World War III: Donald Trump pàṣẹ kí àwọn ọmọ ilẹ̀ Amerika kúrò ni Iran

World War 111

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti sọ pé lóòtọ́ l'òun pa olórí ikọ̀ ajìjàgbara kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀èdè Iran.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba orilẹ-ede Iran ti leri wi pe awọn yoo gbẹsan iṣekupani adari ikọ ọmọ ogun orilẹ-ede naa.

Adari to gaju lọ lorilẹ-ede Iran, Ayatollah Ali Khamenei lọ sọ wi pe gbogbo awọn ọdaran to lọwọ ninu iṣekupani naa ni yoo fi oju wina.

Ali Khamenei ti wọn ti bẹrẹ ipade bayii, ni awọn yoo gbe igbeṣẹ naa lẹyin ipade naa.

Awọn ara ilu naa u jade sita lọgọọrọ lati fi ẹhọnu han lori iṣekupani naa.

World War III

Oríṣun àwòrán, EPA

Bakan naa ni orilẹede Amerika ti parọwa si awọn ọmọ bibi ilẹ Amerika to wa ni ilẹ Iran lati kuro nibẹ ni waranṣeṣa.

Àkọlé fídíò, 'Ohun tóo gbúdọ ṣe lọ́dún yìí bí o bá fẹ́ kí Ọlọ́run bá ọ rìn'

Kí lọ̀rọ̀ ogun abẹ́lé kẹta ṣe tan mọ́ ikú olórí ọmọ ogun Iran tó kú?

Awọn eniyan kaakiri agbaye ti n sọrọ lori bi awọn ọmọ ogun Amẹrika ṣe pa Ọgagun pataki kan l'orilẹ-ede Iran, Qasem Soleiman.

Owurọ ọjọ Ẹti ni iroyin jade pe "aarẹ Amẹrika, Donald Trump lo paṣẹ bi wọn ṣe ju ado-oloro lu u, to si mu ẹmi rẹ lọ.

Ọgagun Soleiman

Oríṣun àwòrán, AFP

Ohun ti ọpọ eniyan n sọ lori Twitter ni pe pipa ti wọn pa ọgagun naa yoo fa ogun agbaye kẹta.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Bi awọn kan ṣe n fi ọrọ naa ṣe nkan to n fẹ igbaradi, ni awọn kan fi n ṣe ẹ̀fẹ̀.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Awọn ọmọ ogun ilẹ Amẹrika ti pa Ọgagun Qasem Soleiman to jẹ olori ẹgbẹ ogun Quds ni Iraq.

Olu ileeṣẹ ologun ilẹ Amẹrika, The Pentagon, fidi rẹ mulẹ pe awọn pa a "nitori aṣẹ ti awọn gba lati ọdọ aarẹ."

Àkọlé fídíò, Ṣé ẹ ti rí kí èèyàn ní àwọ̀ ara tó ń ṣí bíi ìpẹ́pẹ́ ẹja rí?

Inu ọkọ ayọkẹlẹ kan ti wọn fi gbe Ọgagun Soleiman lo wa ni papakọ ofurufu Baghdad, pẹlu awọn ọmọ ogun ajijagbara, lasiko ti ado oloro ja lu u lati ofurufu.

Ko si din ni eniyan maarun to ṣeeṣe ko ku lara awọn ti wọn jọ n lọ.

Olori to ga ju lọ ni orilẹ-ede Iran, Ayatollah Ali Khamenei ti sọ pe "ijiya nla n duro de awọn ọdaran to wa nidi iṣẹlẹ naa".

Bakan naa lo tun kede ọjọ mẹta lati sẹ ọfọ awọn to ku.

Ọkan pataki ni Ọgagun Soleiman ninu ijọba to wa l'ode ni Iran, Ayatollah Ali Khamenei si ni ikọ ajijagbara rẹ, Quds, n jábọ fun.

Àjókù iná ṣì wà ní ìta pápákọ̀ òfurufú Baghdad.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Àjókù iná ṣì wà ní ìta pápákọ̀ òfurufú Baghdad.

Ṣugbọn, ilẹ Amẹrika ti kede ọgagun naa, ati ikọ ajijagbara Quds, gẹgẹ bi agbesunmọmi, to si tun sọ pe wọn mọ si bi ogunlọgọ awọn ọmọ ogun ilẹ Amẹrika ṣe ku.

Ikede kan sọ pe awọn pa Ọgagun Soleiman lati daabo bo awọn ọmọ ogun Amẹrika to wa nilẹ okeere.

Eyi waye lẹyin ọjọ diẹ ti awọn kan to fi ẹhonu han kọlu ileeṣẹ ijọba Amẹrika ni Baghdad, ti awọn ati awọn ọmọ ogun Amẹrika si kọlu ara wọn nibẹ.

Olu ileeṣẹ ologun Amẹrika sọ pe Ọgagun Soleiman fọwọ si bi wsn ṣe kọlu ileeṣẹ Amẹrika.

Ni kete ti iroyin iku Soleiman jade, ni Aarẹ Amẹrika, Donald Trump fi aworan asia Amẹrika sori Twitter.