Nigeria @ 60: Wo àwọn àdínkù tó ti dé bá àṣà àti èdè Yoruba

AJ

Oríṣun àwòrán, @ogundamisi

Iran Yoruba jẹ ọkan gboogi lara awọn ẹya to laami laaka, to si tun tobi julọ ni Naijiria.

Iwọ Oorun ilẹ Afrika ni ẹya Yoruba fi ṣe ibugbe, bo tilẹ jẹ Naijiria ni Yoruba pọ si ju, ṣugbọn awọn ọmọ Yoruba tun wa ni Benin, Togo ati lawọn agbegbe kan ni orilẹ-ede Ghana.

Gẹgẹ bi awọn onimọ ṣe sọ, ko din ni miliọnu mẹtadinlaadọta awọn Yoruba to wa kaakiri agbaye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ohun kan pataki to ya ẹya Yoruba sọtọ laarin awọn ẹya to ku lagbaye, paapaa ni Naijiria, ni ibọwọ f'agba, ede, aṣa, aṣọ wiwọ, ounjẹ, igbeyawo, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àkọlé fídíò, Obateru Akinruntan: Wíwá ohun tá jẹ títí láé ló gbé wa kúrò nílé Ife

Ṣugbọn lati nnkan bi ọgọta ọdun sẹyin ti Naijiria ti gba ominira lọwọ awọn oyinbo alawọ funfun, n ṣe lo da bi pe nnkan wọnyi ko ri bo ṣe wa tẹlẹ nigba aye awọn baba nla wa.

Wo diẹ lara awọn aṣa ati iṣe Yoruba, to ti n dẹnukọlẹ lati nnkan bi ọgọta ọdun sẹyin.

Ìkíni nilana adayeba:

Gbogbo eeyan lo mọ kaakiri agbaye pe, ṣe ni ọmọde maa n dọbalẹ ki agba, to ba jẹ ọkunrin, ti obinrin a si kunlẹ pẹlu orunkun mejeji, lati ki agbalagba nilẹ Yoruba.

Iyawo Ambode n kunlẹ ki Buhari

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Ṣugbọn o jọ bi ẹni pe ko ri bẹẹ mọ laye ode oni, n ṣe lo ba dabi pe awọn eeyan ti n yi ikunlẹ tabi idọbalẹ pada si ibọnilọwọ.

Awọn agba miran kii tilẹ reti ki awọn ọdọkunrin dọbalẹ ki awọn mọ, bẹẹ ni awọn obi ko kọ awọn ọmọ wọn lati dọbalẹ tabi kunlẹ ki wọn kaarọ mọ debi pe wọn yoo ki oriki wọn.

Se ni awọn ọdọkunrin aye ode oni maa n gbiyanju lati bọ awọn agbalagba lọwọ, koda a fi bi ẹni pe afin ọba nikan ni awọn eeyan ti n naa tan bayii, eyii ti ko yẹ ko ri bẹẹ.

Oúnjẹ:

Lara awọn ounjẹ ilẹ Yoruba to lamilaaka ni iyan, amala, adalu, ikọkọkọrẹ, ti awọn ọbẹ bii gbẹgiri ati ewedu, ẹfọ riro ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Laye ode oni, ọpọ ọmọ Yoruba, papa awọn ọdọ ni ko mọ bi wọn ṣe n se awọn ounjẹ wọnyii, ẹlomiran ko tilẹ jẹ wọn ri.

Amala ati ewedu

Oríṣun àwòrán, @Quora

Ootọ ni pe awọn ounjẹ kan jẹ ti awọn ilu ti o yatọ sira wọn, ṣugbọn pupọ ninu awọn ọmọ Yoruba ode oni lo nifẹ ounjẹ oyinbo ju ilẹ wọn lọ.

Abajọ ti wọn ṣe n pe awọn ọmọ aye ode oni ni awọn ọmọ iran "indomie."

Ẹsin abalaye:

Laye atijọ, ẹsin abalaye, ti ọpọ mọ si ẹsin ibilẹ ni awọn Yoruba maa n se, to fi mọ awọn ọdun bii, Osun-Oṣogbo, Ẹyọ, Ogun, Ọdun Ọlọjọ, ọdun Ijẹṣu, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Gbogbo awọn ọdun wọnyii ni adinku ti de ba ju ti atẹyinwa lọ nitori ẹsin igbagbọ, ẹsin Musulumi ati igbalode.

Yoruba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Adinku ti de ba iye awọn ẹlẹsin abalaye nitori igbagbọ awọn eeyan pe Satani ni wọn n sin.

Igbeyawo:

Yatọ si bi wọn ṣe n ṣe ayẹyẹ igbeyawo laye atijọ, bi awọn eeyan ṣe n gbe iyawo sile ti yatọ gbaa si ti aye atijọ.

Laye ọjọhun, baba ọkọ ni yoo lọ ba baba iyawo lati beere fun aya fun ọmọ rẹ, awọn ọmọ naa si le jẹ majesin nigba naa, ṣugbọn ko ni nnkan se.

Ẹru idana igbeyawo

Oríṣun àwòrán, Wojuola

Laye ode oni oju opo ikansiraẹni bii Instagram ati Facebook ni ọpọ ti n ri ọkọ tabi aya, ọpọ a si ti fun ara wọn loyun tan ki awọn obi wọn to mọ ẹni ti wọn n ba ṣere ifẹ.

Ede:

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn oyinbo alawọ funfun lo ti tẹkọ leti wa si Naijiria lati kọ nipa ede, aṣa ati ẹsin abalaye Yoruba, pupọ ninu awọn awọn ọmọ Yoruba ni ko le e sọ ede naa.

Awọn onimọ kan ti di ẹbi iṣẹlẹ yii ru awọn obi to n sọ ede Gẹẹsi si awọn ọmọ wọn ninu ile dipo ede abinibi wọn.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC: Kí ní ìtúmọ̀ Sílébù àti àmi ohun tó ń fún ni?

Eyii to buru ju nibẹ ni bi awọn ti ko kuro ni Naijiria ri, ko se le e sọ ede Yoruba, bẹẹ ede Gẹẹsi ti wọn n sọ naa ko dan mọran lẹnu wọn.

Nibo la n lọ?

Awọn eeyan kan ti n beere ohun ti yoo ṣelẹ si ede ati aṣa Yoruba, ti yoo ba fi pe ọgọrun ọdun ti Naijiria gba ominira lọwọ oyinbo alawọ funfun.

Ti iran Yoruba ko ba fẹ ki ede ati aṣa wọn parun, ojuse gbogbo wa ni!