Osun Deputy Chief of Staff Fraud: Agbẹjọ́rò Binuyo ní ìbanilórúkọjẹ́ ní wọ́n fí ẹ̀sùn gbájúẹ̀ ṣé fún

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbẹjọro fun igbakeji olori oṣiṣẹ lọọfisi gomina ipinlẹ Osun, Abdullah Binuyọ, ti fesi si iroyin to gbode pe awọn ọlọpaa ti fẹsun gbajuẹ kan an oun.
Wahab Ismail, to jẹ agbẹjọro Binuyo, ti wa fi atẹjade sọwọ si BBC Yoruba lori ọrọ yii, to si ni wọn fẹ ba orukọ onibara oun jẹ ni pẹlu iroyin yii.
Saaju asiko yii ni awọn iwe iroyin kan ti gbe iroyin pe, ọfisi ọga agba ọlọpaa Naijiria ti pe Abdullahi Binuyo lẹjọ, lori ẹsun mẹrin to da lori iwa gbajuẹ ati iwe yiyi.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- €10,000, ara owó tí wọn fi ra Ighalo pòórá, Ilé aṣòfin Osun bẹ̀rẹ̀ ìwádìí
- PDP àti APC fi ìbọn dárà l'Ondo, ọ̀pọ̀ èèyan farapa, àìmọye dúkìá ṣòfò
- "Dípò ìnákúnàá lórí ìgbéyàwó ọmọ mi, mo lò owó fún ìgbéyàwó ọmọ òrukàn mẹ́tàlá"
- Àwàdà kẹríkẹrì nígbà táwọn olùdíje ààrẹ́ Amerika méjì kọjú ìjà síra wọn
- Ìjọba àpàpọ̀, jọ̀ọ́ máṣe yẹ̀ lórí àdéhùn rẹ fẹ́gbẹ́ òṣìṣẹ́ - Ile aṣojú-ṣòfin
- Ọgọ́rin arìnrìnàjò tó padà wá sí Nàìjíríà ló ní Coronavirus - PTF
- Wo iye tí ìjọba yóò gbà lọ́wọ́ Laycon gẹ́gẹ́ bí owó orí ẹ̀bùn BBNaija tó jẹ
- N kò mọ ẹni tó fẹ́ gba ìyàwó mi, àmọ́ wọn máa ń sọ pé ó rẹwà - Mike Bamiloye
O ni ko si ootọ ninu ẹsun naa, to ni igbakeji olori osisẹ lọọfisi gomina l‘Osun gbimọran pẹlu awọn eeyan kan, lati lu arakunrin Tunde Ajalani ni gbajuẹ owo to to $120,000.
Wahab ni ''Ọrọ naa jẹ ọrọ iwa agabagebe ti awọn to gbe jade ko si na tan . Wọn mọọmọ fẹ fi tabuku Binuyo ni''
O ṣalaye pe, bo tilẹ jẹ pe lootọ ni Binuyo mọ si idunadura to waye laarin awọn to ṣe owo to fori sanpọn naa, wọn ko le mu labẹ ofin pe o jẹbi.
O fi kun pe, iye owo ti wọn n sọ ọhun kii ṣe ẹgbẹrun lọna ọgọfa dọla, bi kii ṣe pe ẹgbẹrun lọna ọgọrun dọla nii ṣe.

Oríṣun àwòrán, Twitter/nigeria police
Agbẹjọrọ naa tun sọ pe, lati nkan bii ọdun kan sẹyin ni awọn ti da owo naa pada, ti awọn agbẹjọro rẹ ati ọlọpaa naa jẹri si.
O wa pari ọrọ rẹ pe, awọn yoo tọ ipasẹ ofin lati tako ibanilorukọjẹ ti wọn fẹ ṣe fun Binuyo yii.
Labẹ ofin orilẹede Naijiria, awọn ẹsun ti wọn fi kan Binuyo jẹ eleyi ti ijiya wa fun labẹ ofin, to ni ṣe pẹlu iwa jibiti ati awọn ẹsẹ miran.













