Kunle Afolayan: Òun àti Mike Ezuruonye ń gbéná wojú ara wọn lórí ayélujára

Oríṣun àwòrán, Instagram
Nnkan ko rọgbọ laarin awọn eekan meji lagbo ere sinima lorilẹede Naijiria, Mike Ezuruonye ati Kunle Afọlayan lasiko yii.
Awọn mejeeji yii lo n kọlu ara wọn, ti wọn si n tahun si ara wọn lori ayelujara lori awọn atẹjade kan ti awọn mejeeji gbe jade loju opo ayelujara wọn.
Gbajugbaja oṣere sinima ede oyinbo ati igbo ni Naijiria, Mike Ezuruonye lo bọ sori ayelujara lati ko bilala ọrọ fun Kunle Afọnlayan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo àwọn olóríire tó borí nílé BB Naija sẹ́yìn àti iye òjò owó tó rọ̀ fún wọn
- Àwọn afọbajẹ wọ́ Oluwo relé ẹjọ́, ìjọba Osun kò tíì fọùn
- Ẹ gbà mí, Nàíjíríà gbá mi lórí àyẹ̀wò Covid-19 - Iyabo Ojo figbe ta
- A ti ja aráàlú kulẹ̀, ta bá pè wọ́n fún ìwọ́de, wọn kò ní jẹ́ wa mọ́ - NLC Eko
- Àlàyé rèé lórí ìdí tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ kò fi ní bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì mọ́ lónìí
- Ẹgbẹ́ òkùnkùn yìnbọn lu ọmọ kan ní ikùn lásìkò ìdárò akẹẹgbẹ́ wọn
- Laycon ni ọmọ ológo tó jáwé olúborí ní ètò BBNaija season 5 'Lockdown'
- Kí ló wà láàrin Olorì Badra àti Bobrisky, tí ọ̀rọ̀ wọn fi wọ̀?
Eyi ko sẹyin bo ṣe ni o gbe atẹjade ori ayelujara kan ti arabinrin kan fi soju opo rẹ jade si gbangba.
Arabinrin naa, ti orukọ rẹ lori ayelujara njẹ Mwandu Chibwe kọ iwe kan si Kunle Afọlayan loju opo instagram rẹ, nibi to ti n fi ẹsun kan Mike.
O ni onijibiti ẹda gbaa ni ati pe o ti lu ọpọlọpọ awọn obinrin ni jibiti, bẹẹ lo tun pe osere tiata naa ni gbajuẹ.
Ọrọ yii ni Kunle Afọlayan ba gbe si ita gbangba loju opo Instagram rẹ, eyi to bi Mike ninu.
Ninu esi rẹ ti oun pẹlu gbe soju opo ayelujara Instagram rẹ, Mike Ezuruonye laali Kunle Afọlayan pe, ohun to ṣe ku diẹ kaa to.
O ni Kunle Afọlayan ti n fihan ni ọpọlọpọ igba pe, oun korira ẹya Igbo ati pe, ọjọ idẹyẹsi rẹ si awọn ẹya naa ti pẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Ninu atẹjade ori ayelujara naa, Mike ni "ọwọ kekere ti mo ni fun ẹ ti parẹ..."
O ni ko yẹ ki Kunle Afọlayan maa ṣe bi ẹni ti ko mọ pe awọn eeyan kan a maa fi orukọ awọn eekan oṣere lu jibiti ati pe, ajọ EFCC ti ran awọn kan to fi orukọ oun lọ sẹwọn.
Amọ ṣa, Kunle Afọlayan ti ranṣẹ pada loju opo Instagram pe, oun ko mọọmọ kọ ọrọ naa ati pe, kii ṣe bi oun ṣe lero lo ṣe gbaa.
Kunle Afọlayan ṣalaye pe, lẹsẹkẹsẹ loun ti jẹ ko di mimọ fun arabinrin naa pe "Ẹ gba mi o, ewo n temi"

Bakan naa lo fi kun un pe, oun ko korira ẹya igbo tabi dẹyẹsi wọn, bi o ti wulẹ o mọ.
"Mi o mọ ohun to lee fa aṣigbọ ati aṣitumọ yii. Lootọ gbogbo aye lo mọ pe gbogbo nnkan ti aṣa ati iṣe Yoruba to jẹ temi duro fun ni mo n gbe ga.
Sibẹ mi o ṣai ni ibaṣepọ pẹlu awọn eeyan ẹya miran, paapaa julọ, awọn eya Igbo nitori naa, kii ṣe ohun to bojumu fun emi ati Mike Ezuruonye lati wa sọ ọrọ naa di ti ẹlẹya-mẹya.














