Edo Election: Mi ò tíì sọ̀rọ̀ lórí ìdìbò Edo, ẹ di etí yín sí àwọn tó fẹ́ tajà ìròyìn lórí ayélujára - Tinubu

Oríṣun àwòrán, Tinubu Instagram
Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu to jẹ ọkan lara awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ti fi ọ̀rọ̀ sita pé ki awọn ọmọ Naijiria kọ eti ikun si iroyin to n lọ lori ayelujara.
Iroyin ọhun to sọ pe ẹgbẹ oṣelu APC gba kamu lorii bi PDP ṣe fidi wọn janlẹ ninu idigbo to waye ni ipinlẹ Edo lọjọ kọkandinlogun oṣu kẹsan ọdun 2020.
Tinubu ninu ọrọ ti agbẹnusọ rẹ, Tunde Rahman fọwọ si sọ pe ayederu ni ọrọ naa ti wọn ro pe oun loun n sọ ọ ko si ki n ṣe ọrọ kan to fẹsẹ mulẹ.
- Àbájáde ìwádìí ẹlikọ́pítà to já ni Opebi nílùú Eko laipẹ yii ti jáde
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí ọkùnrin tó gé akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ wẹ́lẹ́ wẹ́lẹ́ fún òògùn owó ní Ikorodu
- Èèyàn mẹ́jọ jónà ráúráú nínú ìjàmbá ọkọ̀ akérò tó ṣẹlẹ̀ ní mọ́rosẹ̀ Eko sí Ibadan
- Wo bí Sunday Shodipe ṣe pa Funmilayo tó pa kẹ́yìn l' Akinyele
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ elétò ìlera, ẹ padà sẹ́nu iṣẹ́- JOHESU
Ṣaaju ni atẹjade kan n tan kalẹ lọjọ aje pe Aṣiwaju Tinubu sọ pe:
"ẹ jẹ ki inu wa dun ninu gbogbo ijakulẹ wa gẹlẹ bi a ṣe maa n yọ ninu iṣẹgun wa tori pe aduru ohun ti wọn n ṣe lati mu wa balẹ fihan bi a ṣe lagbara to. Ifidirẹmi wa si n fihan pe a o ki n ṣe Ọlọrun bii kii ṣe eniyan...".
Ayederu atẹjade naa tun sọ lorukọ Tinubu pe bi awọn eeyan ẹlẹran ara bii tawọn ba wa ri awọn bii ti wọn si n ṣajọyọ lori ifidirẹmi awọn bii pe wọn ṣẹgun Ooṣa, "a jẹ pe a sunmọ jijẹ Ooṣa naa niyẹn".
- Ọ̀wọ́ngógó búrẹ́dì gbòde kàn lẹ́yìn tí àwọn oníbúrẹ́dì da iṣẹ́ sílẹ̀
- Sudan tí bẹ̀rẹ̀ ìjìròrò lórí bí US yóò ṣe yọ òrúkọ̀ wọn kúrò nínù ikọ̀ agbẹ́sùnmọ̀mí àgbáyé
- Èèyàn mẹ́jọ jónà ráúráú nínú ìjàmbá ọkọ̀ akérò tó ṣẹlẹ̀ ní mọ́rosẹ̀ Eko sí Ibadan
- Ọlọ́jọ́ Festival 2020:Ọ̀ọ̀ni ti Ilé Ifẹ̀ tí wọ ìléèdí ọlọjọ méje tí kò ní rí ẹnikẹ́ni sójú
- Ìjọba Kaduna kéde ọjọ́ mẹ́ta fún ìdárò Emir Zazzau, Buhari, Tinubu, Babangida náà ń ṣèdárò
- Òṣèré méjì yìí ń fi ẹ̀wọ̀n runmú tóríi fíìmù "Ife" táwọn obìnrin ń bá ara wọn lòpọ̀
Pẹlu bi ọrọ inu atẹjade yii ṣe wuwo to ni awọn eeyan ṣe bẹrẹ si ni gbagbọ pe boya Aṣiwaju lo sọ ọ.
Ṣugbọn ninu ọrọ ti agbẹnusọ Ọgbẹni Tinubu fọwọ si to jade fun awọn oniroyin, Aṣiwaju ni oun o sọ ohun to jọ bẹẹ rara, pe ọgbọn alumọkọrọyi awọn to kan fẹ fi iroyin taja wara wara lori ayelujara ni.
O ni awọn to mọ Aṣiwaju daadaa mọ pe ko si ninu iwa rẹ lati maa ku giri sọrọ sita. "Tori naa, bi asiko ọrọ ba to, Aṣiwaju yoo fi ọrọ tirẹ sita lori bi eto idibo ipinlẹ Edo ṣe lọ".
Àwọn ọmọ Nàìjíríà gbarata lóríi fọ́nrán tí Tinubu fi síta lóríi dídìbò f'ún Obaseki ti Edo
Lẹyin ti gomina ipinlẹ Eko nigbakan ri Oloye Bola Ahmed Tinubu sọrọ ninu fọnran kan to fi sita ni ọjọ Isẹgun lori ẹni ti o fẹ ki awọn eniyan ipinlẹ Edo dibo yan ninu idibo gomina ti yoo waye lọjọ Satide, ọpọ ọmọ Naijiria lo tí ń fi ero wọn han lori ọrọ naa.
Ni kete ti akọwe fun gomina ipinlẹ Edo Godwin Obaseki fi esi ijọba sita lori ọrọ ti Tinubu sọ ni awọn ọmọ ẹgbẹ ati awọn ọmọ Naijiria ti n sọ ero tiwọn naa, to fi mọ ọkan lara agba ẹgbẹ Peoples Democratic Party (PDP) to tun jẹ igbakeji aarẹ Naijiria Nigba kan ri Atiku Abubakar.
Ninu ọrọ rẹ, Atiku ni ki wọn ma tẹle ọrọ ti Tinubu sọ bikose pe ki wọn tu yaya lọ lati dibo fun ẹgbẹ oselu PDP eyi ti Obaseki n ṣoju fun ni ipinlẹ Edo.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ni kete ti Tinubu sọrọ naa ni Atiku ti bọ sori atẹjiṣẹ Twitter rẹ nibi to ti salaye pe saa gomina ko tọ si Obaseki nitori naa ki wọn fun ni anfani saa kan si.
Bakan naa ni Atiku rọ àwọn eniyan ipinlẹ Edo lati yago fun iwa jagidijagan lasiko idibo nibẹ.
Ninu ọrọ tirẹ loju opo Twitter bakan naa Femi Fani-Kayode ni awada kẹrikẹri ni gbogbo ọrọ ti Tinubu sọ ninu fọnran naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
O fi kun-un pe ọrọ Tinubu le ṣe akoba fun Ize Iyamu ninu idibo to n bọ naa.
Ninu awọn miran to tun fi èrò wọn han ni Deji Adeyanju àti awọn ọmọ Naijiria miran.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3

