Kogi attack: èèyàn mọ́kàndínlógún pàdánù ẹmi wọ́n ninu ikọlù náà

ikọ ọlọpa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ̀ yòó wáyé

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kogi sọ pe awọn agbebọn ti pa eeyan mọkandinlogun ni ilu Twari ni ijọba ibilẹ Kogi ni ipinlẹ Kogi.

Alukoro ọlọpaa ASP William Aya lo fidi ọrọ yi mulẹ fun BBC .

William Aya sọ pe yatọ si awọn eeyan to padanu ẹmi wọn,awọn agbebọn naa tun sọ ina sawọn ile ti awọn oniroyin kan si sọ pe wọn dana sun ile baalẹ kan nibẹ

Lowurọ kutu ọjọ Ẹti lawọn alaburu yi yabo Tawari ti alukoro ọlọpaa si sọ pe awọn ko le sọ pato awọn to ṣe iṣẹ aburu yi.

''Kọmisan ọlọpaa ni Kogi ti ṣabẹwo sibẹ ti o si ti ni ki iwaadi bẹrẹ ni pẹrẹwu.Bẹẹ naa ni o sọ pe alaafia ti pada si agbegbe naa bayi''

William Aya tẹsiwaju ninu alaye rẹ pe awọn ọlọpaa kogberegbe to fi mọ awọn to n ṣiṣẹ ọtẹlẹmuye n pawọ pọ pẹlu awọn ọmọ ileeṣẹ ologun lati tọ pinpin awọn to wa nidi iṣẹlẹ yi.

Awọn oṣojumikoro kan sọ fawọn akọroyin Naijiria pe ikọlu naa j eleyi tawọn darandaran fi gbẹsan bi wọn ṣe pa awọn ajinigbe kan ti wọn fura si pe wọn jẹ Fulani lopopona Lokoja Abuja.

O sọ pe awọn eeyan ilu Tawari lo ta awọn agbofinro lolobo nipa awọn ajinigbe yi .

Alukoro ọlọpaa sọ pe ohun ko le fidi ọrọ yi mulẹ ṣugbọn iwadi ṣi n lọ lọwọ.