Ọwọ ologun tẹ Bashir to pa ṣọja l'Okenne nipinlẹ Kogi

Afunrasi ọdaran Bashir joko pẹlu awọn ibọn ti wọn ba lọwọ rẹ

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Àkọlé àwòrán, Ibọn atamatase Ak 47 meji pẹlu ọta ibọn marundinlaadọta ni wọn ba lọwọ atamatase naa

Ọwọ awọn ologun lorilẹede Naijiria ti tẹ afunrasi ọdaran kan ti wọn ni o lọwọ ninu iku ọmọogun kan to wa lara awọn ikọ akọṣẹmọṣẹ kogberegbe ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ lorilẹede Naijiria, Kọburu Mamman lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu keji ọdun 2018.

Ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria sọ wi pe, ọwọ tẹ ọdaran naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Mohammed Bashir ti wọn ṣ'alaye wi pe o wa lara awọn ọmọ ẹgbẹ ajinigbe kan to n da agbegbe ipinlẹ Kogi laamu.

Lasiko ti awọn ologun ya bo agbegbe lagbegbe ileto Irovochinomi ati ileto Egee ni ipinlẹ Kogi ni ọwọ tẹ afunrasi ọdaran naa ti wọn si ba ibọn atamatase Ak 47 meji pẹlu ọta ibọn marundinlaadọta lọwọ rẹ.

Awọn ibọn atamatase ti wọn ba lọwọ afunrasi naa

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Àkọlé àwòrán, Ileesẹ ologun ni ko saye fun ikọlu mọ

Bakanaa ni ileeṣẹ ologun lorilẹede Naijiria tun koro oju si awọn ikọlu gbogbo to waye ni ipinlẹ Adamawa, Benue ati Taraba bayii pẹlu ikilọ wi pe awọn ọmọogun ko ni fi ojuure wo ẹnikẹni ti ọwọ ba ba ti o n da omi alaafia laamu lawọn ipinlẹ naa.

Atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ lorilẹede Naijiria, Ọgagun Texas Chukwu fi sita tun sọọ yanyan laifọtape wi pe iwadi ti n lọ ni ifọwọsowọpọ pẹlu awọn ileeṣẹ alaabo gbogbo yooku lati ṣe awari awọn to wa nidi awọn iṣẹlẹ naa.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: