Ààrẹ Donald Trump: Qasem Soleimani ń gbìmọ̀ràn láti kọ lù wá l'Amerika la ṣe kọ́kọ́ yára pa á - Trump Ààrẹ

Aarẹ Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump ti ni kii ṣe lati bẹ̀rẹ̀ ogun lawọn ṣe pa olori ọmọ ogun alagbara nni lorilẹede Iran bi ko ṣe lati pa ina ogun ko to bẹrẹ.

Ọgbẹni trump sọ pe ijọba idunkukulaja mọ ni ti Soleimani n dari ti wa sopin pẹlu ikọlu to waye ni papakọ ofurufu Iraq lọjọ ẹti.

Soleimani lo dari awọn ikọlu to waye ni aarin gbungbun orilẹede Iran gẹgẹ bi adari ẹgbẹ ọmọ ogun kan to n jẹ Quds Force.

Ẹwẹ, orilẹede Iran ti leri pe afi ki awọn gba ẹsan iku rẹ. Ẹ̀jẹ̀ yóò sàn pẹ̀lú bí Amerika se pa Ọ̀gáagún wa - Iran

Àkọlé fídíò, Trump impeachment: Trump kò fìdí janlẹ̀ tán, àmọ́ níbo ni yóò jásì?

Bi wọn ṣe pa a yii ti ru ọpọlọpọ ibinu soke laarin orilẹede Iran ati orilẹede Amẹrika.

Bakan naa ni ilẹ Amẹrika ni awọn yoo tun fi ẹgbẹrun mẹta kun ikọ ọmọ ogun ti wọn yoo ran lọ si aarin gbungbun iha Guusu gẹgẹ bi ikọ olu lalakan fi n ṣọri.

Ko da, ile iṣẹ mohunmaworan Iraq royin pe ikọlu inu afẹfẹ kan ti waye lorilẹede naa lẹyin wakati mẹrinlelogun ti wọn pa Soleimani.

Ki ni Aarẹ Trump sọ?

Aarẹ Trump ni awọn ọmọ ogun ilẹ Amẹrika ṣe iṣẹ iṣekupani ọhun lai labawọn kankan eyi to si fa iku adunkoko mọni to lagbara ju lagbaye, Qassem Seleimani".

"Soleimani n gbimọran ọtẹ lati kọlu awọn eekan ati ologun Amẹrika a si gba a mu lọrun ọwọ eyi la si ṣe pari ẹmi rẹ."

Ki wa ni esi Iran?

Ninu ọrọ ti wn fi sita lẹyin iku Soleimani, adari Ayatollah Ali Khamenei sọ pe " wi pe o faye silẹ lọ ba Ọlọrun kii ṣe opin ọna rẹ tabi iṣẹ ti a fi ran an, ṣugbn ẹsan a ke kikan kikan lroi awọn to lọwọ ninu ẹjẹ rẹ atawọn akinkanju mii ti wọn pa lana.

Àkọlé fídíò, Ṣé ẹ ti rí kí èèyàn ní àwọ̀ ara tó ń ṣí bíi ìpẹ́pẹ́ ẹja rí?