Ondo election 2020: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní PDP ló ń polongo ní Owo, APC kàn ń kọjá lọ ni

Ẹnikan to fara pa ninu ikọlu

Oríṣun àwòrán, @EyitayoJegedeCO

Lẹyin ikọlu awọn ẹgbẹ oselu APC ati PDP nipinlẹ Ondo, ọpọ awọn eniyan ipinlẹ naa lo ti n foya pe. se eto idibo yoo lọ ni irọwọ rọsẹ nipinlẹ naa bayii?

Gbogbo rukerudo oselu to n gba ọgbẹ lara awọn eeyan lẹnu lọọlọ yii nipinlẹ Ondo ati iporuru ọkan araalu nipa eto idibo to n bọ, lo mu ki BBC Yoruba kan si ẹgbẹ oselu mejeeji to n taporogan ni Ondo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Olabode Richard Olatunde, to jẹ agbenusọ fun ikọ ipolongo ibo Rotimi Akeredolu, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ naa gba pe nnkan to n ṣẹlẹ ni agbo oselu nipinlẹ Ondo n kọni lominu.

Ẹ ba wa pẹtu si PDP lọkan, ko ye kọlu wa lojoojumọ mọ - APC

"A rọ awọn agbofinro lati ba wa pẹtu sawọn ẹgbẹ PDP ninu, bi ikọlu ojoojumọ yii se n lọ n kọni lominu"

Olatunde ni Ikọlu lọtun losi lo n waye si ẹgbẹ oselu APC sugbọn eyi to sẹlẹ lọjọ Isẹgun kii ṣe lori ẹgbẹ oṣelu APC, bikoṣe ikọlu si ilu Owo.

"Bii igba ti PDP kogun wọ ilu ni, ti ẹ ba de Owo bayii, ọpọ ọmọ Owo lo wa ni ile iwosan ti awọn ọkọ si bajẹ loriṣiriṣi."

Ẹnikan to fara pa ninu ikọlu

Oríṣun àwòrán, @EyitayoJegedeCO

O ni iwoye awọn ni pe, nitori oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu APC Rotimi Akeredolu wa lati ilu Owo, ni wọn se n dunkoko mọ wọn, ki wọn maa ba jade wa dibo lọjọ idibo.

Lori ẹsun ti PDP fi kan APC pe, oun lo n ṣe awọn iṣẹ ibi yii, Olatunde ni "yoo dara kí awọn oniroyin beere fọto awọn janduku to di ọna, ootọ ibẹ ni pe, ko si janduku kankan, eke lasan ni. "

"Awọn ọmo ẹgbẹ oselu PDP ti wu gbogbo awọn patako atọka ẹgbẹ APC to wa ni Emure.

Ondo

Oríṣun àwòrán, @newsbreakngr

Ni bayii, wọn ti mu ọkan lara wọn, o si ti wa ni agọ ọlọpaa, awon meje ti wọn ka ibọn mọ lọwọ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP, ni ile ẹjọ ti ni ki wọn gbe wọn lọ si Olokuta."

Asaaju ikọ ipolongo Akeredolu fikun pe alafia ni awọn eniyan ipinlẹ Ondo n fẹ, alafia naa si ni APC n fẹ.

"Ara n fẹ arakunrin Akeredolu nitori awọn iṣẹ idagbasoke to ti ṣe, awọn ara ilu si n fẹ iṣẹ idagbasoke yii, ni wọn yoo ṣe dibo fun Akeredolu, nitori naa, alafia gbọdọ jọba lọdọ APC lasiko idibo."

PDP fẹsun kan APC pe oun lo maa n dena de ikọ ipolongo ibo oun

Ninu ọrọ tirẹ asoju ẹgbẹ Oṣelu People's Democratic Party (PDP), ni ẹgbẹ naa jẹ ẹgbẹ alaafia, amọ ọpọ igba ni APC maa n dena de awọn.

PDP ni awọn fẹ alafia nitori pe ko tọ lati foro yaro, ninu nkan to sẹlẹ lana, ẹgbẹ PDP ko si setan lati maa ja.

PDP ni ọrọ ni awọn yoo maa ba awọn eniyan sọ lati ri daju pe, wọn jade lati dibo nitori nnkan ti ẹgbẹ oselu keji n fẹ ni lati ko ipaya ba àwọn ara ilu, ki wọn maa ba jade dibo.

Iwadii ti bẹrẹ lori ikọlu to waye nilu Owo lọjọ Isẹgun - Ọlọpaa

Lori ọrọ naa, agbẹnusọ ọlọpa ni ipinlẹ Ondo ni, ọga agba ọlọpaa ti bẹrẹ eto iwadii lori iṣẹlẹ to waye ni ilu Owo lana.

O ni nnkan to jẹ kayeefi ni pe, bi PDP se n fọnrere naa, ni APC n pariwo si ara wọn.

