Petrol Price Hike: Ilé aṣojú-ṣòfin dúró ìṣẹ́jú kan fún Buruji Kashamu àti Rose Okoh

Femi Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, @SpeakerGbaja

Ile igbimọ asoju sofin Naijiria ti rọ ijọba apapọ, lati tẹle adehun ti wọn ṣe pẹlu ẹgbẹ oṣiṣẹ, eyi to mu ki wọn ṣẹwele ipinu lati gunle iyansẹlodi ati ifẹhonu han.

Awọn ọmọ ile igbimọ asoju sofin l'Abuja sọ eyi di mimọ, lẹyin ti wọn wọle pada lẹyin isinmi oloṣu meji ti wọn gunle, fun isinmi ọdọdun ti wọn maa n ṣe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ijoko ile naa, ti abẹnugan ile Femi Gbajabiamila dari, salaye pe, o ṣe pataki ki ijọba apapọ tẹle adehun ti awọn ati ẹgbẹ oṣiṣẹ se ti wọn fi wọgile ipinu wọn lati bẹrẹ iyanṣẹlodi to yẹ ko bẹrẹ lọjọ aje.

Ile asoju sofin

Oríṣun àwòrán, @SpeakerGbaja

O ni ninu ifọrọwerọ wọn, ijọba apapọ ṣe adehun fawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ati ọmọ Naijiria lapapọ, eyi ti wọn si gbọdọ tẹle.

O fi kun le pe, bi wọn ba ṣe n tẹle adehun yii ko gbọdọ pa gbogbo akitiyan ijọba lara, lati ṣe gbogbo eto amuludun ti wọn ti n pinu lati ṣe tẹlẹ tabi eyi ti wọn n ṣe lọwọ.

Bakan naa ni abẹnugan ile tun ka iwe ẹbẹ aarẹ, to n bere fun ibuwọlu ile lati san idapada owo fun awọn ipinlẹ marun kan, lori awọn opopona ti wọn ṣe lati inu apo ijọba ipinlẹ wọn.

Ile igbimọ asofin n lo ẹrọ igbalode ti awọn eniyan le ma fi wo ijoko ile loju ẹsẹ

Oríṣun àwòrán, @SpeakerGbaja

Ile igbimọ asofin ninu ijoko ile ṣe idakẹ jẹ iṣẹju kan, fun awọn ọmọ ile igbimo asofin agba meji to papoda, sẹnatọ Rose Okoh ati Buruji Kashamu.

Gbajabiamila ni fun igba akọkọ ninu itan ile igbimọ asofin, ile igbimọ asofin n lo ẹrọ igbalode ti awọn eniyan le ma fi wo ijoko ile loju ẹsẹ.

O ni araalu yoo tun lanfaani lati maa wo bi ijororo ile ati gbogbo idibo yoo se maa waye, bakan naa ni yoo maa lọ si ipamọ fun itan ọjọ iwaju.

A ti ja aráàlú kulẹ̀, ta bá pè wọ́n fún ìwọ́de, wọn kò ní jẹ́ wa mọ́ - NLC Eko

Asia ẹgbẹ osisẹ nibi iwọde

Oríṣun àwòrán, @NLCHQ_ABUJA

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, ajọ to n se akoso ina ọba ni Naijiria, NERC ti ni, awọn yoo tẹle aṣẹ ijọba apapọ lati da owo ina ọba pada si bo ṣe wa tẹlẹ, ki wọn to fi owo le.

Ajọ NERC fi idi ọrọ naa mulẹ lasiko ti wọn fesi si ikede ijọba to mu ki ẹgbẹ oṣiṣẹ fagile iyanṣẹlodi ti wọn fẹ bẹrẹ ni Ọjọ Aje.

NERC ni awọn ti gbọ gbogbo ohun ti ijọba pa laṣẹ, amọ awọn nilo asiko lati gbeyẹwo, lori bi adinku yoo se ba ina ọba laarin ọsẹ meji.

