BBNaija 2020 Winner: Laycon ti gba sọ̀wédowó, ilé fúláàtì àti àwọn nkan míràn

Laycon n gba sọwedowo

Oríṣun àwòrán, Big Brother Naija / Twitter

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 12

Oludari Agba fun ileeṣẹ MultiChoice Nigeria, to jẹ ileeṣẹ to ṣe agbatẹru eto Big Brother Naija, John Ugbe, ti sọ pe, BBNaija ti ọdun 2020 lo ni idibo to ti i pọju lọ.

O sọ eyi nibi ipade oniroyin kan, ti wọn ti pin ẹbun fun awọn to jẹ lori eto naa, eyi to wa sopin lọjọ Aiku.

Ọgbẹni Ugbe ṣalaye pe, milọnu lọna ẹẹdẹgbẹrun ni awọn eeyan di lapapọ fun awọn olukopa lori eto naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa lo ṣalaye pe, biliọnu mẹta aabọ Naira ni wọn fi gbọ bukaata eto Big Brother Naija Lockdown 2020.

Laycon n gba kọkọrọ ile tuntun

Oríṣun àwòrán, Big Brother Naija / Twitter

Ko tan sibẹ o, nibi ipade oniroyin naa ni wọn ti fun Olamilekan Agbeleshebioba 'Laycon', ni sọwedowo ọgbọn miliọnu Naira, ati awọn ẹbun miran to jẹ, gẹgẹ bi olubori ninu eto naa.

Yatọ si eyi, wọn tun kede apapọ iye ti olukopa kọọkan jẹ.

Apapọ iye ti awọn olukopa lori eto BBNaija jẹ

Oríṣun àwòrán, Big Brother Naija / Twitter

Laycon yóò san owó orí tó súnmọ́ N8.5m nínú ẹ̀bùn BBNaija season rẹ̀

Lẹyin ti olukopa eto agbelewo BBNaija, Lekan Agbeleshebiọba ti ọpọlọpọ mọ si Laycon bori pẹlu ẹbun ti akojọpọ iye rẹ to miliọnu marundinlaadọrun naira, N85m ni okiki rẹ ti kan kalenkako ti ọpọlọpọ si ti n kii ku oriire.

Amọṣa, ikini ku oriire kan wa ti o ti n mu ki awọn ọmọ naijiria aatawọn ololufẹ Laycon kaakiri agbaye o maa pariwo 'ee ṣe' 'wọn tun de o' ati bẹẹbẹẹ lọ. Ikini naa ni ti ajọ agbowo ori ni ipinlẹ Eko to kii pe o ku oriire naa ṣugbọn ko maa gbagbe lati san owo ori rẹ bi o ti tọ lọdun 2021.

Eyi mu ki ọpọ awọn ololufẹ Laycon o gbohun soke pe ṣile kan ko gbọdọ re jẹ ninu owo aarẹ ẹgbẹ ICON naa.

Ibeere ti ọpọ wa n beere ni pe, ṣebi ẹbun owo ni wọn fun Laycon, o ṣe tun wa di ogun oni owo ori sisan.

Nigba ti BBC News Yoruba kan si alagba Mustapha Hussein Ọlanrewaju to jẹ akọṣẹmọsẹ iṣuna ati isiro owo, o ni ko souhun to buru ninu ohun ti ajọ naa sọ ati pe labẹ ofin, Laycon gbọdọ san owo ori lori ẹbun tẹtẹ oriire to jẹ naa.

O ni labẹ ofin owo ori sisan pin si meji. Owo ori sisan lori owo ati owo ori sisan lori dukia.

O ni Laycon yoo san owo ori lori ẹbun owo to jẹ ati awọn dukia to jẹ bii mọto, ile atawọn dukia miran ṣugbọn ko sohun to kan an pẹlu owo ori lori awọn irinajo afẹ silẹ okeere gbogbo ti wọn yan fun diẹ.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC: Kí ní ìtúmọ̀ Sílébù àti àmi ohun tó ń fún ni?

O ni gbogbo iye owo yii ni wọn yoo ṣi pọ eyi ti wọn pe ni "witholding tax" lede oyinbo. O ni owo ori ti yoo san da lori awọn ohun ti ko ṣiṣẹ fun, iyẹn "unearned tax" lede oyinbo.

