Akeredolu tó ń díje dupò nígbàkejì nípìnlẹ̀ Ondo

Oríṣun àwòrán, Akeredolu/instagram

A bi Oluwarotimi Odunayo Akeredolu ( SAN) ni ọjọ kọkanlelogun, Oṣu keje, ọdun 1956.

Idile Ẹni ọwọ Ola Akeredolu ati idile "Lady Evangelist" Grace Akeredolu ni ilu Igbotu, ijọba ibilẹ Ese Odo nipinlẹ Ondo.

O lọ si ile iwe alakọbẹrẹ ni ilu Owo lẹyin naa lo lọ si ile-iwe girama St Aquinas College ni ilu Akure, Loyola College ni Ibadan ati Comprehensive High ni Ayetoro nibi to ti gba iwe ẹri aṣe kagba girama.

Lẹyin naa lo lọ si fasiti ile Ife to ti di Obafemi Awolowo bayii, lati gboye amofin to si kẹkọọ jade ni ọdun 1977, bakan naa ni wọn gbaa si ile ẹkọ awọn amofin lọdun 1978.

Àkọlé fídíò, Ojú àwọn èèyàn Ondo ti là pé ìnira ni ẹgbẹ́ APC mú wá - Jegede PDP

Akeredolu di kọmisọnna eto idajọ ati agbẹjọro ijọba ìpinlẹ Ondo lọdun 1997 si 1999,

O si di amofin agba (SAN) lẹyin naa lo di alaga awọn oluranlọwọ awọn to nilo agbẹjọro laarin ọdun 2005 si 2006.

Tani Akeredolu tó ń díje dupò nígbàkejì nípìnlẹ̀ Ondo

Oríṣun àwòrán, Akeredolu/Instagram

Wọn fẹsun iwa jẹgudujẹra kan ninu oṣu kọkanla, ọdun 2009 nigba ti igbakeji ààrẹ ẹgbẹ awọn agbẹjọro (NBA), akọwe eto itọju ọmọ ẹgbẹ àti igbakeji akọwe owo n pin iwe ẹsun kaakiri pe Akeredolu kowojẹ ati pe o tẹ gbogbo ofin ẹgbẹ loju mọlẹ.

Àkọlé fídíò, 'N500 dé fún gbogbo ọmọ tuntun lóṣooṣù bí mo bá di gómìnà Ondo - Adeleye AAC

Ko pẹ ti ọrọ naa ṣẹlẹ ni awọn alaṣẹ ẹgbẹ NBA se atungbeyẹwo ẹsun naa wọn si da ẹjọ naa sigbo.

Tani Akeredolu tó ń díje dupò nígbàkejì nípìnlẹ̀ Ondo

Oríṣun àwòrán, AFP

Ninu oṣu kejila, lọdun 2009 lasiko ti Akeredolu n ṣe idanilẹkọ ni Akeredolu sọ fun awọn ero pe ko si nkan ti ijọba le se lati ṣe atunto ẹka idajọ ti idibo Naijiria fi le lọ lai ni magomago ninu, bi awọn ara ilu gan ba kọ lati gbe igbesẹ to yẹ lati jẹ ki ibo wọn ni itumọ.

Àkọlé fídíò, Toyin Atoyebi mechanic: Ẹ wo Toyin, ọmọbinrin ọdún 16 tó ń tún skadà àti gẹnẹrátọ̀ ṣe ní

Ni ọdun 2012 ẹgbẹ NBA fi ile ẹgbẹ wọn tuntun ti wọn kọ s'Abuja sọ ori Rotimi Akerdolu nitori gbogbo iṣẹ takuntakun to ti ṣe fun ẹgbẹ ati bi o ṣe sọ ẹgbẹ naa di ilumọọka.

Ni ọdun 2011 Akeredolu wa lara ọpọ ero to fẹ di gomina labẹ asia ẹgbẹ Action Congress of Nigeria (ACN) lati di gomina ipinlẹ Ondo ninu idibo ọdun 2013.

Akeredolu dide labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ACN to si fori gbari pẹlu Olusola Oke ati Mimiko.

Tani Akeredolu tó ń díje dupò nígbàkejì nípìnlẹ̀ Ondo

Oríṣun àwòrán, Akeredolu/instagram

Ni ọdun 2016 Akeredolu dide labẹ oṣelu APC ti ajọ INEC si kede rẹ bi olujawe olubori ni ọjọkẹtadinlọgbọn osu kọkanla ọdun 2016.

Ni ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2016, wọn kede Akerdolu bi ẹni to jawe olubori pẹ idibo 244, 842 nigba ti ọgbẹni Jegede ni ibo 150, 380 ti ọgbẹni Oke si ni 126, 889 gẹgẹ ọjọgbọn Ganiyu Ambali to jẹ alaboju to ibo to soju ajọ INEC.

Ni Bayii, ẹgbẹ oṣelu APC tun fun Akeredolu ni aaye lati tun dije dupo gomina fun idibo ọdun 2020 lẹyin to fi ẹyi Olusola Oke, DI Kkemeke, Segun Abraham àti àwọn miran janlẹ ninu idibo komẹsẹoyọ to waye.

Ni ọjọkọkandinlọgbọn oṣu keje ọdun 2020, Rotimi Akeredolu yan Lucky Aiyedatiwa gẹ́gẹ́ bi olujumọ dije dupo fun idibo ọdun 2020 lẹyin oun ati igbakeji rẹ Agboola Ajayi fija pẹẹta.

Rotimi Akeredolu fẹ Betty Akeredolu ni Iyawo, Ọlọrun si fi ọmọ tawọn lọrẹ

Tani Akeredolu tó ń díje dupò nígbàkejì nípìnlẹ̀ Ondo

Oríṣun àwòrán, Akeredolu/Instagram

Àkọlé fídíò, coronavirus prevention badge update: Wo òótọ́ àti irọ́ tó wà nínú báàjì àyà náà