Afurasí adigunjalè ṣàlàyé ìdí tó ṣe se oúnjẹ nínú ilé ẹni tó lọ jà lólè

Oríṣun àwòrán, Punch
Ọkunrin ẹni ogoji ọdun kan ti wọn fẹsun idigunjale kan ti ṣalaye idi to ṣe se ounjẹ ninu ile ẹni ti o lọ ja lole.
Afurasi naa, Tope Olaitan, ṣalaye pe iṣẹ gbẹnagbẹna ni oun yan laayo ṣaaju iṣẹ ole jija, ṣugbọn nnkan ko ṣenure ni saa kan nitori airi owo ile ati owo ṣọọbu san.
O ni oun ki i fi ohun ija oloro jale bi awọn ole miran, ṣugbọn igboya lasan ni oun maa n lo lati ṣẹru ba awọn ti oun ba fẹ ja lole.
Olaitan ṣalaye pe "ẹrọ ibanisọrọ ati kọmputa alagbeka ni mo yan laayo lati maa ji, ti mo ba fẹ jale, niṣe ni mo maa n ki ọwọ sinu aṣọ bi ẹni to ni ibọn lọwọ lati fi ko awọn eeyan laya jẹ."
Nigba to n ṣalaye iṣẹ to ṣe kẹyin ki ọwọ ọpalanba rẹ to segi, o ni oun fo igana wọ inu ile obinrin kan ti oun ṣakiyesi pe o n da gbe, oun si beere owo lọwọ rẹ ṣugbọn o kọ jalẹ.
O ni lẹyin ti gbogbo akitiyan oun lati gba owo lọwọ obinrin naa ja si pabo ni oun wọ inu ile idana rẹ lọ, ti oun si ri ẹran tolotolo meji ninu firiji.
- Ọlọ́pàá rí òkú ọ̀gá àgbà iléèṣẹ́ ńlá kan tí wọn ń wá, lójú omi l‘Eko
- A gbé òfin 1960 jáde, màálù tó bá jẹ oko àgbẹ̀, tí olówo rẹ̀ kò sanwó, títà ni - Buhari
- Ìjọba fẹ́ kọ́lé 300,000, pẹ̀lú ìrànwọ́ fún àgbẹ̀ 4m láti mú àdínkù bá ìṣẹ́ - Osinbajo
- Ènìyàn 296 ló kó àrùn Coronavirus ní Nàìjíríà ní Ọjọ́ Ìṣẹ́gun
Gẹgẹ bo sọ, ẹran naa lo n se lọwọ ninu ile idana ti obinrin ọhun fi ri aye ṣa asala mọ o lọwọ to si kẹ gbajari si awọn eeyan adugbo.
Afurasi ọhun ni afujusun oun ni lati fi owo ti ohun ba ri ninu iṣẹ ole jija tun ṣoọbu to wa niwaju ile iya oun ṣe, lati maa lo fun iṣẹ gbẹnagbẹna.
Olaitan sọ pe oun kabamọ ole jija nitori itiju ti oun mu ba awọn ẹbi oun.
Saaju ni ọkunrin kan ti kọkọ jale pẹlu irufẹ ero to yatọ bayii:
Inú oṣù kẹwàá ni mo ti ń ṣètò olè tí mo jà ní Báǹkì mi- Larry Ehizo
Oṣiṣẹ́ to wà ni ẹ̀ka to n ri si ẹdún awọn onibara banki ti ọlọpàá dá wọn lọ́wọ́ iṣẹ́ duro lọ́jọ́ satide to kọja Larry Ehizo ní, láti inú oṣù kẹwàá ọdun 2019 ni òun ti bẹ̀rẹ̀ sini ṣètò bi òun yóò ṣe lọ digun ja Banki náà lóle.
Ehizo yìí lo pada kúrò lóri ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ọkunrin agbọti kan ló n ba òun lórukọ jẹ́ to si ni ki òun lọ jale, o ní òun ti n gbà á lérò tí òun si ti n mojuto bi ètò ààbo Banki náà ṣe wà tẹ́lẹ̀.
Ọkùnrin yii ṣàlàyé pé gbogbo ǹkan ti Ewim sọ òòtọ ni, "kò dúkokò mọ ni. Mo fi tọ́kantọkan gba nọmba rẹ̀ ni, mo pè é o si ni ki n fún òun ní àsìkò díẹ̀"
- Ejò bu abóyún jẹ nílé ìyàgbẹ́, ó kú pẹ̀lú oyún oṣù mẹ́jọ ní Kaduna
- Ẹ̀yin ọmọ Kwara, ẹ seun fún àtilẹ́yìn yin lori ilé Arugbo - Bukola Saraki
- Lagos-Ibadan Express: Ènìyàn mẹ́rin ti kú nínú ìjàmbá ọkọ̀
- Ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, ètò ilera ọ̀fẹ́ àti iná ọba ló jẹ wá lógún- ọmọ Nàìjíríà
- Ìjọba Gomina Raman Razak padà wólé arúgbó ní Ilọrin!
" Nígbà ti mo pè é, mo ṣàlàyé fun bi yóò ṣe wọle, ibi ti wọ́n yóò ti ri àwọn ọlọpàá to n sọ banki náà, ọnà ti wọ́n yóò gbà láti yọ ẹrọ ayaworan (CCTV) kúrò. Ní alẹ́ ọjọ Jimọ lásìkò ìpàdé wa, a ni ìsòrò láti ri awakọ ti yóò wà wá."

Nígbà ti akọròyìn bèrè pé kíní ìdí ti Ehizo fi ṣe irú ǹkan bẹ́ẹ̀, o ni ìwà ọkájúwà lásán ni, mo rò pé ǹkan ti yóò rọrun láti ṣe ni, mo ti lo àsìkò mi láti wo gbogbo ǹkan ti mo fẹ́ ṣe, mo ti n ro láti inú oṣù kẹwàá.
" Bóyá nitori pé mo ń siṣẹ́ ni Banki ni, mo ro pé mo le ni ìpín nínú owo banki, nítori náà mo ti wo gbogbo ibi ti CCTV wa ibi ti àwọn ọlọpàá wa, bi wọ́n ṣe maa n wà ni òpìn ọṣẹṣẹ, àti ẹrọ apọwo wa ṣe maa ṣe lásìkò náà"
Ọlọpàá Ilú Abuja ti mú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ọdaran méfa ninu àwọn ọdaran bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tun mu Ewim nibi to sápamọ si.
Sááju ni ọlọpàá ti fún ọkan ninu wọ́n ti wọ́n pe Patrick nibón ti wọ́n si mu àwọn mẹ́rin to ku lẹyin ti ipinu wọ́n kùna
Kọmisọnna ilú Abuja Bala Ciroma ti fi oju wọ́n han ni ọjọ iṣẹ́gun to fi mọ Ehizo ọgbọn ọdun, Timothy Joe ọdun mọkanlelogun, Princewill Obinna, mẹrinlélogun, àti Elijah David mọkandinklogun.
