Rotimi Akeredolu atawọn miran nibi ipolongo ibo

Oríṣun àwòrán, @RotimiAkeredolu

Sugbọn o ni agọ ọlọpaa to wa ni ayika ibi iṣẹlẹ naa ni, bi awọn ṣe gbo iro ibọn ni awọn bẹ ibudo naa wo, sugbọn nnkan ti wọn fi to awọn leti ni pe, awọn ẹgbẹ oselu PDP lo n ṣe ipolongo nibẹ, ti awọn ẹgbẹ oṣelu APC si n kọja.

O ni títì di asiko yii, ko si ẹni to le sọ nnkan to ṣẹlẹ.

Ju gbogbo rẹ lọ, agbẹnusọ ọlọpaa ni idibo ti yoo waye ni ipinlẹ Ondo yoo lọ ni irọwọrọsẹ nitori pe gbogbo ibi ti o lewu ni awọn ti moju to, lati ri daju pe gbogbo nkan lọ deede.

Àkọlé fídíò, Goitre Patients: Àwọn èèyàn tó ní àrùn gẹ̀gẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìkórira àti ìdẹ́yẹsí ní àwọn ń kojú

O ni ki gbogbo eniyan ni ifọkanbalẹ, ki wọn si jade lọ dibo nitori gbogbo eto lo ti wa nilẹ lati ri pe alafia jọba.

PDP àti APC fi ìbọn dárà l'Ondo, ọ̀pọ̀ èèyan farapa, àìmọye dúkìá ṣòfò

Ondo

Oríṣun àwòrán, @newsbreakngr

Ni bayii to ku nnkan bi ọjọ diẹ ki eto idibo sipo gomina ipinlẹ Ondo waye, awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP ti kọju ija sira wọn lẹẹkan si ni ipinlẹ ọhun.

Awọn agbẹnusọ ẹgbẹ mejeji fidi rẹ mulẹ pe, lootọ ni iṣẹlẹ naa waye, ti wọn si n di ẹbi iṣẹlẹ ọhun ru ara wọn bi ọmọ iya meji, to n wi awijare niwaju iya wọn.

Iṣẹlẹ naa waye ni ilu Ipele ati Owo, nibi ti awọn eeyan kan ti farapa ti awọn ọkọ si bajẹ.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ikọ ipolongo Eyitayo Jegede, tii se oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP fi lede ni, awọn janduku lati inu ẹgbẹ APC lo ṣe ikọlu si awọn.

Asaaju ikọ olupolongo ibo fun oludije PDP, Fasua Kayode ni awọn janduku naa yinbọn lu ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ oun loju ati ni idodo, ninu akọlu ọhun.

Ondo

Oríṣun àwòrán, theprecisionng

Fasua fi kun pe, ṣe ni wọn gbe ọkunrin naa digbadigba lọ si ile iwosan ijọba ipinlẹ Ondo, eyi to wa ni ilu Akure fun itọju pajawiri.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ naa fi kun pe, wọn tun yinbọn lu awọn ọmọ ẹgbẹ PDP meji miran yatọ si ọkunrin ti wọn gbe lọ sile iwosan, bẹẹ ni wọn tun dana sun ọkọ ipolongo wọn ni ilu Oba-Akoko.

O ni "Ṣaaju ki wọn to ṣakọlu si wa, awọn janduku naa ti kọkọ dí ẹnu ọna to wọ ilu Ipele, eyi to jẹ ilu iya oludije labẹ asia ẹgbẹ wa, iyẹn Eyitayo Jegede."

Ẹwẹ, agbẹnusọ ẹgbẹ APC, Olatunde Olabode sọ pe, irọ patapata ni ẹsun ti PDP fi kan ẹgbẹ oun, o ni ẹgbẹ PDP gan lo ṣakọlu si APC.

O ni "N ṣe ni Jegede bẹ awọn ẹru iku rẹ lọwẹ lati kọlu awọn ara ilu Ipele ati Ijebu, ni ijọba ibilẹ Owo."

Olabode tẹsiwaju pe "Inu ibẹru ni awọn eeyan wa wà bayii nitori bi awọn janduku Eyitayo ṣe n yibọn ni ilu Owo."

Agbẹnusọ ẹgbẹ APC naa ni awọn janduku PDP lo da ilu Owo ru, ti wọn si n ṣakọlu si ẹnikẹni to ba wọ aṣo tabi fila Akeredolu tabi eyii to ni akọle ẹgbẹ APC lara.

O pari ọrọ rẹ pe "ko din ni ogun ọkọ ti wọn bajẹ ati ọkẹ aimoye awọn ara ilu ti wọn lu ni ilu bara."

Àkọlé fídíò, Obateru Akinruntan: Wíwá ohun tá jẹ títí láé ló gbé wa kúrò nílé Ife