Mali transitional leaders: Bah Ndaw àti Assimi Goita ni wọ́n ní kó máa wa ọkọ̀ orílẹ̀-èdè Mali báyìí

Mali gba adari tuntun

Oríṣun àwòrán, @Lima

Minista to wa fun eto aabo lorilẹ-ede Mali tẹlẹ, Bah Ndaw ni wọn ti yan lati wa ọkọ orilẹ-ede naa fun ọdun kan ati aabọ gẹgẹ bi aarẹ to maa da eto iṣejọba pada sipo nibẹ.

Lọjọ Aje ni wọn fẹnuko pe ki oun ati Assimi Goita wa ọkọ orilẹ-ede naa de ibi oge nipa eto iṣelu.

Ogagunfẹyinti ni N'Daw jẹ ko to gba ipo yii ni Mali.

Assimi Goita naa jẹ ọgagun, oun naa lo wa nidi bi awọn ologun ṣe gba ijọba loṣu to kọja ni Mali.

Assimi ni wọn ni ko jẹ igba keji Ogagunfeyinti Bah N'Daw bayii.

Àkọlé fídíò, Abule Ado explosion: Irọ́ ńlá ní NNPC pa lórí ìbúghbàmù Abule Ado níbí tí ẹ̀mí èèyàn 23

Awọn mejeeji ni amuyẹ lati tukọ orilẹ-ede Mali ni asiko yii.

Diẹ lara amuyẹ naa ni pe adari asiko yii gbọdọ wa lati Mali, ko jẹ ẹni ọdun marundinlogoji si aadọrin ọdun, to maa ni iwa ọmọluwabi ti kii si fi ẹtna ṣe lawujọ.

Koda, amuyẹ miran ni pe ẹni naa ko gbọdọ ni ẹjọ iwa ọdaran nile ẹjọ.

Awọn amuyẹ yii naa ni ofin to de awọn minista ati awọn to ku ti wón maa yan sipo lati jọ ṣiṣẹ papọ.

Lasiko ipade ajọ ile Afirika, ECOWAS ni wọn ti fun awọn ọmọ ogun to gbajọba ni orilẹ-ede Mali ni gbendeke ọjọ kẹẹdogun, oṣu késan an yii lati gbe ijọba silẹ fawọn alagbada.

Àkọlé fídíò, Ogbologbo ijapa l'aafin Sọun