Boko Haram: Pásítọ̀ Adeboye ní Ikọ̀ Boko Haram àti gbogbò àwọn tó ń sàtìlẹyìn fún wọn kò ní rí ọdún tuntun

Oríṣun àwòrán, Google
Adari ijọ Redeemed Christian Church of God, Pasitọ Enoch Adeboye ti paṣẹ pe ikọ Boko Haram ko ni ri ọdun tuntun ti wọn ko ba jawọ iṣẹ ibi wọn.
Pasitọ Adeboye sọ ọrọ naa lasiko to n waasu ni ibi ayẹyẹ idupẹ ni ijọ Throne of Grace in ilu Eko.
Adeboye ninu iwaasu rẹ to pe ni ''Ki Olorun dide'' ni o ti sọ wi pe awọn alagbatẹru wọn naa ko ni kadun.
- Àwọn ọmọ FIBAN kò gbọdọ̀ lo orin Wasiu Ayinde mọ́ lẹ́yìn ìfìyàjẹní Murphy- FIBAN
- Yoruba wo ló fẹ́ gbé Oduduwa Republic tẹ́ n pariwo - Lizzy Anjorin
- ''Láti òní lọ, FSARS ò gbọdọ̀ káàkiri ìlú mọ́ tàbí tú ẹrù aráàlú wò mọ́''- Ọ̀gá ọlọ́pàá pàṣẹ
- Àwọn olùpolongo ìdìbò Aketi àti Jegede ń forígbárí l'Ondo, bí wọ́n ṣe n yìnbọn ni wọn n sun táyà
O fikun wi pe gbogbo awọn to n tiraka lati da orilẹede Naijiria pada si oko ẹru naa yoo jẹ ninu iya awọn ẹni ibi.

Oríṣun àwòrán, Google
''Gbogbo orilẹede to jẹ ọta amọ ti wọn n ṣe bi ọrẹ si Niajiria, yoo gba idajọ pẹlu''
''Gbogbo ibi ti wọn ti sọ wi pe ko si Ọlọrun fun Naijiria,ni Ọlọrun yoo ti dide fun wọn.''
- ₦750m ni Akeredolu ń gbà lóṣù fún ‘Security Vote’ àti ₦150m owó oṣù - Agboola Ajayi fèsì
- INEC kéde agbègbè ẹsẹ̀ odò 270 ti èrú ìbò ti le wáyé ní ìpínlẹ̀ Ondo
- Ọ̀pọ̀ aráàlú Owo wà nílé ìwòsàn, síbẹ̀ APC àti PDP kò gba ẹ̀bi
- Ẹ gbọ́ òhun tí àwọn olùdíjé sípò gómìnà nípínlẹ̀ Ondo sọ nípa Bàbá ìsàlẹ̀...
- Wike, má gbé jàgídíjàgan wá sí Ondo, APC kò ní ṣ'èèrú nínú ìdìbò gómìnà tó ń bọ̀- Kalejaye
Ninu ọrọ rẹ Adeboye gbadura, o si tun dupẹ pe aarun Coronavirus ti rọlẹ ni Niajiria, to si gbagbọ wi pe laipẹ laijina ni arun Coronavirus yoo di ohun igbagbe ni Niajiria.
Bakan naa ni Pasitọ Adeboye sọrọ tako awọn oju ọna to wa ni Naijiria ti ko dara ti o si ti jasi iku ọpọlọpọ eniyan.
Tí àtúntò kò bá wáyé ní Naijiria, ó ṣeéṣe kó túká- Pásítọ̀ Adeboye
Adari ijọ Redeemed Christian Church of God, Pasitọ Enoch Adeboye ti kesi ijọba lati tete wa ọna abayọ si igbe awọn eniyan to n bere fun iyapa orilẹede Naijiria

Oríṣun àwòrán, PastorEAAdeboye
Adeboye sọ eleyii ni ibi ayẹyẹ ayajọ ọgọta ọdun ti orilẹede Naijiria gba ominira, eleyii ti ijọ Redeemed Christian Church of God ati Nehemiah Leadership Institute gbe kalẹ.
O ni ọrọ aje to dẹnukọlẹ ni Niajiria wa lara oun to mu ki awọn eniyan ma a ja fun ẹya ti wọn.
- Kò yẹ mi ìdí tí Wasiu Ayinde fi hu ìwà àbùkù tó hù sí mí- MC Murphy
- Àdigunjalè báńkì ní Iyin-Ekiti fẹsẹ̀ fẹ, bí wọ́n ṣe rí wa - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Ìlànà ‘Referendum’ nìkan la fi le gba orílẹ̀èdè Oduduwa, kìí ṣe ìwọ́de
- Ẹ̀yin tẹ́ ń jà fún ẹ̀yà Hausa, Igbo àti Yorùbá, ara yín lẹ̀ ń jà fún - Lamido Sanusi
- Wo àkọsílẹ̀ lórí bí ìpínlẹ̀ kọ̀ọ́kan ní Nàìjíríà ṣe gba ilẹ̀ tí wọ́n wà báyìí
- Buhari, ayẹyẹ kí là ń ṣe gan, ṣé ti ìpànìyàn àbí ìjínigbé? - Aráàlú ń bèèrè
- Lẹ́yìn ọgọ́ta ọdún, ṣé Nàíjíríà le wà ní ìṣọ̀kan bí?
Pasitọ Adeboye ni atunto Naijiria gbọdọ waye laipẹ, ki ipinya ma ṣẹlẹ ni Naijiria.
O gba ijọba ni iyanju lati ri wi pe wọn wo bi wọn ṣe le lo eto oselu lorilẹede Amẹrika ati ni Ilẹ Gẹẹsi lọna ati mu igbelarugẹ ba iṣejọba lorilẹede Naijiria.
'Ti a ba ni aarẹ ati olootu ijọba ni Niajiria, agbara aarẹ a dinku, ti wọn a si pin ohun ini kari ni Niajiria.''
'' Ti a ba ni orilẹede bii 'United States of Nigeria', o ṣeeṣe ki Niajiria dara ju bi o ṣe wa yii lọ''
''Bakan naa ni a nilo Ile Igbimọ awọn lọbalọba, House of Chiefs nitori awọn ni wọn mọ ibi ti bata ti n ta awọn eniyan wọn lẹsẹ julọ''
''Amọ lorilẹede Niajiria ti gbagbe awọn lọbalọba, ohun lo jẹ ki a wa ni ipo ti a wa loni''
Adari ijọ Redeemed Christian Church of God, Pasitọ Enoch Adeboye naa wa fikun wi pe atuntọ Naijiria gbọdọ waye ni kiakia, ki nkan ma ba a bajẹ.