Ida mẹwaa apapọ owo iye ẹbun to jẹ lapapọ ni yoo san gẹgẹ bi owo ori bayii. Ni ti ọrs Laycon ti apapọ owo ohun to jẹ gẹgẹ bi ẹbun jẹ miliọnu marundinlaadọrun naira, N85m o ṣeeṣe ki owo ori ti Laycon yoo san o maa fara pẹ miliọnu mẹjọ abọ naira.

Awọn onimọ nipa iṣuna fi kun un pe kii ṣe ọwọ Laycon ni ijọba ipinlẹ to ba kan yoo ti gba owo ori yii bi ko ṣe latọwọ ileeṣẹ to ṣeto idije agbelewo BBNaija naa.

Idi niyi ti wọn fi n pee ni owo ori alayọọlẹ, iyẹn Witholding tax nitori ileeṣẹ naa ni yoo ti yọ owo naa ki wọn to ko iyoku le Laycon lọwọ lẹyin eto naa.

Laycon ni ọmọ ológo tó jáwé olúborí ní ètò BBNaija season 5 'Lockdown'

Lekan

Oríṣun àwòrán, BBNaija/twitter

Olamilekan Agbelesebiọba 'Laycon', lo jawe olubori lori eto ori amohunmaworan, BBNaija season 5 Lockdown.

Ọjọ mọkanlelaalọgọrin ni awọn olukopa fi wa ninu ile Big Brother, nibi ti wọn ti kopa ninu oriṣiriṣi idije, faaji, ariya, ati bẹẹbẹ lọ.

Oludije ogun lo bẹrẹ idije naa, ṣugbọn awọn marun-un, Laycon, Vee, Dorathy, Nengi, ati Neo, lo gbẹyin sori eto.

Bayii ni awọn eeyan ṣe dibo to mu ki Laycon jawe olubori.

Oríṣun àwòrán, BBNaija

Àkọlé àwòrán, Bayii ni awọn eeyan ṣe dibo to mu ki Laycon jawe olubori.

Lopin gbogbo ere, ibo ti awọn ololufẹ eto naa di ja Vee, Nengi, Neo ati Dorathy.

Awọn nkan to yẹ ki o mọ nipa Laycon

Ilu Eko ni wọn bi Leycon si.

Ọmọ ilu Bajuwen, ni ijọba ibilẹ Odẹda, ni ipinlẹ Ogun ni Lekan.

O kawe gba oye imọ ijinlẹ akọkọ ninu Philosophy, ni Fasiti ilu Eko lọdun 2016.

Nigba to wa ni fasiti, o ṣiṣẹ gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ fun Ọga Agba ileeọẹ kan nilu Eko.

Laycon

Oríṣun àwòrán, Twitter

Lẹyin to kawe gboye tan, o ṣiṣẹ gẹgẹ bi olutaja fun ileeṣẹ Bestman Games, Ikoyi, nilu Eko bakan naa.

Lẹyin naa lo darapọ mọ ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko to wa fun eto iroyin, nibi to ti di amugbalẹgbẹ fun igbakeji ọga agba.

Lati kekere ni Laycon ti n kọrin. Ṣugbọn lọdun 2019, o darapọ mọ ileeṣẹ to n gbe orin jade, Fierce Nation. Nibẹ lo ti gbe awo orin kan to pe akọle rẹ ni 'Laycon'.

O kọ ọkan lara awọn orin inu awo naa pẹlu Reminisce ati Chinko-Ekun.

Awọn nkan ti Laycon to jawe olubori yoo ko lọ sile

•Dubai trip for 2 Irinajo silu Dubai fun eeyan meji

•Ile fulaati oni yaara ibusun meji

•Ọgbọn miliọnu Naira

•Irinajo lati lọ wo aṣekagba idije Champions League, ohun mimu Pepesi fun ọdun kan, ati firiiji Pepsi kan

•Foonu OPPO RENO

•Ọkọ jiipu Innoson G40

•Irinajo si ilu Dublin

•Tẹlifisan ati firiji nla

•Ati awọn nkan miran bi i indomie ati ipanu 'chinchin'

Wo bi àṣekágbá ètò Big Brother Naija Lockdown ṣe lọ

Ni deede aago meje alẹ ni eto naa, ti Ebuka Obi-Uchendu, ṣe atọkun rẹ.

Fireboy lo kọkọ forin da gbogob eeyan lara ya lori eto naa.

Lẹyin ti Big Brother ki awọn olukopa marun to kẹhin si ori eto naa, ni Ebuka kede pe Vee ti ja kuro lori eto naa.

