Ara san p'eeyan mẹrindinlogun ninu ṣọọṣi kan ni Rwanda

Aworan ifihan orilẹede Rwanda ati Burundi
Àkọlé àwòrán, Ni agbegbe Rwanda ni awọn eniyan ti ku'ku ara

Ko din ni eniyan mẹrindinlogun to ku nigbati ara san pa wọn ni inu ile ijọsin kan ni orilẹede Rwanda lọjọ abamẹta.

Ogunlọgọ awọn eniyan miran tun f'arapa ninu ile ijọsin yi lẹyin ti awọn mẹrindinlogun ku lẹṣẹkẹsẹ ni agbegbe Nyaruguru gẹgẹbi aṣoju ijọba Habitegeko Francois ṣe sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP.

Awọn eniyan meji miran tun ku lati ipasẹ ọgbẹ ti wọn ko ninu isẹlẹ naa.

Awọn eniyan ti o to ogoje ni wọn ti ko lọ si ile iwosan fun itọju.

Aṣoju ijọba Habitegeko Francois tun wi pe, saaju isẹlẹ yii, ni ara kan ti kọkọ san pa akẹkọ kan ni agbegbe naa ni ọjọ ẹti.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: