US Presidential Election Debate 2020: Trump àti Biden bínú sọ̀rọ̀ síra wọn lásìkò ìtàkurọ̀sọ

Oríṣun àwòrán, Reuters
Fun igba akọkọ, itakurọsọ waye lọjọ Isegun laarin awọn oludije aarẹ gbankọ meji, to n du aga akoso ilẹ Amerika mọ ara wọn lọwọ.
Donald Trump to wa latinu ẹgbẹ oselu Republican ati Joe Biden to jẹ oludije fun ẹgbẹ oselu Democratic ni wọn dijọ sọ ohun ti wọn fẹ gbe se fun ilu, ti ọpa asẹ ba tẹeyikeyi lọwọ lẹyin ibo aarẹ naa ti yoo waye losu Kọkanla ọdun 2020.
Itakurọsọ naa to waye ni Cleveland, nipinlẹ Ohio ni omilẹgbẹ eeyan lorilẹede Amẹrika ati ni gbogbo agbaye tẹti gbọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo iye tí ìjọba yóò gbà lọ́wọ́ Laycon gẹ́gẹ́ bí owó orí ẹ̀bùn BBNaija tó jẹ
- Ilé ẹjọ́ gíga ní kí òsìsẹ́ First Bank tẹ́lẹ̀ lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún 98 lórí ẹ̀sùn pé o jí mílíọnù 49 àti $368, 000 níbẹ̀
- Sadiya Umar Farouq ti ní pé ọwọ òun mọ́ lórí N2.67 biliọnù owó oúnjẹ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ICPC ní wọ́n se mọ́kumọ̀ku
- N kò mọ ẹni tó fẹ́ gba ìyàwó mi, àmọ́ wọn máa ń sọ pé ó rẹwà - Mike Bamiloye
- Àríyá yá! Sẹ́nátọ̀ Elisha Abbo kési Naira Marley láti ṣe àríyá fún Leycon tó borí ní BB Naija
- Lẹ́yìn ọgọ́ta ọdún tí Nàíjíríà gba òmìnira, wo ipò tí àṣà àti èdè Yorùbá wà
Amọ fun iyalẹnu ọpọ eeyan, se ni awọn oludije mejeeji naa tutọ si ara wọn loju lasiko itakurọsọ ọhun, paapaa, nigba ti wọn n se agbeyẹwo laasigbo iwa ẹlẹyamẹya to kọja lọ ati arun Coronavirus ti ọwọja rẹ le koko lorilẹede Amẹrika.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọrọ lori arun Coronavirus lasan gba to ogun isẹju, ti wọn si n tako ara wọn lori ipa ti ọwọja itankalẹ arun naa ko lori ọrọ aje orilẹede Amẹrika, abẹrẹ ajẹsara, lilo ibomu-bonu ati ọwọ ti aarẹ Trump fi mu arun naa nibẹrẹ.
A si lee ni ibinu ni awọn mejeeji fi n sọrọ sira wọn lasiko itakurọsọ naa, ti wọn si tun fija pẹẹta ninu ọrọ wọn lori awọn ẹka to nii se pẹlu igbe aye ọmọniyan bii iwa ọdaran, eto ilera, koda, ọrọ ẹbi wọn gan tun da ija silẹ.
Koda, ọrọ naa su ẹni to se atọkun eto itakurọsọ yii, Chris Wallace nitori bi awọn mejeeji se n tako ara wọn, ti ekinni si n tẹnu bọ ọrọ ekeji lasiko to ba n sọrọ lọwọ.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Igba ti ọrọ naa fọnna soju ni akoko ti wọn pe Trump nija pe ko wa bu ẹnu atẹ lu iwa ẹlẹyamẹya lorilẹede Amẹrika, ati bi awọn alawọ funfun se n jẹ gaba lori awọn alawọ dudu.
Asiko yii si ni Trump taku delẹ lati bu ẹnu atẹ lu ijẹgaba naa, sugbọn dipo bẹẹ, se lo kesi ikọ kan to n jẹ Proud Boys, pe ki wọn gbaradi ni sẹpẹ.
Alẹ ariwo, ija ati asọ gbaa si la lee pe akoko itakurọsọ naa fun awọn oludibo ti ko tii pinnu nipa ẹni ti wọn yoo dibo wọn fun.

A si lee ni itakurọsọ naa tubọ poruru ọkan wọn siwaju ni nitori bi Trump se n tako ofin to de eto naa, to si n tutọ si alatako rẹ loju, naa ni Biden n pe ede abuku ati oko ọrọ si Trump .
Akọsilẹ nipa itakurọsọ naa si fihan pe igba mẹtalelaadọrin ni awọn oludije ipo aarẹ mejeeji gba ọrọ mọ ara wọn lẹnu, ninu eto naa to waye fun wakati kan ati aabọ.
Wo bí ìtàkurọ̀sọ láàrin Donald Trump àti Joe Biden yóò ṣe wáyé

Oríṣun àwòrán, @thehill
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, eto idibo sipo Aarẹ orilẹ-ede Amẹrika ti sun mọ etile, awọn oludije sipo Aarẹ ọhun ti n gbaradi fun itakurọsọ ti yoo waye loṣu Kẹsan an ati ni oṣu Kẹwaa ọdun 2020.
Itakurọsọ laarin Aarẹ Donald Trump ati oludije sipo Aarẹ Joe Biden yoo waye lawọn ọjọ wọnyii:
- Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹsan an, ọdun 2020 ni ilu Cleveland, Ohio.
- Ọjọ karundinlogun oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 ni ilu Miami, Florida.
- Ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 ni ilu Nashville, Tennessee.
Bakan naa ni igbakeji Aarẹ Amẹrika Mike Pence ati oludije sipo igbakeji Aarẹ, Kamala Harris, naa yoo maa na tan bi owo ni ọjọ keje, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 ni Salk Lake City, Utah.
Akoko ti itakurọsọ naa yoo maa waye lawọn ọjọ naa ni aago meji si aago mẹta abọ ọsan.
Ohun ti itakurọsọ naa yoo da le lori:
Awọn olujiroro naa yoo sọrọ fun iṣẹju marundinlogun lori awọn akori wọnyi:

Oríṣun àwòrán, Reuters
- Akọsilẹ Aarẹ Trump ati ojugba rẹ, Joe Biden.
- Ile ẹjọ giga orilẹ-ede Amẹrika
- Ajakalẹ arun Coronavirus
- Ifẹhonuhan lori ọrọ ẹlẹyamẹya ati iwa ọdaran laarin ilu
- Ṣiṣe ododo ninu eto idibo
- Eto ọrọ aje
Aarẹ Trump ati Biden yoo ni iṣẹju meji pere lati fesi si ibeere ti awọn eeyan ba ni, ki wọn to bọ si gbagede.
- Aarẹ Trump ṣetán láti yan Amy Coney Barrett sílé ẹjọ́ gíga jùlọ ni America
- Trump kò yẹ láti jẹ́ ààrẹ lásìkò yìí, èèyàn kò le fi mọ̀kàrúrù ṣe ààrẹ - Michelle Obama
- Ibú-owó Bloomberg fẹ́ ta kànùngbọ̀n pẹ̀lú Trump nínú ìbò ààrẹ Amẹrika
- Ṣó yẹ kí akẹ́kọ̀ọ́ tàbùkù mi torí mo ya ‘Tatoo’ sí gbogbo ara?- Olùkọ́
Ireti awọn eeyan nibi itakurọsọ naa:
Ọpọ awọn onimọ nipa eto oṣelu kaakiri agbaye lo ti n sọrọ lori ohun to le ṣẹlẹ nibi ifọrọwerọ awọn oludije ọhun.
Bi awọn kan ṣe n sọ pe Trump yoo fakọyọ nitori kii ṣe ajoji si iru ifọrọwerọ bẹẹ, lawọn miran n sọ pe Biden naa kii ṣe ẹran rirọ.
Ọkan lara awọn alatilẹyin Trump, Mike Harlow sọ fun BBC pe ere ọwọ lasan ni Trump yoo fi Biden ṣe ninu itakurọsọ ọhun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakan naa ni Reem Sabha sọ pe ibẹru oun ni pe, bo tilẹ jẹ pe Biden le e gbiyanju lati ta putu, o ṣeṣe ki awọn eeyan ma dibo fun nitori akitiyann rẹ ninu ijiroro naa..
O ni "Ẹru n ba mi nitori awọn eeyan kan ti n sọ pe Joe Biden ko ni okun to lati jẹ Aarẹ Amẹrika ti awọn miran si n lero pe o ti n dagba ju ẹni ti yoo di ipo Aarẹ mu."
Gẹgẹ bi awọn onwoye ohun to n lọ nipa eto oṣelu Amẹrika ṣe so, itakurọsọ awọn oludije ni ipa ninu ipinu awọn oludibo lori ẹni ti wọn yoo dibo wọn fun.
Boya Trump ni yoo tẹsiwaju gẹgẹ Aarẹ lẹyin idibo naa ni tabi Biden yoo yẹ aga m,ọ nidii, gbogbo ẹ wa lọwọ awọn oludibo.