Ajọ naa fikun pe, gbogbo igbesẹ to ba tọ ni oun yoo gbe, lọna ati tẹle ofin ti ijọba apapọ pa laṣẹ fun wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo fẹhọnu han lẹyin ti ajọ Amunawa lorilẹede Niajiria gbe owo le ina ọba, ti ẹkunwo naa si tun ba owo epo bẹntirol lasiko kan naa.

Àkọlé fídíò, Obateru Akinruntan: Wíwá ohun tá jẹ títí láé ló gbé wa kúrò nílé Ife

Eyi lo mu ki ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ tiraka lati gunle iyanṣẹlodi, amọ wọn gbegile iyanṣẹlodi naa lẹyin ti ijọba paṣẹ pe ki ina ọba pada si bo ṣe wa tẹlẹ ki wọn to fi owo kun un.

Ibanujẹ ọkan lo jẹ fun mi bi ẹgbẹ NLC ṣe wogile iyanṣẹlodi - NLC Eko

Alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ Eko, Comrade Agnes Funmi-Sessi, ti bu ẹnu atẹ lu bi ẹgbẹ oṣiṣẹ lapapọ, NLC, ṣe paṣẹ pe ki wọn gbegile iyanṣẹlodi ti wọn fẹ gunle ni Ọjọ Aje, tako ọwọn gogo epo bẹntirol ati ina ọba.

Comrade Funmi-Sessi lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni ohun ti ijọba apapọ n ṣe ni lati pana iyanṣẹlodi naa lasiko yii.

Awọn osisẹ to n se iwọde

Oríṣun àwòrán, @NLCHQ_ABUJA

O ni ibanujẹ ọkan lo jẹ fun oun wi pe, awọn adari NLC gbọ si ijọba lẹnu nitori awọn eniyan ti mura silẹ lati bẹrẹ iyanṣẹlodi tako ọwọngogo naa.

Amọ, Alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ Eko naa ni, awọn ko le e ṣe ohunkohun lẹyin aṣẹ ti awọn adari oṣiṣẹ pa fun wọn, nitori naa ni awọn ṣe pana iyanṣẹlodi ohun.

"Awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Eko ti gbaradi lati ṣewode ati iyanṣẹlodi kaakiri ipinlẹ naa loni, amọ awọn adari wa ti gbabọde fun wa".

"Adura wa ni wi pe, ki ẹgbẹ oṣiṣẹ ma doju ti awọn ọmọ Naijiria, pẹlu igbesẹ ijọba lori ọwọn gogo owo epo bẹntirol ati ina mọnamọna."

"Ti ọsẹ meji ba pe, ti ko si si aṣeyọri kankan, awọn ọmọ Naijiria ko ni da wa loun mọ, ti a ba pe wọn fun iyanṣẹlodi tabi ifẹhọnu han.".

Awọn osisẹ to n se iwọde

Oríṣun àwòrán, @NLCHQ_ABUJA

Nibayii, Comrade Funmi -Sessi ni awọn ko i tii mọ ohun to kan gẹgẹ bi oṣiṣẹ, amọ awọn n duro de aṣẹ ẹgbẹ NLC, lori ohun to kan lẹyin ti wọn ti wọgile iyanṣẹlodi naa.

Àlàyé rèé lórí ìdí tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ kò fi ní bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì mọ́ lónìí

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria, Nigeria Labour Congress ati akẹẹgbẹ rẹ, Trade Union Congress, ti fagile iyanṣelodi ọlọjọ gbọọrọ to yẹ ko bẹrẹ loni.

Eyi ko ṣẹyin abajade ipade pajawiri ti ijọba apapọ ati awọn oṣiṣẹ ṣe lati aago mẹjọ alẹ Ọjọ Aiku, titi di afẹmojumo Ọjọ Aje, ti o yẹ ki iyanṣẹlodi naa bẹrẹ.

Ẹgbẹ osisẹ n se iwọde

Oríṣun àwòrán, @NLCHQ_ABUJA

Lẹyin ijiroro fun ọpọlọpọ wakati, ni ijọba paṣẹ ki iye owo ti awọn eniyan n san lori owo ina ọba pada si bo ṣe wa tẹlẹ fun ọsẹ meji.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Minisita fun ọrọ iṣẹ ati igbanisiṣẹ, Chris Ngige to soju ijọba lo ka abajade ipade naa.