Vee

Oríṣun àwòrán, BIG BROTHER NAIJA

Ẹni ọdun mẹtalologun ni Victoria Adeyeye, to jẹ akọrin. Ilu Eko lo fi ṣe ibugbe, bo tilẹ jẹ pe ilu London ni ni wọn bi si, to si ti dagba.

Ọdun kan sẹyin lo ko wa si ipinlẹ Eko, lati bẹrẹ iṣẹ orin kikọ,

Lasiko ti Ebuka fi ọrọ wa lẹnu wo lori irinajo ifẹ oun ati Neo, Vee sọ pe nigba ti awọn ba pada si aarin ilu, ni wọn yoo mọ ibi ti ori n gbe ẹsẹ lọ fun wọn.

Lẹyin naa ni gbajugbaja akọrin, Rema naa bọ si ori itage, to si kọ awọn orin rẹ, Beamer ati woman.

Neo

Oríṣun àwòrán, Instagram/Neo

Neo ni olukopa keji to ja kuro lori eto naa l'alẹ aṣekagba.

Oun paapa sọ pe opin ko ti i deba irinajo ifẹ oun ati Vee, ṣugbọn oun kii ṣe ọkunrin to sare ma n mu ọrọ ifẹ ni kole-kole.

Ninu ọrọ to sọ, Neo sọ pe oun ti ṣetan lati jaramọ eyikeyi iṣẹ aje to ba yọju.

Bi Neo ṣe kuro lori eto naa, ni Fireboy tun pada sori itage lati kọ orin fun igbadun awọn olukopa, ati awọn ololufẹ eto naa.

Nengi

Oríṣun àwòrán, BIG BROTHER NAIJA

Nengi ni olukopa kẹta to ja kuro lori eto naa ni aṣekagba. Eyi to mu ko ku Laycon ati Dorathy.

Nengi sọ pe oun ti n fura pe oun yoo já.

O sọ pe okoowo oun ni oun yoo gbajumọ lẹyin eto BBNaija.

Arinrin oge 'model' ni Nengi.

Lẹyin ti Nengi kuro ni Big Brother kede asiko ti to fun Dorathy ati Laycon lati fi ile naa silẹ, lẹyin aadọrin ọjọ.

Bayii ni Laycon ati Dorathy, #se kuro ninu ile Big Brother lẹyin aadọrin ọjọ.

Oríṣun àwòrán, BBNaija/Twitter

Àkọlé àwòrán, Bayii ni Laycon ati Dorathy, #se kuro ninu ile Big Brother lẹyin aadọrin ọjọ.

Davido ati Mayorkun naa fi orin da awọn eeyan laraya lori asẹkagba eto naa.

Davido ati Mayorkun

Oríṣun àwòrán, BBnaija

Iyalẹnu si ni eyi jẹ, nitori pe awọn alakoso eto BBNaija ko kede tẹlẹ pe awọn gbajugbaja olorin mejeeji yoo kọrin ni aṣekagba.

Wo iye àwọn tó ní ìbálòpọ̀ lórí ètò BBNaija 2020 tó n parí lónìí

Eica ati Kiddwaya

Oríṣun àwòrán, @BBNaija/twitter

Oni lonii jẹ, ẹni a bẹ lọwẹ. Lonii la o mọ ẹni ti yoo gbade eto agbelewo ile Ẹlẹgbọn Agba, BBNaija 2020.

Ṣugbọn awọn iṣẹlẹ kan to jẹ manigbagbe waye lori eto naa.

Lara wọn ni bi awọn olukopa kan ṣe ṣe ere ifẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Praise ati Ka3na lo kọkọ jẹ jẹ eso ifẹ.

Praise ati Ka3na

Oríṣun àwòrán, @official_ka3na/@itz__praise

Ọjọ Ẹti kan ni eyi waye lẹyin ariya alẹ ti wọn ṣe.

Ninu fidio to gba ori ayelujara, abẹ aṣọ ibora ni awọn mejeeji naa wa, to si jẹ pe bi ara wọn ṣe n lọ si ọtun, ati osi, lo fihan pe 'wọn n dan nkan wo'.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Iyalẹnu lo jẹ fun awọn ololufẹ wọn, nitori pe ko si adehun ifẹ laarin awọn mejeeji.

Àkọlé fídíò, Yemen Water Child: Ọmọdé 44 ni Sọ́jà pa, tí 100 míì sì kú látọwọ́ ohun ìjà olóró

Ọpọ eeyan to si ti n ro pe 'tọkọtaya' naa yoo tun pada da wọn laraya ti ni ijakulẹ bayii, nitori pe awọn mejeeji ti ja kuro ninu eto naa.

