Ritual Murder: Ọlọ́pàá hú òkú akẹ́kọ̀ọ́ fásítì LASU tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àti pásítọ̀ ṣekúpa

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police
Ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oṣun ti hu oku akẹkọọbinrin fasiti ipinlẹ Eko LASU.
Omobinrin naa, Favour Daley-Oladele n mura fun eto agunbanirọ, ki ọrẹkunrin rẹ ati pasitọ kan to jọ gbimọ pọ ṣekupa ni Ikoyi-Ile, ni ipinlẹ Oṣun.
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Oṣun to siwaju awọn to hu oku naa, Babatunde Kokumo ṣalaye pe hihu oku naa ṣe pataki fawọn ọlọpaa lati pari iṣẹ iwadii wọn lori iṣẹlẹ naa.
Pasito ijọ alaṣọ funfun kan, Segun Philip ati Adeeko Owolabi to jẹ ọrẹkunrin Favour pẹlu iya rẹ, Bola Oladele ni wọn ti wa ni gbaga ile iṣẹ ọlọpaa lori ẹsun pe wọn jọ gbimọ pọ ni.
Pasitọ Philip ati Owolabi jẹwọ pe lootọ lawọn pa Favour lati fi ṣe oogun owo, amọ ẹlẹda ọmọbinrin naa ko jẹ ni ni oogun owo.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo wọn pẹlu Adeeko lo ti ṣalaye pe pasitọ fun oun ni ọmọ odo lati fi lu u lori ti pasitọ si sare fi ọbẹ yọ ọkan rẹ eyi to fi se asejẹ fun Adeeko ati iya rẹ.
Owolabi ẹni ọdun mẹtalelogun naa sọ pe oun kabamọọ ohun ti oun ṣe pẹlu Philip, o ni iṣẹ to bọ lọwọ baba ati mama oun lo sun oun debi fifi ọrẹbinrin oun ṣe oogun owo.
Ẹwẹ, baba oloogbe akẹkọọbinrin naa ṣapejuwe Favour gẹgẹ bi wura ninu idile oun.
Babab Favour ni: ''A woju Ọlọrun fun ọdun diẹ ki a to bi Favour.
O si lọ fasiti eyi to mu inu wa dun pe yoo kẹkọọ gboye laipẹ ṣugbọn eeyan kan gbimọ pọ lati ṣekupa a,''
Baba oloogbe naa ni iku Favour jẹ ibanujẹ nla fun idile oun ati pe idajọ odod nikan lo ku ti oun n reti.
















