Akọ̀wé-owó wọ gàù ní iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé ó jí N500,000 lọ́wọ́ ọ̀gá rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Google
Akowe-ileeṣẹ kan ti wọ gau ni ileẹjọ lori ẹsun pe oji N500,000 ninu owo ọga rẹ.
Ẹsun ole jija ni wọn fi kan arakunrin to n gbe agbegbe 8, Solomon Ogunshuba, Dalemo, nipinlẹ Ogun.
Agbẹjọrọ ijọba sọ fun ileẹjọ pe ọdun 2019 si ọdun 2020 ni ileeṣẹ Dejol Bun Venture Limited ni Ijaiye, ni ilu Eko.
- Akomolede àti Aṣa: Ọ̀rọ̀ Ẹ̀yán ni Bunmi Femi Amao ń kọ́ wa lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà
- Ọ̀gá iléeṣẹ́ gbé £10 mílíọ̀nù ẹ̀bùn owó fún òṣìṣẹ́, èyí lohun tó pawọ́n pọ̀
- Orílẹ̀èdè Amẹrika ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wo wọlé-wọ̀de Atiku, àwọn ìyàwo rẹ̀ lórí owó tí wọ́n kó lọ sí òkèèrè
- Hisbah mú ọkùnrin mẹ́ta tó pín fídíò ìfipábánilòpọ̀ ọmọdébìnrin 16 tó fẹ́ ṣèyàwó lórí ayélujára
Agbẹjọro ijọba naa fi ẹsun kan akọwe owo naa wi pe ko fi iye owo to to N500,000 jabọ fun ileeṣẹ naa lasiko to n jabọ iye owo to wọle si ileeṣẹ naa.
Iwa yii ni o fi dero ileẹjọ, amọ ẹni ti wọn fi ẹsun kan naa sọ wi pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.
Adajọ ileẹjọ Magistreti, O. l. Adelaja ti ba beeli rẹ ni iye owo to to N500,000 pẹlu awọn oniduro meji.
Ọjọ Kejila, Oṣu Kẹwaa ni adajọ sun igbẹjọ naa si.
- Lawuyi Ogunniran, àgbà ọ̀jẹ̀ òǹkọ̀wé Eégún Aláré dágbére fáyé!
- Orílẹ̀èdè Amẹrika ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wo wọlé-wọ̀de Atiku, àwọn ìyàwo rẹ̀ lórí owó tí wọ́n kó lọ sí òkèèrè
- Ọ̀gá iléeṣẹ́ gbé £10 mílíọ̀nù ẹ̀bùn owó fún òṣìṣẹ́, èyí lohun tó pawọ́n pọ̀
- Hisbah mú ọkùnrin mẹ́ta tó pín fídíò ìfipábánilòpọ̀ ọmọdébìnrin 16 tó fẹ́ ṣèyàwó lórí ayélujára
- Bah N'Daw àti Assimi Goita di adarí tuntun láti tukọ̀ orílẹ̀-èdè Mali ní ọdún kan àti aàbọ̀