Ariwo Erica ati Kiddwaya ni awọn eeyan tun npa lori ayelujara .

Eyi ko ṣẹyin fidio kan ti awọn ololufẹ eto naa fi sita loru ọjọ kan, to si ṣafihan awọn 'ololufẹ' mejeeji nibi ti wọn ti n 'fun ara wọn ni eso ifẹ jẹ'.

Erica ati Kiddwaya

Oríṣun àwòrán, Twitter

Lẹyin eto ti wọn ti le Lilo ati Ka3na pada sile lalẹ ọjọ Aiku, ni iṣẹlẹ naa waye.

Ori aga ijoko ni awọn mejeeji ti kọkọ bẹrẹ, ti wọn si n fi ọwọ pa ara wọn lara. Koda, idi Erica ṣi silẹ ya-n-ya, ti ọwọ Kidd si bu idi naa so.

Lẹyin naa, ti gbogbo awọn olukopa to wa nile wọle lọ ọ sun, ni awọn mejeeji jọ wa pọ lori ibusun kan naa.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Bi awọn kan ṣe n sọ pe niṣe ni Kidd n ki ika si oju ara Erica, ni awọn kan sọ pe ibalopọ taara ni wọn n ni.

Ko tan sibẹ o, ninu fidio naa lo ti han bi Erica paapa n ke ha, yu, bi ẹni n gbadun nkan to dun.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ láàrin Ozo àti Nengi olórí àti igbákejì nílé BBNaija rèé

Awọn ololufẹ eto ile ẹlẹgbọn agba, BBNaija tun sọrọ lori ohun to ṣẹlẹ laarin olori ile, Ozo ati igbakeji rẹ, Nengi lalẹ Ọjọru mọju Ọjọbọ kan.

Awọn kan tiẹ n binu tẹlẹ pe BBNaija ko ri fọnran ohun to ṣẹlẹ laarin Ozo ati Nengi wo.

Ọpọ lo fẹ ri bawọn mejeeji ti jọ sun pọ ninu ile Ozo to jẹ olori ile.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Ṣugbọn ẹrọ ayaworan kamẹra ko ṣafihan ohun to n lọ laarin awọn mejeeji.

Amọ, laarọ Ọjọbọ lawọn eeyan ri fidio kan ninu eyi ti Nengi ti gbagbe irọri rẹ to fi ṣami aye rẹ lori ibusun pẹlu Ozo.

Ki Ozo to di olori ile ati Nengi di igbakeji, awọn mejeeji ko tii jọ sun papọ ri lori ibusun kan naa, bi o tilẹ jẹ pe wọn sun mọ ara wọn.

Ṣugbọn ohun to jẹ ki ọpọ ololufẹ eto BBNaija nipa awọn mejeeji ni pe Ozo nífẹẹ Nengi, amọ Nẹngi ni oun ko fẹ ni ololufẹ ninu ile ẹlẹgbọn agba BBNaija.

Ọrọ ibalopọ ko ṣẹṣẹ ma a waye laarin awọn olukopa ninu eto naa lati igba to ti bẹrẹ.

BBNaija 2020: Ta ni ₦85m tọ́ sí láàrin Laycon, Dorathy, Nengi, Vee àti Neo?

Nengi, Laycon, Vee, Neo ati Dorathy

Oríṣun àwòrán, Instagram/BBNaija

Oni lonii jẹ, ẹni a bẹ lọwẹ. Lonii la o mọ ẹni ti yoo gbade eto agbelewo ile Ẹlẹgbọn Agba, BBNaija 2020.

Obitibiti owo, miliọnu marunlelọgọrin naira(N85m) ni ẹni to ba jawe olubori ninu awọn oludije marun un to ku, Laycon, Nengi, Vee, Neo ati Dorathy yoo gba lọle.

Atọkun eto naa, Ebuka Obi-Uchendu ti sọ pe, ẹni ti ibo rẹ ba pọju ninu awọn marun un to ku, ni yoo gbade BBNaija ti ọdun yii.

Eto BBNaija ti ọdun yii lami laaka, o kun fun oriṣiiriṣii iṣẹlẹ eyi to ti sọ ọpọ awọn oludije di ilumọọka.

Yatọ si awọn marun un to ku ninu ile naa, awọn ti wọn ti yọ kuro gan an ti di eeyan ti ọpọlọpọ n tẹle loju opo ayelujara wọn.