End of X post, 4

End of X post, 5

End of X post, 6
Ẹ̀yìnkùlé bàbá Tinubu kò dé Edo, kò ṣe mẹ̀dọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Obaseki-PDP
Isọrọ ni igbesi, eyi lo mu ki ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, fesi pada fun Asiwaju Bola Ahmed Tinubu lori fidio to ti ni ki awọn eeyan Edo ma ṣe dibo fun Godwin Obaseki.
Gomina Godwin Obaseki ni oludije ẹgbẹ naa ninu idibo Gomina to n bọ lọna.
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa fi sita lojuopo Twitter, wọn ni ẹyinkule baba Tinubu ko de Edo, nitorinaa gale gale rẹ to n ṣe ninu fidio ọhun ko le yi ipinu awọn ara ilu Edo pada.
Ẹgbẹ naa sọ pe awọn eeyan Edo ti pinu lọkan wọn ti pẹ lati yan Obaseki si ipo pada nitorinaa ki Tinubu lọ ṣagbejẹ mọwọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 7
Yatọ si ọrọ ẹgbẹ yi, Oludamọran Gomina Obaseki lori ọrọ iroyin, Crusoe Osagie sọ pe ki Tinubu da ọrọ rẹ pada.
O ṣalaye pe awọn eeyan Edo ko faye gba baba isalẹ ninu oṣelu ipinlẹ wọn nitori naa ki Tinubu fawọn lọrun silẹ
'Ẹ má dìbò yín fún Obaseki', Tinubu késí àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ Edo
"Godwin Obaseki ko ba wa kopa ninu igbiyanju lati fi oṣelu awarawa rinlẹ, nitori naa ko yẹ lẹni taa dibo fun".
Asiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress,APC, Bola Ahmed Tinubu lo sọ ọrọ yi ṣaaju idibo Gomina ipinlẹ Edo.
Ninu fọnran fidio nkan bi iṣẹju mẹrin naa, Tinubu ṣalaye idi ti oun ṣe fẹ ki awọn ara ipinlẹ Edo ma ṣe dibo fun un.
Tinubu mu orisirisi akawe ọna ti Obaseki ko fi ṣe iṣe ẹni to nifẹ oṣelu awarawa to si ni eyi to lati ma ṣe dibo fun Obaseki.
''Gbogbo awọn agbaagba ilẹ yi parọwa si lati bọwọ fun ofin ilẹ wa ṣugbọn o keti ikun si wọn''
O tẹsiwaju pe bẹẹ lo bẹgi dina awọn aṣofin ilẹ Edo lati joko ijiroro ni ile aṣofin.
''Ẹ ma ṣe dibo fun Obaseki, mo parọwa si yin''
Ẹgbẹ oṣelu APC ni Godwin Obaseki ti dije dupo wọle gẹgẹ bi Gomina ipinlẹ Edo.

Oríṣun àwòrán, others
- Njẹ́ o mọ̀ pé bíi ọdún 700 sẹ́yìn ni wọ́n ti ń bọ Osun-Osogbo? Mọ̀ síi nípa ìtàn ojúbọ̀ nàá
- Mi ò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí ẹ fi kàn mí pé mo ya "Blue Film" nínú igbó Osun Osogbo - Jolaosho TBlak
- Àgbàọ̀jẹ̀ òṣèré Shan George ṣetán láti ṣègbéyàwó pẹ̀lú ọkọ kẹẹ̀rin lẹ́ni ọdún 50
- Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn tó wá láti ìdílé ẹrú kìí lọ́kọ tàbí aya láyé òde òni ní Nàìjíríà?
Ija lo de, orin dowe to waye laarin oun ati alaga ẹgbẹ, Adams Oshiomole lo ṣokunfa bi Obaseki ti ṣe kuro ni ẹgbẹ APC lọ si PDP.
Ninu idibo Gomina ipinlẹ Edo to n bọ lọna, Obaseki ati Pasitọ Ize Iyamu ni wọn yoo jijọ du ipo.
Fọnran fidio Tinubu yi jẹ akọkọ iru rẹ nibi ti Tinubu yoo ti jader sita lati parọwa si ara ilu lati ma ṣe dibo fun ẹni to kuro ninu ẹgbẹ APC.
Saaju gbogbo ọrọ ti Tinubu n sọ nipa Obaseki ko ju pe ko sọ loju opo Twitter tabi ninu atẹjade.