Tinubu: Buhari kò leè du ipò fún sáà kẹta láéláé

Oríṣun àwòrán, Presidency
Aarẹ Muhammadu Buhari ati Asiwaju Bola Ahmed Tinubu sepade pọ nilu Abuja lọjọ Isẹgun.
Lẹyin ipade bonkẹlẹ to waye laarin awọn mejeeji, Tinubu sọ fun awọn ọmọ Naijiria pe asaaju Naijiria naa jẹ oniwa rere ati onigboya eniyan, ti ko si lee fẹ se saa kẹta lori aleefa laelae.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Pásítọ̀ pe Naira Marley ní ẹlẹ́mìí èṣù, Marley fèsì padà pé kí pásítọ̀ gan tẹ èṣù mọ́lẹ̀
- Ẹ́ gba fóónù, ẹ pe ẹbí yín pé a fẹ́ dáná ṣun yín - Aráàlú sọ fún adigunjalè méji
- N kìí gbádùn ara mi tí ń kò bá jà lọ́jọ́ kan- Ango Argungun
- Díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò mi ìgboro tìtì l'ọ́dún 2020 rèé
- Ó ti di ogójì èèyàn tí wọ́n tẹ̀ pa níbi ìsìnkú Qasem Soleimani tí kò wáyé mọ́
Amọ Naijiria ti ori rẹ ba pe, to ba si ti ba aarẹ Muhammadu Buhari sisẹ ri yoo mọ pe kii se ẹni to lee ti ọwọ bọ ofin ilẹ wa Naijiria.
Awọn eeyan ti ko fẹ ko gbajumọ isẹ to n se lori ipo aarẹ, lo n fura kiri, ti wọn si n fi awọn ẹsun ti ko tọ kan Buhari, sugbọn emi ni mo ti n ja fun ifẹsẹmulẹ ijọba awa ara wa.

Oríṣun àwòrán, Presidency
"Alatako ni mo jẹ tẹlẹ fun Buhari ko to di pe erongba sise saa kẹta de, eyi ti asaaju kan tẹlẹ nilẹ yii kuna lati gbe kalẹ. Mo mọ Buhari pe ko lee gbinyanju iru rẹ laelae."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post