Awọn olukopa naa ti n jẹ ẹbun owo ati awọn ẹbun nla miran ṣaaju asiko yii.

Awọn olukopa marun-un to kẹhin sori eto BBNaija season 5

Oríṣun àwòrán, BIG BROTHER NAIJA

Àkọlé àwòrán, Awọn olukopa marun-un to kẹhin sori eto BBNaija season 5, Laycon, Nengi, Dorathy, Neo àti Vee

Awọn kan lara wọn ti jẹ ẹbun irinajo igbafẹ ati jijẹ aṣoju fun awọn ileeṣẹ to ṣe onigbọwọ eto naa.

Awọn kan lara wọn si ti jẹ to ẹbun owo miliọnu marun Naira.

Nitori naa ni BBC Yoruba fi ṣe alaye lẹkunrẹrẹ nipa ẹni to ṣeeṣe ko gbade BBNaija ti ọdun yii.

Laycon:

Laycon

Oríṣun àwòrán, Instagram/Laycon

Olamilekan ''Laycon'' Agbeleshe lo ṣeeṣe ko gbade eto BBNaija ti ọdun yii, nitori ogunlọgọ eeyan to n fifẹ han si, ti wọn si n dibo fun ni gbogbo igba.

Lati ibẹrẹ eto naa ni ọpọ awọn ololufẹ eto BBNaija ti fẹran Laycon to fi di oni ti eto naa yoo pari.

Lootọọ ni pe awọn eeyan ko mọ pe o lẹbun orin kikọ ko to de ile Ẹlẹgbọn Agba, ṣugbọn lẹyin to wọle BBNaija tan, lawọn ilumọọka olorin takasufe ati gbajugbaja oṣere bii Tunde Ednut, Reminince, Yinka Ayefele, Nkechi Blessing n satilẹyin fun.

Awọn mii to tun n gbaruku ti Laycon ni Lateef Adedimeji, Olaniyi "Sanyeri" Afonja, Ufuoma McDermott, Broda Shaggy ati Lekan KingKong.

Awọn eeyan to le ni miliọnu kan ati igba (1.2m) lo n tẹ le Laycon loju opo Instagram rẹ.

Owo to ti jẹ ti le ni miliọnu marun-un Naira, N5,031,000.

Bakan naa lo ti jẹ ẹbun lati polowo ọja, eroja iṣaraloge, ounjẹ ọfẹ, ohun elo inu ile, aṣoju ileeṣẹ, irinajo si Scotland, ati ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin.

Dorathy:

Dorathy

Oríṣun àwòrán, Instagram/Dorathy

Dorathy Bachor, to jẹ gbaju-gbaja lori eto naa, ti ọpọ si sọ pe o konimọra, lo ṣeeṣe ko gba ipo keji nitori bi awọn eeyan ṣe n dibo fun un.

Ẹgbẹ awọn ololufẹ rẹ ''DExplora'' n dibo fun Dorathy witi-witi, koda awọn ni igi lẹyin ọgba rẹ ti ko ti fi di ero ile.

Ọpọ igba lo ti wa lara awọn oludije ti BBNaijia fẹ le lọle, ṣugbọn awọn olukopa bii Prince ati Ozo lo lọ dipo rẹ.

Eeyan ẹgbẹrun un lọna ọtalelẹgbẹrin o din mẹwa (850,000) lo n tẹle e loju opo Instagram rẹ.

Ẹwẹ, Dorathy ti jẹ ẹbun owo to ku diẹ ko to miliọnu mẹrin Naira, N3,926,000.

Ko tan sibẹ o, o tun jẹ ẹbun foonu, ọda, eroja fun inu ile, ounjẹ ọfẹ, aṣoju ileeṣẹ, ati ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin.

Nengi:

Instagram/Nengi

Oríṣun àwòrán, Instagram/Nengi

Rebecca "Nengi'' Hampson lo ṣeeṣe ko gba ipo kẹta lonii bi eto BBNaija ọdun 2020 yoo ti wa si ipari.

Eeyan to din diẹ ni miliọnu kan (948,000) lo n tẹle e loju opo Instagram rẹ, ti wọn si wa lara awọn ti wọn n dibo fun un ni gbogbo igba.

Nengi yoo figa gbaga pẹlu Dorathy fun ipo keji, ṣugbọn Ozo to fi ifẹ han si Nengi nigba to si wa nile BBNaija ti rọ awọn ololufẹ rẹ, lati dibo fun Nengi.