Ẹgbẹ osisẹ n se iwọde

Oríṣun àwòrán, @NLCHQ_ABUJA

Ninu ọrọ ti wọn, ẹgbẹ oṣiṣẹ ni awọn gbegi le iyanṣẹlodi naa fun ọṣẹ meji, lati fun ijọba apapọ laaye lati gbe igbesẹ to yẹ fun awọn oṣiṣẹ.

NLC ni awọn igbesẹ ijọba naa gbọdọ fun awọn osisẹ ni igbe aye irọrun, ki wọn si da awọn ohun to wọn gogo pada si bi o ṣe wa tẹlẹ.

"Laarin ọsẹ meji naa ni ajọ to n risi ọrọ ina oba, DISCOs, yoo fi wọgile owo ina oba ti o ti da owon gogo yii'

Bakan naa ni ijọba fikun pe, wọn n gbe igbesẹ lati ma a ṣe iranwọ fun awọn oṣiṣẹ nipa owo ọkọ, owo ina ọba, owo ile gbigbe, eto ọgbin ati awọn owo iranwọ miran.

Ijọba fikun wi pe, wọn yoo pese ọkọ ti yoo ma gbe awọn eniyan kaakiri ni awọn ilu nla ni orilẹede Naijiria, to fi mọ igberiko, ki ọdun 2021 to pari.

Awọn olufẹhonuhan l'Osogbo

Bakan naa ni awọn oṣiṣẹ ijọba yoo ni anfaani si ida mẹwaa ninu ile igbe ti ijọba apapọ n kọ kaakiri.

Awọn to wa nibi ipade naa ni Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ, Ayuba Wabba ati akẹgbẹ rẹ ni ẹgbẹ TUC, Quadri Olaleye.

Bakan naa ni Minisita fun ọrọ oṣiṣẹ, Chris Ngige; Minisita fun ọrọ epo bẹntirol, Timipre Silva; Festus Keyamo (SAN) wa nibi ipade naa.

Àkọlé fídíò, Obateru Akinruntan: Wíwá ohun tá jẹ títí láé ló gbé wa kúrò nílé Ife

Ko tan sibẹ o, Minisita fun ọrọ iroyin, Lai Mohammed ati akọwe ijọba apapọ, Boss Mustapha naa bawọn peju sibẹ pẹlu.

À ń dúró de òṣìṣẹ́ tó bá ṣèwọ́de, ẹ finmú káta òfin - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Yoruba bọ, wọn ni ka wi fun ni ka to da ni, agba ijankadi.

Eyi lo jẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria kilọ fawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC to fẹ gunle iyanṣẹlodi lọla ọjọ Aje lori afikun owo ina ọba ati epo bẹntiro.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Frank Mba ti sọ pe, oṣiṣẹ to ba jade lati ṣe iwọde lọjọ yoo foju wina ofin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni wamuwamu lawọn ọlọpaa n duro de awọn oṣiṣẹ to ba fẹ ṣe iwọde, awọn yoo si se ohun to tọ labẹ ofin.

Mohammed Adamu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigeria Police Force

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa sọ fawọn akọroyin pe, ọrọ oun ko ju bayii lọ lori erongba ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lati gunle iyanṣẹlodi lọla.

Ṣugbọn awọn agbẹjọro kan ni ileeṣẹ ọlọpaa ko lagbara labẹ ofin lati da ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ duro pẹlu iwọde ti wọn fẹ ṣe.

Agbẹjọro agba, Chino Obiagwu sọ pe, ko lẹtọ labẹ ofin fun ileeṣẹ ọlọpaa lati gba iṣẹ ileẹjọ ṣe, nipa dida awọn oṣiṣẹ duro pẹlu iwọde ti wọn fẹ ṣe.

Amofin Obiagwu ṣalaye pe, lootọọ ni ileẹjọ to n ri si ọrọ osisẹ paṣẹ pe ki ẹgbẹ osisẹ mase gunle iynaṣẹlodi ṣugbọn ileẹjọ ko ni ki wọn maa ṣe iwọde.

Awọn osisẹ n pin iwe iwọde

Oríṣun àwòrán, @NLCHeadquarters

O ni ọrọ to wa nilẹ kii ṣe ọrọ iwa ọdaran ti ọlọpaa le da si, ọrọ iṣẹ ni.

Agbẹjọro Obiagwu ni, to ba wu ijọba apapọ, o le lọ si ileẹjọ ti o ba ro pe awọn oṣiṣẹ ti tapa si ofin, amọ ọrọ naa ko kan ọlọpaa rara.

Ẹwẹ, olori awọn oṣisẹ lorilẹede Naijiria, Ọmọwe Folasade Yemi-Esan tẹlẹ ti rọ awọn oṣiṣẹ jake jado Naijiria pe ki wọn ma ṣalai lọ sibi iṣẹ lọjọ Aje.

Àkọlé fídíò, Yemen Water Child: Ọmọdé 44 ni Sọ́jà pa, tí 100 míì sì kú látọwọ́ ohun ìjà olóró

Ẹ̀yin òṣìṣẹ́, ẹ má ṣáì lọ síbi iṣẹ́ lọ́jọ́ Ajé, olórí àwọn òṣìṣẹ́ ní Nàìjíríà tako ìyanṣẹ́lódì

Olori awọn oṣisẹ lorilẹede Naijiria, Ọmọwe Folasade Yemi-Esan ti rọ awọn oṣiṣẹ jake jado Naijiria pe ki wọn ma ṣalai lọ sibi iṣẹ lọjọ Aje.

Amọran yii waye lẹyin ti ẹgbẹ apapọ awọn oṣiṣẹ ni naijiria kede pe iyanṣẹlodi yoo bẹrẹ lọjọ Aje lati fi ẹhonu han lori bi ijọba apapọ ti ṣe afikun owo ina ọba ati epo bẹntiro.

Folasade Yemi-Esan

Oríṣun àwòrán, Twitter/@eniola esan

Ọmọwe Yemi-Esan rọ awọn oṣiṣẹ papaa julọ awọn to wa nipele kejila lọ soke atawọn oṣiṣẹ ko ṣee maa ni lati lọ sẹnu iṣẹ wọn lọjọ Aje.

Olori awọn oṣisẹ ni Naijiria ṣalaye pe ijọba apapọ ṣi n jiroro lọwọ pẹlu ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lori ohun ti wọn fẹ ki ijọba ṣe gan an.

Ọmọwe Yemi-Esan tun sọ pe aṣẹ ti ileẹjọ to n ri si ọrọ awọn ile iṣẹ ni Naijiria l'Ọjọbọ ti sọ pe ẹgbẹ oṣiṣẹ ko le gunle iyanṣẹlodi mọ lọjọ Aje.

O wa rọ gbogbo awọn akọwe agba atawọn adari ẹka ileeṣẹ ijọba lati sọ fawọn oṣiṣẹ to wa labẹ wọn pe ki wọn rii pe awọn oṣiṣẹ lọ sibi iṣẹ lọjọ Aje to n bọ.

Àkọlé fídíò, SS3 ní mo wà báyìí, mo sì ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ púpò nílé-lóko gẹ́gẹ́ bí onílù - Ayansike

Kò sí iléẹjọ́ tó le dá wa dúró, ìyanṣẹ́lódì yóò bẹ̀rẹ̀ ní Ọjọ́ Ajé - NLC

Ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria, NLC ti ni dandan awọn yoo tẹsiwaju ninu iyanṣẹlodi ti awọn fẹ gunle bẹrẹ lati Ọjọ Aje, ọsẹ to n bọ.

Ọkan lara awọn adari ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ naa lo sọ fun BBC News Hausa pe awọn ko i tii ri iwe ipẹjọ ileẹjọ kankan to sọ wi pe ki awọn ma gunle iyanṣẹlodi.

Bakan naa ni ẹgbẹ oṣiṣẹ naa fikun wi pe awọn naa ni atilẹyin ileẹjọ lati tẹsiwaju ninu iyanṣẹlodi tako ọwọngogo owo epo bẹnitirol ati ina ọba.

Amọ, ileẹjọ kan ni ilu Abuja ti pasẹ ki ẹgbẹ oṣiṣẹ dawọ iyanṣẹlodi wn duro titi di igba ti awọn ma a gbọ ẹjọ ti ajọ kan pe mọ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC.

Adajọ Ibrahim Galadima gbe igbeṣẹ naa lẹyin ti Ajọ Peace and Unity Ambassadors Association pe fun ki ẹgbẹ NLC jawọ ninu iyanṣẹlodi ti wọn fẹ gunle ni ọjọ Aje.

Bakan naa ni ileẹjọ ohun pàṣẹ ki ẹgbẹ NLC ma di awọn ọmọ Naijiria lọwọ lati ṣe iṣẹ oojọ wọn.

Awọn olufẹhonuhan l'Osogbo

Ileẹjọ naa tun paṣẹ fun Ọga Agba Ọlọpaa ati adari ẹsọ alaabo lati ri wi pe awọn oṣiṣẹ ni aabo to daju lasiko ti wọn ba n ṣiṣẹ wọn tako aṣẹ NLC.

Amọ, ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ti ni gbogbo ọmọ Naijiria ni yoo kopa ninu iyanṣelodi yii nitori gbogbo ọmọ Niajiria lo n jẹ irọra bi wọn ṣe fikun owo epo ati ina ijọba ni Naijiria.

NLC ni owo oṣu oṣiṣẹ ti da radarada nitori ọwọngogo to gun owo epo, ina ọba, ati ounjẹ kaakiri Naijiria.

Ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ, epò, iná ọ̀ba ti sọ owó oṣù N30,000 da N9 nitórí náà kò ní sí ọjà, epo, iléèwòsàn láti Ọjọ́ Ajé - NLC

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria,NLC ti kede wi pe awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi ati ifẹhọnuhan kaakiri orilẹede Naijiria bẹrẹ lati Ọjọ Ajẹ, ọsẹ to n bọ.

Adari ileeṣẹ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ NLC ni ipinlẹ Eko, Onyeka Chris lọ sọ bẹẹ fun BBC News Yoruba lasiko to n sọrọ lori igbaradi wọn fun ifẹhọnuhan ọlọgọọrọ naa.

Chris ni awọn oṣiṣẹ darapọ mọ awọn ọmọ Niajiria to ku kaakiri lati tako igbesẹ ijọba to fi owo kun owo epo ati ina ọba naa.

O ni igbesẹ ijọba yii fihan wi pe ko ye wọn ohun ti awọn ọmọ Naijiria n la kọja kaakiri orilẹede Niajiria.

Ki lode to jẹ isinyii ni NLC fẹ ṣe ifẹhọnu han lẹyin ti awọn eniyan ti n ra ọwọngogo epo, ina ati ounjẹ?

Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ni awọn tẹlẹ gbogbo igbesẹ to yẹ lati ri wi pe ijọba yi ipinnu wọn pada ko to di asiko yii.

Amọ, ijọba ko fun wọn ni esi lori gbogbo lẹta ati iwe ti awọn fi ranṣẹ si ijọba ko to di wi pe awọn gbe igbesẹ lati ṣe ifẹhọnuhan ati iyanṣẹlodi tako igbesẹ ijọba.

Àkọlé fídíò, Toyin Atoyebi mechanic: Ẹ wo Toyin, ọmọbinrin ọdún 16 tó ń tún skadà àti gẹnẹrátọ̀ ṣe ní

NLC ni awọn tele ilana ati alakalẹ ti o ṣe koko ki awọn to gunlẹ iyanṣelodi ni ko jẹ ki awọn tete bẹrẹ ifẹhọnuhan di asiko yii.

Gbogbo ẹgbẹ oṣiṣẹ ijọba, awọn oniṣẹ ọwọ, awọn ọdọ, awọn adari ẹgbẹ akẹkọọ lo parapọ sọ wi pe ki iyanṣẹlodi yii tẹsiwaju.

Awọn wo ni yoo kopa ninu iyanṣẹlodi yii ati fun igba wo?

Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ti ni gbogbo ọmọ Naijiria ni yoo kopa ninu iyanṣelodi yii nitori gbogbo ọmọ Niajiria lo n jẹ irọra bi wọn ṣe fikun owo epo ati ina ijọba ni Naijiria.

NLC ni owo oṣu oṣiṣẹ ti da radarada nitori ọwọngogo to gun owo epo, ina ọba, ati ounjẹ kaakiri Naijiria.

''Owo osu N30,000 ti da N9 nitori owongogo ti ba ounjẹ ti ko si ṣe e ra mọ.''

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Aṣa: Ọ̀rọ̀ Ẹ̀yán ni Bunmi Femi Amao ń kọ́ wa lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà lóri BBC Yoruba

''Ohun to buruju ni wi pe awọn oloṣelu to fi owo kun owo epo, ina ọba kii san owo kankan lati ra nkan wọnyii, ọfẹ ni wọn n rii lọ''.

''Mẹkunu ti ko ni iṣẹ, ti oun jẹ iya ni igbesẹ ijọba n fi aye ni lara.''

''Titi da igba ti ijọba ba da owo epo ati ina ọba pada si bo ṣẹ wa tẹlẹ ni awọn yoo to jawọ ninu iyanṣẹlodi naa.''

Bakan naa ni wọn fikun wi pe ileeṣẹ kankan ko ni ṣi, awọn ileepo ko ni ṣi, ojuko iwapo, ileewosan, ileeṣẹ ijọba, ileeṣẹ ofurufu ati bẹẹ lọ ni yoo darapọ.

A kò sí lára àwọn tó ń ṣèwọ́de tako èlé owó epo àti iná ọba - NLC

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorilẹede Niajiria, NLC ti ni awọn ko gbero lati ṣe ifẹhọnuhan tako owongogo bẹntirol ati ina mọnamọna.

Igbakeji adari ẹgbẹ NLC lorilẹede Naijiria, Comrade Joe Ajaero lo fi ọrọ naa lede lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori boya ifẹhọnu han yoo waye ni ọjọ Isẹgun, Ọjọ Kẹjọ, Oṣu Kẹsan, ọdun 2020.

Eyi ko ṣẹyin iroyin to n tan kaakiri pe ẹgbẹ oṣiṣẹ yoo bẹrẹ ifẹhọnuhan tako bi ijọba apapọ ṣe fi owo kun owo epo bẹntirol.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Comrade Joe ni awọn ko i tii fun ọmọ ẹgbẹ awọn ni aṣẹ kankan lati bẹrẹ ifẹhọnu han.

Ẹgbẹ osisẹ n se iwọde

Oríṣun àwòrán, @NLCHQ_ABUJA

O ni ifẹhọnu ti awọn fẹ ṣe ni Ọjọ Iṣẹgun ni lati dẹkun ifiyajẹni to n waye ni ipinlẹ Rivers.

Ẹgbẹ NLC ni ijọba n fi iya jẹ awọn oṣiṣẹ ni ipinlẹ Rivers, ti wọn ti lẹ n na lara wọn nitori wọn n bere fun ẹtọ wọn.

Bakan naa ni wọn fikun wi pe lati igba ti ijọba apapọ ti n gbimọ rẹ ni awọn ti bẹrẹ si ni tako igbeṣẹ naa.

Nibayii, NLC ni awọn ti bẹrẹ ijiroro pẹlu ijọba lati yi igbeṣẹ naa pada.

Amọ, ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC fikun pe awọn yoo gunle iyanṣelodi ti ijọba ba kọ lati gba ero wọn ro, abi ti wọn ni dandan awọn yoo tẹsiwaju pẹlu owongogo owo epo bẹntirol ati ina mọnamọna naa.

Ninu ọrọ tirẹ, Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ni idi ti oun fi gbe igbesẹ naa ni lati fi opin si iwa jẹgudujẹra ni ẹka mejeeji, ki idagbasoke ba a le ba ọrọ ajẹ ni Niajiria.

Ọjọ́ Ìṣẹ́gun yóò ro lásìkò ìwọ́de lórí èlé owó epo - Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́

Yoruba ni awifuni ko to da ni, agba ijakadi ni, bẹẹ si ni ogun awitẹlẹ kii pa arọ, eyiun arọ to ba gbọn.

Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn osisẹ ni Naijiria, NLC ati TUC ti n leri leka pe ọjọ isẹgun yoo ro lorilẹede Naijiria.

Idi ni pe awọn ẹgbẹ osisẹ mejeeji yii ti n palẹ ogun mọ lati gbena woju ijọba apapọ lori alekun owo eroja epo rọbi to se.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn ẹgbẹ osisẹ naa ni awọn yoo gun le iwọde lati tako ele owo ori epo naa, bẹẹ ni awọn ti n se koriya ati itaniji fawọn osisẹ lati kopa ninu iwọde naa.

Àkọlé fídíò, Baby abandoned on dunmpsite: Mo ti bímọ mẹ́rin tẹ́lẹ̀ fún bàbá méjì nínú òṣí- Dupe Ogbomos

Amọ awọn eeyan kan ti n kede loju opo ayelujara pe ileẹjọ kan ti da awọn ẹgbẹ osisẹ ọhun lọwọkọ lati mase gunle iwọde ti wọn n gbero naa.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lori ikede ile ẹjọ naa, igbakeji aarẹ fun ẹgbẹ TUC, Chika Onuegbu sisọ loju rẹ pe, awọn ko tii ri iwe kankan gba lati ile ẹjọ to tako iwọde ti awọn n gbero yii.

Onuegbu ni "Lọwọ lọwọ, awa si n ko awọn ọmọ ẹgbẹ wa jọ lati fi ẹhonu han lori owo tijọba fikun owo epo, eyi to n nipa to ko dara lori awọn osisẹ nilẹ yii.

Bakan naa ni wọn tun fi owo kun owo ina ọba lasiko kannaa, to fi mọ owo ori awọn ọja gbogbo, eyi to nipa buruku lori owo ounjẹ atawọn ohun eelo fun igbaye-gbadun gbogbo osisẹ."

O fikun pe lasiko ti ọwọn ọja n waye yii, nijọba tun jẹ awọn osisẹ kan lowo osu, owo ifẹyinti ati owo ajẹmọnu ifẹyinti lẹnu isẹ, eyi ti ko wu eti gbọọ rara.

Awọn ẹgbẹ osisẹ naa wa kesi ijọba apapọ lati da owo epo pada si iye to wa tẹlẹ bibẹẹ kọ, awọn yoo korajọ lati fi ẹhonu to lagbara han ni Naijiria.

Awọn olufẹhonuhan l'Osogbo

Ó tó gẹ́ẹ́! Àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe ìwọ́de l'Osogbo lórí àfikún owó epo bẹntiróò

Awọn eeyan niluu Osogbo tii ṣe olu-ilu ipinlẹ Oṣun ṣe ifẹhonuhan lori afikun owo epo bẹntiroo ti ijọba apapọ ṣẹṣẹ kede rẹ.

Ẹgbẹ kan to n jẹ The Osun Civil Societies Coalition (OCSC) lo ṣagbatẹru ifẹhonahan naa.

Laarọ ọjọ Ẹti lawọn eeyan peju pesẹ si Nelson Mandela Freedom Park, l'Osogbo, lati fi aidunnu wọn han si igbẹsẹ ijọba lati sọ epo jala di naira mọkanlelọgọta.

Olufẹhonuhan l'Osogbo

Ọpọ awọn olufẹhonuhan lo gbe beeba lọwọ eyi ti wọn kọ oriṣiiriṣii ọrọ sii bi ''awa o faramọ afikun owo epo''(NO TO FUEL PRICE INCREMENT), ''O TO GẸẸ''(ENOUGH IS ENOUGH) ati bẹẹ lọ.

Awọn olufẹhonuhan l'Osogbo

Minisita abẹle fun epo rọbi, Timipre Marlin Sylva ti kọkọ ṣalaye pe owo iranwọ ti ijọba ko fi si ori epo mọ lo jẹ ki ayipada maa ba iye tawọn ọmọ Naijiria n ra epo looreekooree.