Sex: Ẹ̀ẹ̀méje ló gorí ọmọ alaṣẹ́wó, ni kò bá bọ̀ mọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Davy ti gbẹmi mi lasiko ifigagbaga ibalopọ pẹlu obinrin aṣẹwo nile itura kan lagbegbe Ejigbo nipinlẹ Eko.
Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Eko, DSP Elkana Bala ti ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi iku ojiji ti ko si wa lasan. O ni nkan bii ago kan oru ku iṣẹju mẹẹdogun lọjọ Aiku lo ṣẹlẹ.
Iroyin sọ pe oloogbe naa lọ gba yara ni ile itura naa, Graceland Brothel to wa ni agbegbe Moshalasi ni Ejigbo lẹyin ti oun ati ọmọ alaṣẹwo kan jọ leri ẹgbẹrun lọna aadọta naira.
Davy ati Amaka jọ leri lati mọ ẹni ti yoo kọkọ dawọọ lẹ ninu awọn mejeji. Bi alaṣẹwo naa ṣe ni olomi lo maa rẹ, ni arakunrin naa fesi pe "jẹ ka da a le e".
Báwo lọ̀rọ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀?
Ọrẹ oloogbe Davy to ba awọn akọroyin sọ̀rọ̀ lori ipo ti o wa fi hande pe ọ̀rọ̀ yii bẹrẹ nigba ti oloogbe ti leri to fọwọ sọya niwaju awọn ọrẹ rẹ pe oun le lo wakati meji lori obinrin lai simi.
Bi wọn ṣe n ba ọrọ naa lọ, kan lara awọn ọrẹ rẹ ni lae ko le ba Amaka mọ oloṣo dan an wo tori wọn ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi ẹni ti wọn gba lọga ninu ibalopọ.
Wọn ni Amaka ti ba awọn ọdọkunrin kan kẹsẹ bọ ṣokoto kan to si jawe olubori. Ṣugbọn o dori akayin o, ni akara ba tu sepo. Davy ko goke naa pada bọ o, ori ẹlẹẹkeje lẹmi ti bọ.