Nengi si ti gba ẹbun owo to le ni miliọnu marun-un, N5,328,000 tẹlẹ lori eto.

Yatọ si eyi, o tun ti jẹ ẹbun ounjẹ fun oṣu mẹta, eroja fun inu ile fun ọdun kan, paali eroja iṣaraloge, ọ̀dà, irinajo si ilu Abuja ati orilẹ-ede Scotland, ati Dubai fun ayẹyẹ One Africa Music Fest.

Nengi tun jẹ owo Bitcoin to to ẹẹdẹgblta Dọla, ati aṣoju ileeṣẹ.

Vee:

Vee

Oríṣun àwòrán, Instagram/vee

Victoria "Vee" Adeyele lo kan bayii. Oun lo ṣee ṣe ko gba ipo kẹrin lonii ninu awọn oludije marun un to ku nile Ẹlẹgbọn Agba.

Ọpọ awọn ololufẹ BBNaija lo ti fẹran Vee papaa julọ nitori ibaṣepọ rẹ pẹlu Laycon ninu ile.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ololufẹ rẹ ko pọ to bẹẹ, ori lo gbe de ipele to kẹyin nile Ẹlẹgbọn Agba.

Ẹgbẹrun un lọna ẹẹdẹgbẹta eeyan lo n tẹle Vee loju opo Instagram rẹ.

Oun naa ti jẹ ẹbun miliọnu meji aabọ Naira.

O tun jẹ ẹbun ohun elo inu ile, ounjẹ ọfẹ, aṣoju ileeṣẹ, irinajo si orilẹ-ede Scotland, ati ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin.

Neo:

Neo

Oríṣun àwòrán, Instagram/Neo

Neo Akpofure ni o ṣeeṣe ki o gba ipo to kẹyin ni BBNaija ti ọdun 2020 yii.

Neo naa dabi Vee ti ori ko yọ lawọn igba to ti wa lara awọn ti BBNaija fẹ le lọ sile.

Eeyan bi ẹgbẹrun lọna irinwo le mẹjọ, lo n tẹle Neo loju opo Instagram rẹ.

Oun naa ti jẹ ẹbun owo to le ni miliọnu mẹta Naira, N3,572,000.

Bakan naa lo jẹ ẹbun ohun elo inu ile, ounjẹ ọfẹ, aṣoju ileeṣẹ, ati ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin.

Atupalẹ ẹbun fun ẹni to ba gbade BBNaija ọdun yii ni ọgbọn miliọnu naira(N30m), ile pẹtẹẹsi oni yara meji, ọkọ SUV kan, irinajo afẹ si ilu Dublin lorilẹede Scotland atawọn ọpọlọpọ ohun elo ninu ile

Wo nkan ti awọn olukopa to ti já kuro lori eto naa jẹ:

Triky tee

  • O jẹ N3,359,000
  • Ohun elo inu ile
  • Irinajo silu Dubai fun ayẹyẹ One Africa Music Fest
  • Ọ̀dà
  • Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin

Ozo

  • O jẹ N2,780,000 gẹgẹ bi ẹbun owo
  • Ọkọ ayọkẹlẹ
  • Irinajo silu Abuja
  • Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin
  • Irinajo silu Dubai fun ayẹyẹ One Africa Music Fest

Prince

  • Oun naa jẹ N2,570,000
  • Ohun elo inu ile
  • Irinajo silu Abuja
  • Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin
  • Irinajo silu Dubai fun ayẹyẹ One Africa Music Fest

Kiddwaya

  • O jẹ ẹbun owo: N1,720,000
  • Foonu tuntun
  • Ọ̀dà
  • Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin

Wathoni

  • O jẹ ẹbun owo: N1,250,000
  • Eroja iṣaraloge
  • Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin

Brighto

  • O jẹ ẹbun owo: N970,000
  • Ọ̀dà
  • Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin

Tolanibaj

  • O jẹ ẹbun owo: N825,000
  • Irinajo silu Abuja
  • Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin

Praise

  • O jẹ ẹbun owo: N770,000
  • Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin

Lucy

  • O jẹ ẹbun owo: N570,000
  • Ọ̀dà
  • Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin

Kaisha

  • O jẹ ẹbun owo: N570,000
  • Ọ̀dà
  • Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin

Tochi

  • O jẹ ẹbun owo: N220,000
  • Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin

Eric

Ẹẹdẹgbẹta Dọla owo Bitcoin