Ìròyìn tó mi ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ 2020: Amẹ́ríkà dojú ìjà kọ Iran, Ìjọba Kwara wò ilé arúgbó Saraki

aworan awọn ti iroyin wn migboro titi

Satide ti yoo ba da ati ọjọ Jimọ laa tii mọ.

Bi a ba ni ka fi ti awọn iroyin to mi igboro lọsẹ kini Oṣu kini ọdun 2020 yi wo o, nkan yoo ṣẹnu 're lagbami iroyin lọdun ti a ṣẹṣẹ mu yii.

O dabi ana ti a dagbere fun ọdun 2019 ti pupọ wa si n ki ara wa pe a ku ipalẹmọ 2020.

2020 ti de ti o si ti n so eso iroyin lorisirisi.

Ẹ jẹ ki a fi diẹ to ara wa leti ninu wọn ki ọrọ naa ma baa di ariyanjiyan.

Àkọlé fídíò, 2020: Ọdun 2020 yii ko nìí nira fún àwọn tó bá bẹ̀rù Olorun

Abuja Bank Robbery: Ọwọ́ sìkún ọlọ́pàá tẹ Ernest tí wọ́n ń wá.

Ojoro la fẹ fi bẹrẹ tori ẹ le fẹ sọ pe ha ha, ọsẹ to kọja ni ọ̀rọ̀ yii bẹrẹ, ṣugbọn ẹyin yoo ri pe ko baa le daa la fi ṣe bẹ tori o ṣi wa lori igba iroyin titi di ọsẹ yii.

Iroyin awọn adigunjale to lọ fọ banki nilu Abuja tọwọ ọlọpaa tẹ wọn la kọkọ fẹ mu.

Aworan adigunjale ti ọwọ ọlọpaa tẹ nilu Abuja

Oríṣun àwòrán, Guardian Newspaper

Lootọ ni pe lọjọ Kejidinlọgbọn oṣu to pari 2019 ni ọwọ tẹ wọn ṣugbọn ẹni tawọn ọlọpaa sọ pe o jẹ ogunagbongbo iṣẹlẹ naa, laarin ọsẹ kini 2020 ni ọwọ palaba rẹ segi.

Abuja Bank Robbery: Ọwọ́ sìkún ọlọ́pàá tẹ Ernest tí wọ́n ń wá wa lara awọn iroyin tawọn eeyan n ka iroyin rẹ nipa iṣẹlẹ yii.

Ni bayi ti ọwọ ọlọpaa ti tẹ Earnest, iye awọn tọwọ tẹ lori iṣẹlẹ naa ti di marun un.

Ayodele Fayose: Ẹ̀yin ọ̀tá mi, ẹ lọ dì mọ́ òpò ina lọ́dún 2020

Ayodele fayose

Oríṣun àwòrán, @GovAyoFayose

Àkọlé àwòrán, Ẹ̀yin ọ̀tá mi, ẹ lọ dì mọ́ òpò ina lọ́dún 2020- Ayodele Fayose

Nise ti ọdun tuntun bẹrẹ, Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ ri, Ayodele Fayose fi eebu ọrọ ransẹ si awọn to n pẹgan rẹ.

Ọrọ ko ṣẹyin bi awọn kan ṣe bu ẹnu atẹ lu u lẹyin ti fidio jade nibi ti o ti n jo pẹlu oyinbo lode kan ni ilẹ okeere.

Aworan Fayose nibi to ti n ba oyinbo jo

Oríṣun àwòrán, @GovAyoFayose

Wọn ni ṣebi itọju lo loun fẹ lọ gba nilu okeere to fi gba beeli rẹ lọdọ adajọ.

Fayose da wọn lohun pe ayẹwọ ara ni oun lo se, oun ko dubulẹ aisan, nitori naa oun laṣẹ lati jo ati yọ ninu ọdun tuntun.

ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara wó ìlè arúgbó ní ìdàjí

Bi ere bi ere ni ọrọ naa bẹrẹ a mọ ki a to diju ka to la, a ijọba ipinlẹ Kwara ti wo ile Arugbo eleyi to jẹ ti Dokita Olusola Saraki, baba adari ile aṣofin agba Naijiria tẹlẹ ri.

Ile Arugbo ti Ijọba Kwara wo nilu Ilorin

Eemọ kileyi lawọn alatilẹyin Saraki n ke ti awọn iya arugbo naa ṣi n ṣemo pe Gomina Abdulrahaman ti gba ijẹ lẹnu awọn.

Ninu fọnran fidio to wa nisalẹ yii, wọn ti ṣaaju ke gbajare si ki o ma wo ile naa ṣugbọn pabo ni igbiyanju wọn ja si.

Àkọlé fídíò, Àwọn arúgbó ní kí ìjọba máà ṣe wó ilé arúgbó m'áwọn lórí

Nigba ti osẹ yoo fi wa si opin, Bukola Saraki to jẹ ọmọ Dokita Olusola Saraki ati Gbemisola Saraki naa ti tutọ soke foju gba a lori igbesẹ ijọba yii.

Iroyin yi ko ti jọ bi ẹni loju tu,ẹ tubọ maa tẹle wa fun atupalẹ bi ọrọ naa ba ti ṣe n lọ si.

Ṣaaju igba naa, ẹ ka sii nipa rẹ loju awọn opo wọnyii:

World War III: Donald Trump pàṣẹ kí wọ́n pa olórí ikọ̀ ajìjàgbara orílẹ̀èdè Iran

Jẹjẹ lo jọ bi pe ọṣẹ akọkọ 2020 n palẹmọ lati pari ki iroyin bi ilẹ Amerika ti ṣe ṣekupa ọgagun ọmọ orileede Iran kan ni Iraq.

Kete ti iroyin yii lu sita ni gbogbo oju opo iroyin lagbaye gbanajẹ ti awọn eeyan si n pariwo WWIII loju opo Twitter.

Aworan aarẹ Trump Ilẹ Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹkunrẹrẹ iroyin nipa iṣẹlẹ yii ree to ba jẹ pe ẹ ko tii maa fọkan ba a bọ tẹlẹ: