LASEMA: Afẹ́fẹ́ gáàsì ṣe ìjàmba fún èèyàn 30, ilé 23,ọkọ 15 ní ìpínlẹ̀ Eko

Oríṣun àwòrán, Twitter/LASEMA
Ọjọ buruku ẹsu gbomimu lo jẹ fun awọn awọn eniyan agbegbe Balogun, Iju Ishaga nipinlẹ Eko ni Ọjọru.
Lẹyin ti ọkọ nla to n gbe afẹfẹ gaasi gbina to si jọ ile mẹtalelogun, ọja, ọkọ marundinlogun, ti eniyan ọgbọn si farapa ninu iṣẹlẹ naa.
Ajọ Lasema loju opo ikansiraẹni Twitter wọn ni awọn ọkọ nla to gbina naa gbe afẹfẹ gaasi wa si agbegbe naa ni ki o to gbina.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Awọn ọlọpaa, ileeṣẹ panapana ati ẹsọ alaabo NSCDC lo yara de ibi iṣẹlẹ naa ti wọn si pa ina naa, lẹyin to ti ṣọṣẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ajọ Lasema naa fikun wi pe awọn eniyan ọgbọn to farapa naa ti wa ni ileewosan kaakiri ipinlẹ Eko.
''Nigba ti awọn meji ti ifarapa wọn lagbara ti wa ni ileewosan ekọṣẹ ti ile iwa giga,Lagos State University Teaching Hospital,ni Ikẹja.''
Bakan naa ni wọn fikun wi pe ko si ẹmi ẹnikẹni to sọnu ninu ijamba ina naa.
Ìjàmbá iná pa èèyàn 23, tó fi mọ ọmọ iléèwé àlákọ́bẹ̀rẹ̀ ní Lokoja-Abuja
Ọ̀pọ̀ èèyàn àti akẹ́kọ̀ọ́ pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàmbá iná ni ojú ọ̀nà Lokoja sí Abuja

Awọn eeyan kan ti padanu ẹmi wọn lẹyin ti ọkọ kan to gbe epo bẹtiro gbina ni Felele, loju ọna Lokoja si Abuja.
Ni nkan bi aago mẹjọ aabọ owurọ Ọjọru ni iṣẹlẹ naa waye.
Awọn ọmọ ileewe, to fi mọ awọn akẹkọọ ileewe Gbogbonise 'polytechnic' ti ipinlẹ Kogi to wa ni tòsí ibi ti ijamba naa ti waye, wa lara awọn to kú.
Iroyin fidirẹmulẹ pe ọkọ agbepo naa lo kọlu ọkọ miran nitosi GT Plaza, gbajugbaja ile oúnjẹ kan to tun jẹ ibudokọ fun awọn ọkọ to n lọ lati ipinlẹ
Kogi si ibomiran, to si gbina loju ẹsẹ.
Ijamba naa tubọ buru kọja bo ṣe yẹ nitori bi awọn ọkọ miran to n bọ tun ṣe n wọ inu ijamba naa lai mọ.
Bakan naa ni iwe iroyin The Nation sọ pe ọkọ to jona le ni mẹwaa.
Ni bayii, awọn oṣiṣẹ alaabo ojupopo, FRSC, ati panapana ti wa nibi iṣẹlẹ naa.












